





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Al-Shikhiir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo lọ pẹlu awọn ikọ bani Āmir si ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ni a wa sọ pe: Iwọ ni olowo wa, ni o wa sọ pe: "Allāhu ni Olowo", a sọ pe: ati ọlọlajulọ inu wa, ati ọlọrọ julọ inu wa, ni o wa sọ pe: «Ẹ maa sọ awọn ọrọ yin, tabi apakan awọn ọrọ yin, ẹ ma jẹ ki esu o lo yin (ki o gbe yin kọja aala)».
Abu Daud ati Ahmad ni wọ́n gba a waAwọn ijọ kan wa ba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, nigba ti wọn de ọdọ rẹ wọn sọ - ni ẹni ti n yin in - awọn ọrọ eleyii ti o korira rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, Ni wọn wa sọ pe: "Iwọ ni olowo wa", Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ fun wọn pe: Allāhu ni Olowo. Nitori naa o n bẹ fun Un iyi (isiwaju) ti o pe lori awọn ẹru Rẹ, ati pe awọn ni ẹrusin Rẹ. Ni wọn wa sọ pe: Iwọ ni "ẹni ti o lọla julọ ninu wa" ti o si tun ga jùlọ ni ipo ati iyi ati ẹyẹ. Ati pe iwọ ni "ẹni ti o tobi julọ ninu wa ni ọrọ" ti o tun pọ julọ ni ọrẹ tita ati giga. Lẹyin naa ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa tọ́ wọn sọna pe ki wọn máa sọ gbolohun wọn ti wọn ti ba saaba ki wọn o si ma la awọn gbolohun kan bọ ara wọn lọrun, ki esu ma lọ ti wọn lọ si ibi aseju ati ayinju eleyii ti maa n muni ko sinu nkan ti wọn ṣe leewọ ni ẹbọ (imu orogun mọ Ọlọhun) ati awọn atẹgun rẹ.
Lati ọdọ ọmọ 'Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ni àárọ̀ jiju okuta ipari, ti o si wa lori rakunmi rẹ pé: "Ba mi mu okuta kekere kan" mo wa mu awọn okuta kekere meje fun un, awọn ni okuta kéékèèké tí a maa n fi ìka méjì jù, o wa bẹ̀rẹ̀ si nii ju wọn si atẹlẹwọ rẹ, o si n sọ pe: "Awọn iru awọn wọnyi ni ẹ maa ju" lẹyin naa o sọ pe: "Ẹyin eniyan, ẹ ṣọ́ra kuro nibi aṣeju nibi ẹsin, dajudaju nnkan ti o pa àwọn ti wọn ṣíwájú yin run ni aṣeju nibi ẹsin".
Ibnu Maajah ati Nasaa'iy ati Ahmad ni wọ́n gba a waỌmọ 'Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- n sọ pe oun wa pẹlu Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ọjọ iduran ni àárọ̀ jiju okuta jamratul ákọ́bà ni hajj idagbere, Bayii ni o ba pa a láṣẹ ki o ba a sa okuta ti o maa jù, o si ba a sa òkúta meje, ikan nibẹ da gẹgẹ bii èso himmas tabi èso bunduk, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbe wọn si ọwọ rẹ lẹyin naa o mì wọn, o wa sọ pe: Irú wọn ní ìwọ̀n ni ki ẹ jù, Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣekilọ nipa aṣẹju ati imu nnkan le koko ati kikọja aala nibi awọn alamọri ẹsin, ati pe kikọja aala ko iparun ba awọn ijọ ìṣáájú ati aṣeju ati imu nnkan le koko nibi ẹsin.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Ko si àkóràn, tabi fifi ẹyẹ fura mọ aburu, tabi fifi ẹyẹ owiwi fura mọ ìṣẹ̀lẹ̀ àjálù, tabi fifi oṣu Safar fura mọ aburu, ki o si sa fun adẹtẹ gẹgẹ bi o ṣe maa n sa fun kinihun".