





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Tolha ọmọ 'Ubaidullah - ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Arákùnrin kan wa ba ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu awọn ara Najd, ti irun ori rẹ ri wúruwùru ti ohun rẹ n lọ sókè ti a o si gbọ́ ohun ti n sọ yé, titi ti o fi sunmọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni o ba n beere nipa Isilaamu, ni ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a – wa sọ pé: “Irun wákàtí márùn-ún ni ojúmọ́”, o wa sọ pe: Ǹjẹ́ nǹkan míì tun jẹ dandan le mi lórí yàtọ̀ si i? O sọ pe: “Rara, àfi ti o ba fẹ ṣe aṣegbọrẹ, ati aawẹ oṣù Ramadan”, o sọ pe: Ǹjẹ́ nǹkan mii tún jẹ́ dandan fún mi yàtọ̀ sí i? O sọ pe: “Rara, afi ti o ba fẹ ṣe aṣegbọrẹ”, ojiṣẹ Ọlọhun- kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa dárúkọ sàká fun un, o sọ pe: Njẹ omiran lẹyin wọn jẹ dandan fun mi? O sọ pe: “Rara, afi ki o ṣe aṣegbọrẹ”, o sọ pe: Ni arakunrin naa yi ẹsẹ pada, o wa n sọ pe: Mo fi Ọlọhun bura, mi ko nii lekun lori eyi, mi ko nii dinkun ninu rẹ, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: ”O ti jere ti o ba sọ ododo”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niArakunrin kan ninu awọn ara Najd wa sọ́dọ̀ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti irun rẹ ri wuruwuru, ti ohun rẹ lọ sókè, ti wọn ko gbọ nnkan ti o n sọ ye, titi o fi sunmọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ti o si beere nipa awọn ọran-anyan Isilaamu? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bẹ̀rẹ̀ pẹlu irun, ti o si sọ fun un pe dajudaju Ọlọhun ṣe irun marun-un ni ọran-anyan le e lori ni gbogbo ọ̀sán ati oru. O sọ pe: Njẹ nnkan kan tun jẹ dandan fun mi ninu awọn irun yàtọ̀ si awọn marun-un yii? O sọ pe: Rara, afi ti o ba ki nafila lati ṣe aṣegbọrẹ. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ninu nnkan ti Ọlọhun tun ṣe e ni dandan le ẹ lori ni awẹ oṣu Ramadan. O sọ pe: Njẹ nnkan kan tun jẹ dandan fun mi ninu awẹ yàtọ̀ si awẹ Ramadan? O sọ pe: Rara, afi ti o ba gba aawẹ fun aṣegbọrẹ. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dárúkọ saka fun un. Arakunrin naa sọ pe: Njẹ nnkan kan tun jẹ dandan fun mi ninu awọn saara lẹyin saka ọran-anyan? O sọ pe: Rara, a fi ti o ba ṣe aṣegbọrẹ. Lẹyin igba ti arakunrin naa gbọ́ lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa awọn ọran-anyan yìí, o pẹyin da, o si búra pẹlu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pe oun maa dunni mọ́ ọn laisi alekun tabi adinku, ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ lẹyin ìyẹn pé: Ti arakunrin naa ba sọ ododo lori nnkan ti o bura le lori dajudaju o maa wa ninu awọn olujere.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Eyi ti o loore julọ ninu ọjọ ti oorun yọ nibẹ ni ọjọ Jímọ̀, ninu rẹ ni wọn ṣẹda Aadam, ninu rẹ ni wọn mu u wọ alujanna, ninu rẹ ni wọn mu u jade kúrò nibẹ, ọjọ́ igbende ko lee to afi ni ọjọ Jimọ".
