





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Dajudaju Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- kọ fun yin lati maa bura pẹlu awọn baba yin", Umar sọ pe: Mo fi Ọlọhun bura, mi ko bura pẹlu rẹ lati igba ti mo ti gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti kọ kuro nibẹ ni ti ẹni ti o mọọmọ tabi ni ẹni tí ó gbé ìbúra ẹlòmíràn pẹ̀lú rẹ wa.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- kọ kuro nibi bibura pẹlu awọn baba, ẹni ti o ba fẹ búra, ko gbọdọ bura afi pẹlu Ọlọhun, ko si gbọdọ bura pẹlu ẹni ti o yàtọ̀ si i. Lẹyin naa, Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe oun ko bura pẹlu rẹ lati igba ti o ti gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti kọ kuro nibi ìyẹn, ni ẹni ti o mọọmọ tabi ni ẹni ti o n gbé ọrọ ẹni ti o yàtọ̀ si i wa ti o bura pẹlu ẹni ti o yàtọ̀ si Ọlọhun.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Akọkọ nnkan ti wọn maa ṣe idajọ rẹ laaarin awọn eniyan ni ọjọ igbedide ni nibi awọn ẹjẹ".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju akọkọ nnkan ti wọn maa ṣe idajọ rẹ laaarin awọn eniyan nibi abosi apa kan si apakan ni ọjọ igbedide ni: Nibi awọn ẹjẹ, gẹgẹ bii pipa ènìyàn ati awọn ọgbẹ.
Lati ọdọ ọmọ Abbās - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọja nibi saare meji kan, ni o wa sọ pe: «Dajudaju wọn n jẹ awọn mejeeji niya lọwọ, wọn o si jẹ wọn niya nitori alamọri nla kan (ni iwoyesi awọn eeyan), ẹ o wa ri ọkan ninu awọn mejeeji o jẹ ẹni ti kii mọra kuro nibi itọ, amọ ẹnìkejì o jẹ ẹni ti maa n gbé ọrọ ofofo kaakiri» lẹyin naa ni o wa mu imọ ọpẹ tutu o si ya a si meji, ti o si tun ri ẹyọ kọọkan mọ saare kọọkan, wọn wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki ni idi ti o fi ṣe eleyii? O sọ pe: «O ṣee ṣe ki wọn o ṣe iya awọn mejeeji ni fufuyẹ lopin igba ti wọn o ba tii gbẹ (imọ ọpẹ)».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọja nibi saare meji kan, ni o wa sọ pe: Dajudaju awọn meji ti wọn ni saare mejeeji yii wọn n jẹ wọn niya lọwọ; ati pe wọn o jẹ wọn niya lori alamọri ti o tobi ni iwoyesi yin, bi o tilẹ̀ jẹ́ pé o tobi lọdọ Ọlọhun, Ẹ o wa ri ọkan ninu awọn mejeeji o jẹ ẹni ti ko ni akolekan nipa ṣiṣọ ara rẹ ati aṣọ rẹ kuro nibi itọ nigba ti o ba n gbọ bukaata rẹ, Ati pe ikeji maa n ṣe ofofo laarin awọn eeyan, ti yio wa maa gbe ọrọ ẹni ti o yatọ si i ni erongba ifi-ara-ni ati dida iyapa ati ogun silẹ laarin awọn eeyan.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ṣé ki n sọ ọrọ kan fun yin nipa dajjal, ti Anabi kan ko sọ nipa rẹ ri fun ijọ rẹ? O jẹ olójú kan, o maa mu nnkan ti o da bii alujanna ati ina wa pẹlu rẹ, eyi ti o n pe ni alujanna ni ina, mo n ṣekilọ fun yin gẹgẹ bi Nuh ṣe ṣekilọ fun ijọ rẹ pẹlu rẹ".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fun awọn saabe rẹ nipa dajjal ati awọn iroyin rẹ ati awọn ami rẹ pẹlu nǹkan ti Anabi kan ko sọ ri ṣíwájú rẹ, ninu ìyẹn ni: Pe o jẹ olójú kan. Ati pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- fi nnkan ti o daa bii alujanna ati ina pẹlu rẹ, ni ibamu si riri oju. Ṣugbọn alujanna rẹ jẹ iná, ti ina rẹ si jẹ alujanna, ẹni ti o ba tẹle e o maa mu u wọ inu alujanna yii ninu nnkan ti awọn eniyan n ri, ṣùgbọ́n ina ti o n jóni ni, ẹni ti o ba yapa rẹ o maa mu u wọ ina ninu nnkan ti awọn eniyan n ri, ṣùgbọ́n alujanna ti o daa ni, Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣekilọ fun wa kuro nibi wahala rẹ gẹgẹ bi Nuh ṣe ṣekilọ fun ijọ rẹ pẹlu rẹ.
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Ẹ yára si awọn iṣẹ daadaa siwaju ki awọn fitina kan ti yio da bii oru ti o ṣokunkun gan o to de, ti ọmọniyan o ji ni mumini ti yio si di alẹ ni keferi, tabi ki o di alẹ ni mumini ki o si ji ni keferi, ti yio ta ẹsin rẹ tori adun aye ti ko nii pẹ tan.