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé awọn kan ninu awọn àlámọ̀rí asiko aimọkan ni ti siṣekilọ kuro nibẹ, ati ṣíṣe àlàyé pe dajudaju àlámọ̀rí ọwọ Ọlọhun ni o wa, ati pe nnkan kan ko le ṣẹlẹ̀ afi pẹlu àṣẹ Rẹ ati kadara Rẹ, awọn ni: Akọkọ: Awọn ara asiko aimọkan n lero pe dajudaju aisan maa n ran fun ara rẹ; ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi kọ kuro nibi adisọkan ṣíṣí aisan latara alaisan sọ́dọ̀ ẹlòmíràn fúnra rẹ; Ọlọhun ni n ṣàkóso ayé; Oun ni O n sọ aisan kalẹ ti O si n gbe e kuro, ìyẹn ko lee ṣẹlẹ̀ afi pẹlu fifẹ Rẹ ati kadara Rẹ. Ikeji ni: Awọn ara asiko aimọkan ti wọn ba jade fun ìrìn-àjò tabi òwò, wọn maa lé ẹyẹ lọ, ti o ba fo si agbegbe ọtun wọn maa dunnu, ti o ba fo si agbegbe osi wọn maa fura mọ aburu wọn si maa ṣẹri pada, ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe kọ kuro nibi ifura mọ aburu yii pẹlu ẹyẹ, ti o si ṣàlàyé pe adisọkan ibajẹ ni. Ikẹta: Awọn ara asiko aimọkan maa n sọ pe: Ti ẹyẹ owiwi bá bà lori ile kan, àjálù kan maa ṣẹlẹ̀ si awọn ara ile náà; ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe kọ kuro nibi ifura mọ aburu pẹlu ìyẹn. Ikẹrin: O kọ kuro nibi ifura mọ aburu pẹlu oṣu safar, oun ni oṣu keji ninu awọn oṣu ti òṣùpá. Wọ́n tún sọ pé 'Safar' jẹ́ ejò tó ń gbé inú ikùn, tó ń ṣàkóbá fún ẹran ọ̀sìn àti ènìyàn. Wọ́n sọ pé ó máa ń ranni ju àrùn ìgbóná lọ; ni o wa tako adisọkan yii. Ikarun-un: Ó pàṣẹ pé kí wọ́n yẹra fún ẹni tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá n bẹ lára rẹ gẹ́gẹ́ bí ìwọ yóò ṣe yẹra fún kìnnìún, gẹ́gẹ́ bí ìṣọ́ra fún ara rẹ, ati wiwa ààbò fun un, àti ṣíṣe àwọn ìdí tí Ọlọhun pa láṣẹ. Ẹ̀tẹ̀ jẹ́: Àìsàn tó máa ń ba àwọn ẹ̀yà ara jẹ́.
Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Ko si akoran, ko si si ifi ẹyẹ fura mọ daadaa tabi aburu, ati pe mo fẹ́ràn fah'lu, o sọ pe wọn sọ pe: Kí ni fah'lu? O sọ pe: "Ọrọ ti o daa".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju akoran ti èèyàn asiko aimọkan ni adisọkan rẹ pe dajudaju aisan maa n ṣi kuro fun ara rẹ bọ si ara ẹlomiran láìṣe pẹlu kadara Ọlọhun jẹ ibajẹ, Ati pe ifi ẹyẹ fura mọ daadaa tabi aburu jẹ ibajẹ, oun ni ifuramọ aburu lati ara èyíkéyìí nnkan ti a gbọ́ lo jẹ ni tabi ti a ri, ninu awọn ẹyẹ tabi awọn ẹranko tabi awọn oni ailera tabi awọn onka tabi awọn ọjọ tabi eyi ti o yàtọ̀ si wọn, Wọn dárúkọ awọn ẹyẹ nitori pe o jẹ eyi ti o gbajumọ lọdọ awọn ara asiko aimọkan, ati pe ipilẹ rẹ ni titu ẹyẹ silẹ nigba ti a ba fẹ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ kan bii irin-ajo tabi owo tabi eyi ti o yàtọ̀ si ìyẹn, ti o ba fo lọ si ẹgbẹ ọtun, ó maa furamọ daadaa, o si maa ba nnkan ti o fẹ lọ, ti o ba fo lọ si ẹgbẹ òsì, o maa furamọ aburu, o si maa koraro kuro nibi nnkan ti o fẹ. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju ọrọ daadaa maa n wu òun, oun ni nnkan ti o maa n ṣẹlẹ̀ si ọmọniyan bii ayọ̀ ati idunnu ninu ọrọ daadaa ti o n gbọ́, ti o si maa mu ro ero daadaa pẹlu Olúwa rẹ.
