





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Abu Maalik Al-Ash’ari- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Imọra ni idaji igbagbọ, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH maa n kun òṣùwọ̀n, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH ati gbolohun SUBHAANALLAH, mejeeji maa n kun- tabi o n kun- nnkan ti o n bẹ laaarin sanmọ ati ilẹ, ati pe irun jẹ imọlẹ, saara jẹ awijare, suuru jẹ imọlẹ, Kuraani maa jẹ ẹri fun ẹ tabi ki o tako ẹ, gbogbo eniyan yoo maa jáde lọ ní aarọ ni ẹni ti o n ta ẹmi ara rẹ, ninu ki o la a kúrò ninu iná, tabi ki o ko ìparun ba a”.
Muslim gba a waOjiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: Dajudaju imọra ti ìta maa jẹ pẹlu aluwala ati iwẹ, ati pe o jẹ majẹmu fun irun. Ati pe sisọ gbolohun: “ALHAMDULILLAH, o n kun òṣùwọ̀n”, oun ni ẹyin fun Un- mimọ ni fun Un-, ati ìròyìn rẹ pẹlu ìròyìn pipe, wọn maa wọn ọn ni ọjọ́ igbende alukiyaamọ, o maa waa kún òṣùwọ̀n iṣẹ. Ati pe sisọ gbolohun: “Subhaanallah ati Alhamdulillah” oun ni ṣíṣe afọmọ Rẹ kuro nibi gbogbo adinku ati riroyin Rẹ pẹlu pipe ti o pe ti o tọ si titobi Rẹ pẹlu nini ifẹ Rẹ ati gbigbe E tobi, yoo kun nnkan ti o wa laaarin sanmọ ati ilẹ. Ati pe “irun jẹ imọlẹ” fun ẹru ni ọkan rẹ, ati ni oju rẹ, ati ninu sàréè rẹ, ati nibi igbedide rẹ. Ati pe “Saara ṣíṣe jẹ awijare” ati ẹri lori ododo igbagbọ olugbagbọ, ati iyapa rẹ si ṣọbẹ-ṣelu ti kii ṣe saara; nitori pe ko ni igbagbọ si ohun ti wọn ṣe adehun rẹ lórí saara ṣíṣe. Ati pe “Suuru ṣíṣe jẹ imọlẹ” -oun ni kiko ẹ̀mí ro nibi ìgbónára ati ibinu- imọlẹ kan ni ti igbona ati jijo nkan maa n waye pẹlu rẹ, gẹgẹ bii imọlẹ oòrùn; nitori pe nnkan ti o nira ni, o si n bukaata si jija ẹ̀mí naa logun ati dide e kuro nibi nnkan ti o n fẹ; ẹni ti o ba ni i ko nii yẹ ko nii gbo ni ẹni ti yoo maa mọna ti yoo si maa tẹsiwaju lori nnkan ti o tọna. Oun ni ṣíṣe suuru lori itẹle ti Ọlọhun, ati kuro nibi ẹṣẹ, ati suuru ṣíṣe lori awọn ajalu ati awọn oniran-anran àwọn nnkan ti eeyan korira ni ayé. Ati pe “Kuraani jẹ awijare fun ẹ” pẹlu kika a ati ṣíṣe ìṣẹ́ pẹlu rẹ, tabi “awijare tako ẹ” pẹlu gbigbe e ju silẹ lai fi ṣe iṣẹ́ tabi kika a. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju gbogbo eniyan n gbiyanju ti wọn n fọnka ti wọn si n dide lati oju orun wọn ti wọn n jade lati inu awọn ile wọn tori awọn ìṣẹ́ wọn ni oríṣiríṣi, O wa ninu wọn ẹni ti o n duro deedee lori itẹle ti Ọlọhun ti yoo tu ẹ̀mí rẹ kuro ninu ina, o si wa ninu wọn ẹni ti yoo yẹ kuro nibi ìyẹn ti yoo si ko si inu awọn ẹṣẹ ti yoo si pa a run pẹlu wiwọ ina.