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju eyi ti o daa julọ ninu ọjọ ti oorun ran ninu rẹ ni ọjọ Jimọ, Ninu awọn iroyin rẹ ti o fi da yatọ ni pe: Dajudaju Ọlọhun ṣẹda Aadam- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- ninu rẹ, ninu rẹ ni O mu u wọnu alujanna, ninu rẹ ni O mu u jade lati inu rẹ ti O si mu u sọkalẹ sori ilẹ̀, ọjọ igbende ko lee to afi ni ọjọ Jimọ.
Lati ọdọ Abu Hurayrah - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: "ẹru kan ko ni se ibasiri fún ẹrú kan láyé nbi ayaafi ki Ọlọhun se ibasiri fún un ni ọjọ igbende".
Muslim gba a waAnọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) n salaye fun wa pé musulumi kan ko ni bo asiri ọmọ Iya rẹ tó jẹ musulumi nipa àlámọ̀rí kan ninu awọn àlámọ̀rí, ayaafi ki Ọlọhun bo asiri rẹ ni ọjọ igbende, iran iṣẹ ti a ba se náà ni a o gba ẹsan rẹ, yóò wa jasipe bibo àṣírí Ọlọhun fún un ni pé yóò bo asiri awọn laifi rẹ àti àwọn ẹsẹ rẹ lati máa ṣe itanka rẹ lọdọ awọn ti wọn wani ibi gbangba Al-kiyaoma, o si le je pe bibo asiri rẹ ni ki Ọlọhun má ṣe iṣiro rẹ tabi ki o má ti ẹ mẹnu kaan rárá.
Lati ọdọ Abu Muslim Al-Khaolaaniy, o sọ pe: Al-Habeeb Al-Ameen sọ fun mi, ṣùgbọ́n ẹni ti mo nífẹ̀ẹ́ si ni, ṣùgbọ́n oun lọdọ mi, o jẹ olufọkantan, 'Awf ọmọ Maalik Al-'Ashja'iiy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: A jẹ lọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, mẹ́sàn-án tabi mẹjọ tabi meje, o wa sọ pe: "Ẹ tẹti ẹ gbọ, njẹ ẹ ko nii ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun?" A si ṣẹṣẹ ṣe adehun kan tan ni, a sọ pe: A ti ṣe adehun fun ẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, lẹyin naa, o sọ pe: "Ẹ tẹti ẹ gbọ, njẹ ẹ ko nii ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun?" A sọ pé: Dajudaju a ti ṣadehun fun ẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, leyin naa, o sọ pe: "Ẹ tẹti ẹ gbọ, njẹ ẹ ko nii ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun?" O sọ pe: A wa tẹ awọn ọwọ wa, a si sọ pé: A ti ṣadehun fun ẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, lori ki ni a maa ṣadehun fun ẹ? O sọ pe: "Lori pe ẹ ma maa jọsin fun Ọlọhun ẹ ko si gbọdọ da nnkan kan pọ mọ Ọn, ati awọn irun maraarun-un, ẹ si gbọdọ maa tẹle- o wa sọ ọrọ kan ti o pamọ ni jẹjẹ- ẹ ko si gbọdọ beere nnkan kan lọwọ awọn eniyan" dajudaju mo ti ri awọn kan ninu awọn ẹni yẹn, ti ọrẹ ẹnikan ninu wọn ba jabọ, ko nii ni ki ẹni kankan o ba oun mu un.
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa lọdọ awọn kan ninu saabe, o wa beere lọwọ wọn lẹẹmẹta lati ṣadehun fun un lori idunnimọ awọn àlámọ̀rí kan: Akọkọ: Ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo pẹlu mimu awọn àṣẹ Rẹ ṣẹ ati jijina si awọn nnkan ẹkọ Rẹ, ati pe wọn ko gbọdọ da nnkan kan pọ mọ Ọn. Ikeji: Gbigbe awọn irun maraarun-un ti a ṣe wọn ni ọran-anyan duro ni ọsan ati oru. Ikẹta: Gbigbọ ati Itẹle pẹlu daadaa fun ẹni ti o ba n dari alamọri awọn Musulumi. Ikẹrin: Mimaa sọ gbogbo awọn bukaata wọn kalẹ ti Ọlọhun laini beere nnkan kan nibẹ lọwọ awọn eniyan, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa rẹ ohun rẹ nilẹ pẹlu rẹ. Dajudaju awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- ṣiṣẹ pẹlu nnkan ti wọn ṣe adehun le lori, titi ẹni ti o gba hadiisi naa fi sọ pe: Dajudaju mo ri awọn kan ninu awọn saabe wọnyẹn, ti ọrẹ ẹnikan ninu wọn ba jabọ, ko nii sọ fun ẹni kankan ki o ba òun mu u, bi ko ṣe pe o maa sọkalẹ ti o si maa mu u fun ara rẹ.