Lati ọdọ Al-Barrohu- ki Ọlọhun yọnu si i-: Lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dajudaju o sọ nipa awọn Ansar pe: "Ẹnikan ko nii nífẹ̀ẹ́ wọn afi olugbagbọ, ẹnikan ko si nii korira wọn afi sobẹ-ṣelu, ẹni ti o ba nífẹ̀ẹ́ wọn, Ọlọhun maa nifẹẹ rẹ, ẹni ti o ba si korira wọn Ọlọhun maa korira rẹ".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju nini ifẹ awọn Ansar ninu awọn ara Madina, jẹ àmì lori pipe igbagbọ; eleyii rí bẹ́ẹ̀ nitori gbigba iwaju wọn nibi aranṣe Isilaamu ati Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ati gbigbiyanju nibi gbigba awọn Musulumi sile, ati nina awọn dukia wọn ati ẹmi wọn si oju ọna Ọlọhun, ati pe kikorira wọn jẹ ami lori ṣiṣe sobẹ-ṣelu. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba nífẹ̀ẹ́ awọn Ansar, Ọlọhun maa nifẹẹ rẹ, ẹni ti o ba si korira wọn Ọlọhun maa korira rẹ.
Lati ọdọ Abu Hurayrah - kí Ọlọhun bá wa yọnu si i, o sọ bayi pe: Òjíṣẹ Ọlọhun - Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - sọ bayi pe: "È sun mọnra, ẹ se daada, ki ẹ lọ mọ pe kò sí ẹnikan ninu yin ti yoo la pọlu iṣẹ ọwọ rẹ" awọn ọmọlẹyìn rẹ sọ bayii pe: Se ati iwọ naa irẹ ojisẹ Ọlọhun? Anọbi daun oni: ati emi naa, ayaafi ki Ọlọhun da gaga ikẹ Rẹ ati aanu Rẹ lemi lori (ki Ọlọhun siji àánu Rẹ bò mi) .
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ṣe awọn ọmọlẹyìn loju kòkòrò (o fa ifẹ wọn) síbi imaa sisẹ, ati ki wọn si bẹrù Ọlọhun bi wọn ba se ni agbara mọ, láì ṣe àṣe kọja ààlà, ati láì ṣe asee to, ki wọn ni eero iṣẹ àṣe dara pẹlu imáa ṣe iṣẹ wọn nítorí ti Ọlọhun (aniyan tori Ọlọhun) ati imáa tẹlé ilana ati alaalẹ anọbi, ki iṣẹ wọn le jẹ àtéwọgbà, atipe ki o jẹ okunfa isọkalẹ àánu Ọlọhun fún wọn. O si tun fún wọn niro pe isẹ enikọọkan yin nikan ko lee gbayinla, sugbọn afi ki ẹ rí ikẹ gba lọdọ Ọlọhun. Wọn sọ pe: titi o fi de orí rẹ, irẹ ojisẹ Ọlọhun, iṣẹ rẹ ko lee gbaọla toun ti bi o se tobi to? Anọbi sọ pe: titi ofi dé orí mi, ayaafi ki Ọlọhun bomi lasiri pẹlu aanu Rẹ.
