





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Tooriq ọmọ Ashyam Al-Ash-ja'iy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ẹni ti o ba sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOHU, ti o wa ṣe aigbagbọ pẹlu nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun, dukia rẹ ati ẹjẹ rẹ ti jẹ eewọ, ati pe ìṣirò rẹ wa lọ́wọ́ Ọlọhun”.
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba sọ ti o si jẹrii pẹlu ahọn rẹ pe “LAA ILAAHA ILLALLOHU”, o n túmọ̀ si pe: Ko si ẹni ti a le jọsin fun pẹ̀lú ẹ̀tọ́ afi Ọlọhun, ti o wa ṣe aigbagbọ pẹlu nnkan ti wọn jọsin fun yatọ si Ọlọhun, ti o bọpa-bọsẹ kuro nibi gbogbo awọn ẹsin yatọ si Isilaamu, dajudaju dukia rẹ ati ẹjẹ rẹ jẹ eewọ fun awọn Musulumi, ohun ti ó kàn wa ni eyi ti o han ninu iṣẹ rẹ, wọn ko nii gba dukia rẹ, wọn ko si nii ta ẹjẹ rẹ silẹ, afi ti o ba da ẹṣẹ kan tabi wuwa ọdanran kan ti o maa sọ ìyẹn di dandan ni ìbámu si awọn idajọ Isilaamu. Ati pe Ọlọhun ni yoo ṣe ìṣirò rẹ ni ọjọ igbedide, ti o ba jẹ olododo yoo san an lẹsan, ti o ba jẹ sọbẹ-selu yoo fi iya jẹ ẹ.
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amri – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji – dajudaju Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Awọn olùṣe ikẹ, Ọlọhun Ajọkẹ aye maa kẹ wọn, ẹ maa kẹ awọn ti n bẹ lori ilẹ, Ọba ti n bẹ ni sanmọ a kẹ ẹyin naa».
Abu Daud ati Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a waAnabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n ṣe alaye pe dajudaju awọn ti wọn maa n kẹ awọn ti wọn yatọ si wọn, Ọba Ajọkẹ aye naa o kẹ wọn pẹlu ikẹ Rẹ ti o kari gbogbo nkan; ní ti ẹ̀san t’ó ṣe wẹ́kú (iṣẹ́ wọn). Lẹyin naa ni o wa pa aṣẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pẹlu kikẹ gbogbo nkan ti o wa lori ilẹ ni eeyan tabi ẹranko tabi ẹyẹ tabi nkan ti o yatọ si i ninu awọn iran ẹda, ati pe ẹsan iyẹn naa ni ki Ọlọhun kẹ wọn lati oke awọn sanmọ Rẹ.
Lati ọdọ ‘Āisha – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Awọn eeyan kan bi Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – leere nipa awọn adagbigba, ni Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – wa sọ fun wọn pe: «Wọn o jẹ nkankan» wọn sọ pé: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju wọn maa n sọ awọn nkan ni igba miran ti yio si jẹ ododo, ni Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – wa sọ pe: «Ọrọ yẹn ninu ododo ti alujannu n ji gbọ ni o wa, yoo waa gbe e si eti aayo rẹ gẹgẹ bi adiyẹ ṣe maa n gbe ọrọ fun adiyẹ miran, nigba naa ni wọn o waa ro irọ to le ni ọgọrun-un mọ ọn».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niWọn bi Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – leere nipa awọn ti wọn maa n sọ nipa awọn kọkọ ti yio ṣẹlẹ ni ọjọ iwaju, ni o wa sọ pe: Ẹ ma bikita pẹlu wọn, Ẹ si ma di ọrọ wọn mu, alamọri wọn o si gbọdọ pataki si yin. Ni wọn wa sọ pe: Dajudaju ọrọ wọn maa n ṣe deedee nkan ti n ṣẹlẹ ni igba miran, gẹgẹ bii ti wọn ba sọ nipa iṣẹlẹ alamọri kọkọ kan ni oṣu bayii ni ọjọ bayii, ti yio si ṣẹlẹ ni ibamu si ọrọ wọn. Ni o wa sọ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pe: Dajudaju awọn alujannu maa n ji awọn iroyin sanmọ gbọ, nigba naa ni wọn yio wa sọkalẹ wa ba awọn aayo wọn ninu awọn adagbigba ti wọn o si fun wọn ni iro nkan ti wọn gbọ, lẹ́yìn naa ni adagbigba o fi irọ ọgọrun-un kun eyi ti o gbọ lati sanmọ.