Lati ọdọ Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i-, o sọ pe: Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori kẹtẹkẹtẹ kan ti wọn n pe ni ‘Ufair, o sọ pe: “Irẹ Mu’aadh, njẹ o mọ iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin Rẹ, ati nnkan ti o jẹ iwọ àwọn ẹrusin lori Ọlọhun?”, mo sọ pe: Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “Dajudaju iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni ki wọn maa jọsin fun Un ki wọn si ma da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ, iwọ àwọn ẹrusin lori Ọlọhun ni ki O ma fi iya jẹ ẹni ti ko ba da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ”, mo sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ṣe ki n maa fun awọn eniyan ni iro idunnu nipa rẹ? O sọ pe: “Rara, ma fun wọn ni iro ìdùnnú, ki wọn ma baa gbára lé e”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin, ati iwọ awọn ẹrusin lori Ọlọhun, ati pe iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni ki wọn maa jọsin fun Un ni Oun nikan ṣoṣo ki wọn si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ, Ati pe iwọ awọn ẹrusin lori Ọlọhun ni ki O ma fi iya jẹ awọn ti wọn mu U ni Ọkan ti wọn ko da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ. Lẹyin naa Mu’aadh sọ pé: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, njẹ mi ko nii fun awọn eniyan ni iro ki wọn le dunnu pẹlu ọla yìí? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ fun un ni ti ipaya ki wọn maa gbe ara le e.
Lati ọdọ Jabir- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Arakunrin kan wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ki ni nnkan meji naa ti wọn maa n sọ nǹkan di dandan? O sọ pe: “Ẹni ti o ba ku ti ko da ẹbọ kankan pọ mọ Ọlọhun yoo wọ alujanna, ẹni ti o ba si ku ti o da ẹbọ pọ mọ Ọlọhun yoo wọ ina".
Muslim gba a waArakunrin kan beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa pe iroyin meji naa wo ni yoo sọ wiwọ alujanna di dandan, ati ti yoo sọ wiwọ ina di dandan? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- da a lohun pe: Dajudaju ìròyìn ti yoo sọ wiwọ alujanna di dandan ni ki ọmọniyan ku ti o si n jọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo ti ko da ẹbọ kankan pọ mọ Ọn, Ati pe iroyin ti yoo sọ wiwọ ina di dandan ni ki ọmọniyan ku ti o si n da ẹbọ pọ mọ Ọlọhun ti yoo wa orogun ati olubakẹgbẹ fun Ọlọhun nibi ìní ẹtọ si ìjọsìn Rẹ tabi nibi jijẹ Oluwa Rẹ tabi nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ.
Lati ọdọ Sufyan ọmọ Abdullahi Ath-Thaqoofiy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, sọ ọrọ kan fun mi ninu Isilaamu ti mi ko nii bi ẹnikẹni leere nípa rẹ yàtọ̀ si ẹ, o sọ pe: "Sọ pe: Mo gbagbọ ninu Ọlọhun, lẹyin naa ki o duro deedee".