Láti ọdọ Jaabir ọmọ Abdullahi kí Ọlọhun yọnu sí awan méjèjì, dájú dájú anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti Ọlá Rẹ má bà sọ pé: « wan tí fún mí ni nkán márùn tí wan kọ fún ẹni kánkan síwájú mí : wan fí ọwọ àti igbakẹ kankan mú aranse ba mí
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi kí ikẹ àti ọlá Ọlọhun máa ba fún wa miró pé dájú dájú Ọlọhun ti fún òun ni nkán márùn tí Ọlọhun kọ fún ẹnikan nínú awani anọbi síwájú rẹ: Alakọkọ: wan ràn mise pẹlu ìbẹrù tí wan nju sínú ọkan awàn ọtá mí , kò dá kí o já sipe kí Jinan mí sí ìbi tí wan wa le gbani ni irinajo osù kàn gbáko. Ẹlẹẹkeji: wan se ilẹlẹ ni ààyè ifori kanlẹ fún wa tí a o máa kirun níbi kí bí tí a ba wa, wan tún se ni nkán imọra pẹlu lílo iyẹpẹ nígbàtí a bà kagara láti lọ omi. Ẹlẹkẹta: wan se ọrọ ogún lẹtọ fún wa , òun ni nkan tí awàn musulumi nri gbà ní ojú ogún pẹlu awan alaigbagbọ. Ẹlẹkẹrin: wan fun mí ni isipẹ tí o to bi jùlọ níbi ìfun awan ènìyàn ni ìsimi níbi ìbẹrù bojo ibuduro ọjọ igbende. Ẹlẹkaarun: wan ràn mí sí gbogbo ẹda lapapọ àti eniyan àti alujannu wan yatọ sí ti awan anọbi tí wan síwájú rẹ, wan ran wan sí awan ìjọ wan nìkan ní .
Lati ọdọ Haarithah ọmọ Wahbi Al-Khuzaa'iyy - ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - o sọ pe: mo gbọ Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - tí ń sọ bayi pe: "Ẹ jẹ kín fún yín ní ìró nipa awọn ẹni Alujanna? gbogbo ọlẹ ti ko lágbára rara, ti o ba búra iroro nkan síwaju Ọlọhun, Ọlọhun yóò sọ ọ di daada, ẹ jẹ kí nfun yin ni iro nipa awọn ẹni iná: gbogbo ẹni ti o le koko, ti nrin tanlu tanlu, oni moto moto".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) fún wa niro apakan awọn iroyin awọn ẹni Alujanna (ọgbà idẹra) ati awọn ẹni ina. Awọn ti wọn pọ̀jù nínú ẹni Alujanna awọn ni: "gbogbo ọlẹ ti kò lágbára rara" itumọ rẹ nipe: ẹni tí o ntẹriba ti o si njirẹbẹ fún Ọlọhun ti o ga jùlọ, ti o rẹ raa rẹ fun Un, debiipe apakan awọn eniyan wọn npe e ni ọlẹ, wọn nyẹpẹrẹ rẹ̀, ẹni ti o yẹpẹrẹ araa rẹ̀ fun Ọlọhun yii, ti o ba fi Allah (Ọlọhun) bura ni enití n rokan si oore Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, Allah yoo sọ di daada, yoo si sọ ohun ti o bura le lori di ootọ, yoo si da lohun ohun ti o beere ati adua rẹ. Awọn ti wọn pọju ninu awọn ẹni iná ni gbogbo "oni iwa to le koko" ohun ni onibinu, ọlọkan líle koko, alajangbila, tabi oni iwa ibajẹ (alaburu) ti kii tẹriba fún daada, "onigirimọkai" ohun ni oni moto moto, Alajẹju (okuonjẹ), ẹni tori gbàngbà, ti nrin irin tanku taloku (irin akọ) oniwa buruku, "oni moto moto" pẹlu aigba ododo wọle, ati ifoju yẹpẹrẹ wo awọn elomiran.