Muslim gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe mumini ni ojukokoro pẹlu yiyara ati pipọ ni ṣíṣe awọn iṣẹ oloore siwaju nínira rẹ ati kiko airoju kuro nibẹ latari dide awọn fitina ati iruju ti yio dena rẹ, ti yio si ṣẹri àwọn kúrò nibẹ, ati pe okunkun kan ni ti o da bi okunkun oru, ti ododo ati irọ maa dapọ nibẹ, ti yio si le fun awọn eeyan lati ṣe iyatọ laarin mejeeji, ati pe latari lile rẹ (fitina) ọmọniyan o nii mọ nǹkan ti o fẹ ṣe, débi pe yio ji ni mumini ti yio si di alẹ ni keferi, tabi ki o di alẹ ni mumini ki o si ji ni keferi, yio fi ẹsin rẹ silẹ fun adun aye ti yio tan.
Lati ọdọ Huzaifah- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ẹ ko gbọdọ sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti lagbaja ba fẹ, ṣùgbọ́n ẹ maa sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ lẹyin naa ti lagbaja ba fẹ".
Abu Daud ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú al-Kubrọ, ati AhmadAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ kuro nibi ki Musulumi maa sọ nibi ọrọ rẹ pé: "Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti lagbaja ba fẹ", Tabi ohun ti Ọlọhun ati lagbaja ba fẹ; Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nitori pe fifẹ Ọlọhun ati erongba rẹ jẹ nnkan ti a tu kalẹ ti ẹnikẹni ko si ba A kẹgbẹ nibẹ, Ati pe o n bẹ nibi lilo harafi waw nibi asopọ naa, imuninimọlara pe ẹnìkan n ba Ọlọhun kẹgbẹ ati ifidọgba láàrin ẹni yẹn ati Ọlọhun. Ṣugbọn yoo maa sọ pé: Ti Ọlọhun ba fẹ, lẹyin naa ti lagbaja ba fẹ, Ki o fi fifẹ ẹru tẹle fifẹ Ọlọhun pẹlu sisọ pe: "Thummo" dipo "Wa", nitori pe "Thummo" n ṣe àǹfààní ki nǹkan wa lẹyin ati lilọra.
Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khudriy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Dajudaju ẹ ma maa tẹle oju ọna awọn ti wọn ṣáájú yin, ni odiwọn ìbú atẹlẹwọ si ibu atẹlẹwọ, ni odiwọn apa si apa, koda ki wọn wọnu isa agilinti ẹ maa tẹle wọn" a sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, awọn Juu ati Nasara àbí? O sọ pe: "Taa waa tún ni?".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n fun wa ni iro nipa nnkan ti isesi awọn kan ninu ìjọ rẹ maa wa lori rẹ lẹyin ti o ba lọ tan, oun ni itẹle oju ọna Juu ati Nasara nibi awọn adisọkan wọn ati awọn iṣe wọn ati awọn àṣà wọn ni itẹle kan ti o péye ti o lágbára ni odiwọn ibu atẹlẹwọ si ibu atẹlẹwọ, ni odiwọn apa si apa, koda ki wọn wọnu isa agilinti awọn wọnyii maa wọle lẹyin wọn.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba pepe lọ si ibi imọna, iru awọn ẹsan ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹsan, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹsan wọn, ati pe ẹni ti o ba pepe lọ si ibi anu, iru awọn ẹṣẹ ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹṣẹ, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹṣẹ wọn".
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o fi eniyan mọna ti o si tọka ti o si ṣe awọn eniyan lojukokoro lọ sibi oju ọna kan ti ododo ati daadaa n bẹ nibẹ pẹlu ọrọ tabi iṣẹ, iru ẹsan ẹni ti o tẹle e n bẹ fun un laisi pe ìyẹn maa din nnkan kan ku ninu ẹsan olutẹle náà. Ati pe ẹni ti o ba dari ti o si tọka awọn eniyan lọ sibi oju ọna ibajẹ ati aburu, ti ẹṣẹ ati àṣìṣe tabi ti àlámọ̀rí ti ko lẹtọọ n bẹ nibẹ, pẹlu ọrọ tabi iṣẹ, iru ẹṣẹ ẹni ti o tẹle e n bẹ fun un laisi pe ìyẹn maa din nnkan kan ku ninu awọn ẹṣẹ wọn.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni,- lẹẹmẹta-", ko si ninu wa afi, ṣùgbọ́n Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- n mu u lọ pẹlu igbarale Ọlọhun.
Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe ikilọ kuro nibi fifi ẹyẹ fura mọ aburu, oun ni fifuramọ aburu latara eyikeyii nnkan kan ti a le gbọ́ lo jẹ ni tabi ti a le ri, ninu awọn ẹyẹ tabi awọn ẹranko tabi awọn oni aisan tabi awọn onka tabi awọn ọjọ tabi eyi ti o yàtọ̀ si wọn, Ṣugbọn o dárúkọ awọn ẹyẹ nitori pe o gbajumo nigba aimọkan, ati pe ipilẹ rẹ ni títú awọn ẹyẹ silẹ nigba ti wọn ba fẹ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ kan bii irin-ajo tabi okowo tabi eyi ti o yàtọ̀ si ìyẹn, ti o ba fo si apa ọtun, yoo ni ifuramọ daadaa yoo si maa ba nnkan ti o fẹ ṣe lọ, ti o ba fo si apa osi, yoo ni ifuramọ aburu yoo si da ọwọ duro kuro nibi nnkan ti o fẹ ṣe. O sọ pe dajudaju ẹbọ ni, ifuramọ aburu ẹbọ ni; nitori pe ko si ẹni ti o le mu daadaa wa afi Ọlọhun, ko si si ẹni ti o le ti aburu danu afi Ọlọhun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un. Ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe nnkan kan ninu ifuramọ aburu le waye ninu ọkan Musulumi, ṣùgbọ́n o jẹ dandan fun un lati fi igbarale Ọlọ́hun ti i danu, pẹlu ṣíṣe awọn okunfa.