Lati ọdọ Al-Baraa ọmọ 'Azib- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Musulumi ti wọn ba bi i leere ninu saare: O maa jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu ati pe dajudaju Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni", ìyẹn ni ọrọ rẹ pé: (Allāhu yóò máa fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ t’ó rinlẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn (Ibrahim, Ayah 27).
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niWọn maa bi olugbagbọ leere ninu saare, awọn mọlaika meji ti a fi ṣe amojuto ìyẹn maa beere lọwọ rẹ nipa ìyẹn, awọn mejeeji ni Munkar ati Nakeer, gẹgẹ bi orúkọ awọn mejeeji ṣe wa ninu ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn hadiisi, O maa jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe eleyii ni ọrọ ti o fi ẹsẹ rinlẹ ti Ọlọhun sọ nipa rẹ pé: (Allāhu yóò máa fi àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo rinlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ t’ó rinlẹ̀ nínú ìṣẹ̀mí ayé àti ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn (Ibrahim, Ayah 27).
Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Wọn pa mi láṣẹ lati ba awọn eniyan ja titi wọn maa fi jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ti wọn si n gbe irun duro, ti wọn si n yọ saka, ti wọn ba ṣe iyẹn, wọn ti daabo bo awọn ẹjẹ wọn ati awọn dukia wọn kuro lọdọ mi afi pẹlu ẹtọ Isilaamu, ati pe ìṣirò iṣẹ wọn wa lọwọ Ọlọhun".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju Ọlọhun pa oun láṣẹ pẹlu biba awọn ọṣẹbọ ja titi wọn fi maa jẹrii pe ko si ẹnikan ti a le jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Allahu nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un, ati ki wọn jẹrii ìránṣẹ́ fun Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ati ṣiṣe iṣẹ pẹlu nnkan ti ijẹrii yii n beere fun bii sisọ awọn irun maraarun-un ni ọsan ati alẹ, ati ki wọn maa yọ saka ti o jẹ ọran-anyan fun awọn ti wọn lẹtọọ si i. Ti wọn ba ti ṣe awọn alamọri yii, dajudaju Isilaamu maa daabo bo awọn ẹjẹ wọn ati awọn dukia wọn, ti pipa wọn ko nii lẹtọọ afi ti wọn ba wu iwa ọdanran kan ti wọn wa maa fi lẹtọọ si pipa lori rẹ tori okùnfà idajọ Isilaamu, lẹyin naa, ni ọjọ igbedide Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa ṣe amojuto ìṣirò iṣẹ wọn nigba ti O mọ awọn kọ̀kọ̀ wọn.
Lati ọdọ ọmọ Abbas kí Ọlọhun yọnu sí awan méjèjì dájú daju òjíṣẹ Ọlọhun kí ikẹ àti ọlá rẹ máa ba sọ pé: « Dájú dájú Ọlọhun ti se amojukuro aṣiṣe àti ìgba gbé fún mi nípa awan ìjọ mí àti nkán tí wan ba jẹ wàn nípa láti ṣe ».