Muslim ati Ahmad ni wọ́n gba a waSaabe Sufyan ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere lati kọ oun ni ọrọ kan ti o ko awọn ìtumọ̀ Isilaamu sinu, ti oun maa dirọ mọ ọn, ti oun ko si nii bi ẹni ti o yàtọ̀ si i leere nipa rẹ? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pé: sọ pe Mo mu Ọlọhun lọkan, mo si gbagbọ pe Oluwa mi ni ati Ọlọhun mi ati Aṣẹ̀dá mi ati Ẹni ti maa maa jọsin fun lododo ti ko si orogun fun Un, Lẹyin naa, yoo tẹ fun itẹle Ọlọhun pẹlu ṣíṣe awọn ọran-anyan Ọlọhun ati gbigbe awọn eewọ Ọlọhun ju silẹ ti yoo si maa tẹsiwaju lori rẹ.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dajudaju Ọlọhun maa ya arákùnrin kan sọ́tọ̀ nínú ìjọ mi lójú àwọn ẹ̀dá ni ọjọ́ igbende alukiyaamọ, O maa ṣí ìwé iṣẹ mọkandinlọgọrun-un fun un, ìwé kọ̀ọ̀kan gùn ni odiwọn ibi tí ojú bá le rína dé, lẹyin naa O maa sọ pé: Ǹjẹ́ nǹkan kan n bẹ nínú eyi ti o fẹ takò? Ǹjẹ́ àwọn malaika òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá ti wọn jẹ oluṣọ ṣe àbòsí rẹ bi? O maa sọ pé: Rara, Irẹ Olúwa mi, O maa sọ pé: Ǹjẹ́ o ni àwíjàre kankan bi? O maa sọ pé: Rárá, Irẹ Oluwa mi, O maa sọ pé: Ko ri bẹẹ, dájúdájú o ni iṣẹ rere kan ni ọdọ Wa; torí pé ko si àbòsí fun ẹ ni oni, wọn maa wa mu iwe pélébé kan jáde ti ohun ti o wa ninu rẹ jẹ: ASH’HADU AN LAA ILAAHA ILLALLOHU, WA ASH’HADU ANNA MUHAMMADAN ABDUHUU WA ROSUULUHUU, O maa sọ pé: Mu òṣùwọ̀n rẹ wá, o maa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, iwe pélébé wo ni o wa pẹ̀lú àwọn ìwé iṣẹ yii? O maa sọ pé: Wọn ko nii ṣe abosi fun ọ, o sọ pe: Wọn maa gbe àwọn ìwé iṣẹ naa sórí abọ́ òṣùwọ̀n kan, wọn si maa fi iwe pélébé naa sórí abọ́ òṣùwọ̀n mii, ni àwọn iwe iṣẹ naa maa di ohun ti o fúyẹ́, ti iwe pélébé naa si maa wúwo, ko si nnkan kan ti o le wuwo ju orúkọ Ọlọhun lọ”.
Tirmiziy ati Ibnu Maajah ni wọn gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun maa ṣẹsa arakunrin kan ninu ijọ rẹ lójú awọn ẹda ni ọjọ igbedide, wọn maa pe e lati ṣe ìṣirò iṣẹ fun un, O si maa fi iwe àkọsílẹ̀ mọkandinlọgọrun-un han an, àwọn naa ni awọn iwe awọn iṣẹ aburu rẹ ti o n ṣe ni aye, ati pe òró iwe àkọsílẹ̀ kọọkan gùn ni ìwọ̀n ibi tí irina ba dé, Lẹyin naa Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ fun arakunrin naa pe: Njẹ waa tako nnkankan ninu nnkan ti wọn kọ sinu awọn iwe àkọsílẹ̀ yii? Njẹ awọn Mọlaika mi Olùṣọ́ Olukọwe ṣe abosi rẹ? Arakunrin naa maa sọ pé: Rara Oluwa mi. Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ pé: Njẹ awijare n bẹ fun ẹ ninu nnkan ti o ti siwaju ninu awọn iṣẹ ni aye? Bóyá o jẹ igbagbe tabi àṣìṣe tabi aimọkan, Arakunrin naa maa sọ pé: Rara Oluwa mi, mi ko ni awijare kankan. Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ pé: Bẹẹ kọ, dajudaju daadaa kan n bẹ fun ẹ lọdọ wa, ati pe ko si abosi kan fun ẹ lónìí. O sọ pe: Yoo mu kaadi kan jade ti wọn kọ sibẹ pé: Mo n jẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn tọ si ni ododo afi Allahu, mo si n jẹrii pe Muhammad ẹrusin Ọlọhun ni ati Ojiṣẹ Rẹ. Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ fun arakunrin yii pé: Mú òṣùwọ̀n rẹ wa. Arakunrin naa maa sọ ni ẹni ti o n ṣe eemọ pé: Irẹ Oluwa mi! Ki ni òṣùwọ̀n kaadi yii já mọ́ ni ẹ̀gbẹ́ awọn iwe àkọsílẹ̀ yii? Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ pé: Abosi ko lee ṣẹlẹ̀ si ẹ lailai. O sọ pe: Wọn yoo gbe awọn iwe àkọsílẹ̀ naa sinu abọ́ òṣùwọ̀n kan, ati kaadi naa sinu abọ́ òṣùwọ̀n kan; bayii ni abọ́ òṣùwọ̀n ti awọn iwe àkọsílẹ̀ wa nibẹ maa di ohun ti o fuyẹ, ti abọ́ òṣùwọ̀n ti kaadi wa ninu rẹ maa tẹṣuwọn ti o maa wuwo, ni Ọlọhun ba maa fi ori jin in.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Nígbà tí Ọlọhun da alujanna ati ina, O ran Jibril- ki ọla maa ba a- lọ sí alujanna, O wa sọ pé: Wò ó, ki o si wo ohun ti Mo pèsè kalẹ̀ fun awọn ọmọ alujanna ninu rẹ. Ni o ba wo o, o si ṣẹri pada, ni o wa sọ pe: Mo fi agbara Rẹ bura, ko si ẹni kankan ti o maa gbọ nipa rẹ ti ko nii wọ̀ ọ́. Ni O ba pàṣẹ ki wọn fi àwọn nǹkan ti ẹmi korira rọkirika rẹ, O wa sọ pé: Tún lọ sibẹ, ki o si wo o ati ohun ti Mo pèsè kalẹ̀ fún àwọn ọmọ alujanna nínú rẹ̀. Ni o wa wo o, o si ba a pe wọn ti fi àwọn ohun tí ẹ̀mí korira rọkirika rẹ, o wa sọ pé: Mo fi agbara Rẹ bura, ẹ̀rù n ba mi ki ẹni kankan ma wọ ibẹ̀. O sọ pé: Lọ wo ina ati ohun ti Mo pèsè kalẹ fun awọn ọmọ ina nínú ẹ. O wo inu rẹ, ni o wa ri i ti o n gun ara wọn, o ṣẹri pada, o si sọ pé: Mo fi agbara Rẹ bura, ko si ẹni kankan ti o maa wọ̀ ọ́. Ni O wa ni ki wọn fi àwọn nǹkan ti ẹmi maa n gbádùn rọkirika rẹ, o padà, o si sọ pé: Mo fi agbara Rẹ bura, mo n paya ki ẹni kankan má là kúrò nibẹ ayafi ki o wọ̀ ọ́”.
Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun, nigba ti O da alujanna ati ina, O sọ fun Jibril- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- pé: Lọ si alujanna ki o si wo o, bayii ni o ṣe lọ, o si wo o, lẹyin naa o ṣẹri pada, Jubril si sọ pé: Irẹ Oluwa mi, mo fi agbara Rẹ bura ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa rẹ ati nipa nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu idẹra ati awọn oore afi ko fẹ lati wọ ọ, ki o si maa ṣe iṣẹ́ nitori rẹ. Lẹyin naa Ọlọhun wa fi awọn nnkan ti ẹmi korira ati awọn nǹkan ti ó le rọkirika alujanna bii ṣíṣe awọn nnkan ti wọn pa wa láṣẹ ati jijina si awọn nnkan ti wọn kọ̀; o wa jẹ dandan fun ẹni ti o ba fẹ wọ ọ lati re kọja awọn nnkan ti ẹmi korira yẹn. Lẹyin naa Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- sọ pé: Irẹ Jibril! Lọ ki o lọ wo alujanna, lẹyin igba ti O rọkirika rẹ pẹlu awọn nnkan ti ènìyàn korira, O si lọ wo o, lẹyin naa o sọ pe: Irẹ Oluwa mi, mo fi agbara Rẹ bura, mo n paya ki ẹnikẹni ma wọ ọ pẹlu okunfa awọn ilekoko ati awọn wahala ti wọn wa ni oju ọna rẹ. Nígbà ti Ọlọhun da ina, O sọ pe: Irẹ Jibril! Lọ ki o lọ wo o, o si lọ wo