Lati ọdọ Abu Hurayrah - kí Ọlọhun yọnu si i - o sọ bayi pe: Òjíṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) sọ pé: Allah Ọlọhun ti O gbọngbọn ti O ga jùlọ sọ pé: Emi wà pẹlu aba ti ẹru mi dá sí mi, Emi si wà pẹlu rẹ nigbati o ba rántí Mi , ti o ba rántí mi ninu ẹmi rẹ Emi naa yóò rántí rẹ ninu ẹmi Mi, ti o ba rántí mi làárìn awọn ìjọ Emi naa yóò rántí rẹ láárín awọn ti wọn lóore jù ìjọ tiẹ lọ, ti o bá sun mọ mi ni iwọn àlàfo ni na ọmọnika tán Emi yóò sún mọ ni iwọn ni na igunpá, ti o bá sun mọ Mi ni iwọn gigun apá Emi yóò sún mọ ni iwọn gigun ni na apa méjèejì lẹẹkan naa, ti o bá wá bá mi ni eniti nrin, Emi yóò wá bá ní Ẹni ti nyara.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba) fún wa niro pe dájúdájú Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pé: Emi wà pẹlu aba ẹru mi sí mi, Emi yóò sì máa bá a lo nibamu aba rẹ sí mi, pẹlu ini ireti ati ifun ni ni ireti amojukuro, bẹẹni ma máa ṣe oore eyi ti nfọkan sí lọdọ mi, tabi awọn nkan mii; mo wà pẹlu rẹ pẹlu ikẹ ati ifini se kongẹ daada ati itọsọna ati amojuto ati ikun lọwọ nigbati o ba rántí mi. Ti o bá seranti mi ninu ọkan rẹ ni òun nìkan ti ẹnikankan kò si ni bẹ pẹlu sise afọmọ ati gbólóhùn pe kò sí Ọlọhun míràn to yẹ kaa maa sìn àyàafi Allah, tabi awọn ìrántí mii, maa rántí rẹ ninu ẹmi Mi. Ti o bá rántí Mi láàrin àwọn akojọ kan, Emi naa yóò rántí rẹ láárín awọn akojọ ti wọn pọ ti wọn si dáa jù wọn lọ. Ẹni tí o ba sun mọ Ọlọhun ni iwọn ina ika ọwọ mararun tan Ọlọrun yóò se alekun fun yóò wá sun mọ ni iwọn igunpa kan. Ti o bá sun mọ ni iwọn igunpa kan Ọlọhun yóò sún mọ ni iwọn ina apá mejeeji tan lẹ kan naa. Ti o ba wa bá Ọlọhun ni ẹnití nrin Ọlọhun yóò wá ba ni yara yara. Ti ẹru (eniyan) bá sun mọ Oluwa rẹ pẹlu imáa tẹle àṣẹ Rẹ ti o kọ ju sí daada, dajudaju Ọlọhun Oluwa ti O ga jù lọ yóò se alekun ni isunmọ rẹ pada yóò máa jẹ ẹsan iru nkan to se. Gbogbo igba ti ijẹ ẹru fún Ọlọhun ti olugbagbọ ba ti pé fún Oluwa rẹ náà ni Ọlohun ti Ọ̀la Rẹ ga yóò sún mọ, ọrẹ Ọlohun ati ẹsan Rẹ pọ jù iṣẹ ati wahala ti ẹru se lori rẹ lọ, eyi ti o ṣẹlẹ nipe ẹsan Ọ̀lọhun tẹwọn lori iṣẹ ẹru pẹlu ọna ati iye iṣẹ tó ṣe. Olugbagbọ ododo yóò máa daba daada sí Oluwa rẹ, yóò sì máa ṣiṣẹ daada, yóò sì máa yàrá sise daada, yóò sì máa ṣe alekun iṣẹ tí yóò fi pàdé Ọlọhun.