رواه ابن ماجه والبيهقي وغيرهماAnọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ má bà nfun wa niro pé dájú dájú Ọlọhun ti se amojukuro nkán mẹta fún awan ìjọ rẹ : Alakọkọ ni : aṣiṣe, òun ni nkán tí o ba ṣẹlẹ láti ọdọ wàn lai mọn mọn se , òun ni kí muslimu ni ero pẹlu nkán tí o se , kí o wa jasi pe iṣẹ rẹ tí o se se alaba pàdé nkàn tí o yatọ sí nkan tí o gba lérò. Ẹlẹẹkeji ni : igbagbe, òun ni kí muslim se ìrántí nkán kan , ṣugbọn kí o tún gbà gbé rẹ nigbati o fẹ se , kò sí ẹsẹ fún nípa rẹ bákan náà. Ẹlẹkẹta ni : ijeni nípa se nkán, wàn le jẹ ẹrú ( ọmọ ènìyàn) nípa láti ṣe nkan tí kò fẹ se pẹlu pé koni ìkápá láti dá ijẹnipa náà padà , nígbà náà kòní sí ẹsẹ tàbí aburú kàn kan . Pẹlu ise àkíyèsí pé dájú dájú àkòrí ọrọ Hadith ni òun tí bọ nbẹ láàrin ẹrú àti Olúwa rẹ nípa ṣíṣe nkán tí wan se leewọ , ṣugbọn gbígbé nkán tí wan páni lá sẹ jù silẹ ni ti igbagbé kò tí mú aṣẹ náà kúrò, ṣugbọn tí ìwà ọdaran kan ba tí atara ṣíṣee wa ye òun tí o jẹ ẹtọ ènìyàn kò tí bọ , gẹgẹ bí kí o se sí paayan , dandan ni kí o sanwo ìtanràn emi b, tàbí kí o sesi ba mọto jẹ dandan ni fún láti san owó ìtanràn .
Lati ọdọ Abu Barzata Al-aslamiy - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹsẹ mejeeji ẹru kan ko nii yẹ ni ọjọ igbedide titi ti wọn o fi bi i nipa ọjọ ori rẹ nibo ni o pari rẹ si, ati nipa imọ rẹ kini o fi ṣe, ati nipa dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ati pe nibo ni o na an si, ati nipa ara rẹ nibo ni o lo o si».
Tirmiziy ni o gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju ẹnikẹni ninu awọn eeyan ko nii tayọ aaye iṣiro iṣẹ ni ọjọ igbedide lọ si alijanna tabi ina titi ti wọn o fi bi i nipa awọn alamọri kan: Alakọkọọ: Iṣẹmi rẹ nibo ni o pari rẹ sí? Ẹlẹẹkeji: Imọ rẹ njẹ o wa a nitori ti Ọlọhun? Ati pe njẹ o fi ṣiṣẹ ṣe? Ati pe njẹ o mu un de ọdọ ẹni ti o lẹtọọ si i? Ẹlẹẹkẹta: Dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ṣe nibi ẹtọ ni abi níbi eewọ? Ati pe nibo ni o na an si, ṣe ibi nkan ti o yọ Ọlọhun ninu ni abi ibi ti o bi I ninu? Ẹlẹẹkẹrin: Ara rẹ ati agbara rẹ ati alaafia rẹ ati ọdọ rẹ nibo ni o lo o si?
Lati ọdọ An-Nu‘mān ọmọ Bashīr - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Apejuwe awọn Mumuni nibi nini ifẹ ara wọn ati kikẹ ara wọn ati nini aanu ara wọn da gẹgẹ bi apejuwe odidi ara, nigba ti orike kan ba n ke irora gbogbo ara yoku ni yio para pọ pẹlu rẹ nibi aisun ati igbona.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju o jẹ dandan ki ìṣesí awọn Musulumi pẹlu ara wọn o maa jẹ nibi nini ifẹ daadaa ati ikẹ ati ikunlọwọ ati aranṣe, ati titara pẹlu nkan ti o ba ṣẹlẹ si wọn ni inira, gẹgẹ bii ara kan soso, nigba ti oríkèé kan ninu rẹ ba ṣe aisan, gbogbo ara ni yio ba a ṣe papọ nibi aisun ati igbona.