o, Lẹyin naa ni o dé, Jibril wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, mo fi agbara Rẹ bura, ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa iya ati awọn wahala ati ìfìyàjẹ ti o wa nínú rẹ̀ afi ki o korira lati wọ ọ ki o sì jina si awọn okunfa rẹ. Lẹyin naa Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- fi àwọn adùn rọkirika ina, O si ṣe wọn ni oju ọna lọ si ibẹ, lẹyin naa, O sọ pe: Irẹ Jibril, lọ ki o si wo o, Jibril si lọ o si wo o, lẹyin naa o de, o si sọ pe: Irẹ Oluwa mi, mo fi agbara Rẹ bura, dajudaju mo paya ẹru si ba mi pe ki ẹni kankan ma la kuro nibẹ; fun nnkan ti o rọkirika rẹ ninu awọn adun.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: "Ọlọhun kọ kadara awọn ẹda ṣíwájú ki O to da sanmọ ati ilẹ fun ẹgbẹrun lọ́nà aadọta ọdun, o sọ pe: Aga ọla Rẹ wa ni ori omi".
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun kọ nnkan ti o maa ṣẹlẹ̀ ninu awọn kadara awọn ẹda ni ifọsiwẹwẹ ninu isẹmi ati iku ati arisiki ati nnkan ti o yatọ si ìyẹn sinu Wàláà ti A n ṣọ ṣíwájú ki O to da sanmọ ati ilẹ fun ẹgbẹrun lọ́nà aadọta ọdun, ti yoo maa ṣẹlẹ̀ ni ibamu si nnkan ti Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ti kadara, Gbogbo nnkan ti o n bẹ n bẹ pẹlu idajọ Ọlọhun ati kadara Rẹ, Nnkan ti o ba ṣẹlẹ̀ si ẹru wọn ti kọ ọ pe ko nii fo o ru, nnkan ti o ba fo o ru wọn ti kọ ọ pe ko nii ṣẹlẹ̀ si i ni.
Lati ọdọ Jaabir – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Mo gbọ ti Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe: «Dajudaju nkan ti n bẹ laarin ọmọniyan ati mimu orogun mọ Ọlọhun ati ṣiṣe keferi ni gbigbe irun jù silẹ».
Muslim gba a waAnabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – kilọ kuro nibi gbigbe irun ọranyan ju silẹ, o si tun sọ pe dajudaju nkan ti n bẹ laarin ọmọniyan ati kiko sinu imu orogun mọ Ọlọhun ati iṣe keferi ni gbigbe irun ju silẹ, nitori naa irun ni origun keji ninu awọn origun Isilaamu, ati pe ipo rẹ tobi ninu Isilaamu, nitori naa ẹni ti o ba gbe e ju silẹ l’ẹni ti n tako ijẹ dandan rẹ o ti di keferi pẹlu apanupọ gbogbo Musulumi, ati pe ti o ba gbe e ju silẹ patapata ni ti ifi ọwọ dẹngẹrẹ mu un ati ni ti oroju, o ti di keferi, wọn si tun gba ipanupọ awọn saabe wa lori iyẹn, ti o ba wa jẹ pe o maa n fi i silẹ ni igba miran ti yio si tun ki i ni igba miran, nigba naa o ti ni ẹtọ si adehun iya to ni agbara yii.
Lati ọdọ Buraida- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dajudaju adehun ti o wa laaarin wa ati laaarin wọn ni irun, ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, dajudaju o ti ṣe aigbagbọ”.
Tirmiziy ati Nasaa'iy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju adehun ati majẹmu ti o wa laaarin awọn Musulumi ati laaarin awọn ti wọn yatọ si wọn ninu awọn alaigbagbọ ati awọn ṣọbẹ-selu ni irun kiki, ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, dajudaju o ti ṣe aigbagbọ.