Láti ọ̀dọ̀ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- pe: Mu’aadh wa lẹ́yìn Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori nnkan ọgun, o sọ pe: “Irẹ Mu’aadh ọmọ Jabal”, o sọ pe: Mo n da ẹ lohun irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mo si n wa oriire fun dida ẹ lóhùn, o tun sọ pe: “Irẹ Mu’aadh”, o sọ pe: Mo n da ẹ lohun irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mo si n wa oriire fun dida ẹ lóhùn, lẹẹmẹta, o sọ pe: “Ko si ẹni kankan ti o n jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin tọ si lododo afi Allahu, ati pe Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni lododo lati inu ọkan rẹ, afi ki Ọlọhun ṣe ina leewọ fun un”, o sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, njẹ mi ko nii maa sọ ọ fun awọn eniyan ki wọn le dunnu? O sọ pe: “Ti o ba ri bẹẹ wọn maa gbara le e”. Ni Mu’aadh wá sọ ọ́ nigba ti o fẹ ku ki o ma baa kó sínú ẹṣẹ.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niMu’aadh ọmọ Jabal- ki Ọlọhun yọnu si i- wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori nǹkan ọ̀gùn rẹ, o wa pe e: Irẹ Mu’aadh? O paara pipe e rẹ lẹẹmẹta; lati fi pataki nnkan ti o fẹ sọ rinlẹ. Ati pe gbogbo ìyẹn ni Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i- n da a lohun pẹlu ọrọ rẹ pé: “LABBAEKA YAA ROSUULALLOOHI WA SAHDAEK”, o n túmọ̀ sí pe: Mo n da ẹ lohun irẹ ojiṣẹ Ọlọhun ni idahun kan lẹyin idahun, mo si n tọrọ oriire fun jijẹ ìpè rẹ. Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pe ko si ẹnikẹni ti o n jẹrii pe LAA ILAAHA ILLALLOOH, itumọ rẹ ni pe: Ko si ẹni ti a le jọsin fun pẹ̀lú ẹ̀tọ́ afi Ọlọhun, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, lododo lati inu ọkan rẹ lai parọ, ti o ba ku lori iṣesi yii, Ọlọhun maa ṣe ina leewọ fun un. Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i- wa beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe ṣe ki oun sọ ọ fun awọn eniyan ki wọn le yọ ki wọn si dunnú si dáadáa? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa paya pe ki wọn ma baa gbara le e, ti iṣẹ wọn fi maa kere. Mu’aadh ko sọ hadiisi naa fun ẹnikẹni afi ṣiwaju iku rẹ; ni ti ipaya kikosi inu ẹṣẹ fifi imọ pamọ.
Lati ọdọ Abu Hurayra – ki Ọlọhun yọnu si i– dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Oluwa wa ti ọla Rẹ ga maa n sọkalẹ ni gbogbo oru si sanmọ aye nigba ti o ba ṣẹku idamẹta igbẹyin, yio wa maa sọ pe: «Tani yio pe Mi ki n maa da a lohun? Tani yio bi Mi leere ki n si maa fun un? Tani yio wa aforijin Mi ki n si ṣe aforijin fun un?».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga maa n sọkalẹ ni gbogbo oru si sanmọ aye nigba ti o ba ku idamẹta igbẹyin ninu oru, O si tun n ṣe awọn ẹru Rẹ ni ojukokoro ki wọn o pe E, pe Oun yio jẹ ipe ẹni ti o ba pe Oun, O si tun ṣe wọn ni oju ọyin ki wọn o bi I leere nkan ti wọn n fẹ, pe Oun yio fun ẹni ti o ba bi Oun leere, O si tun pe wọn sibi ki wọn wa aforijin Rẹ nibi awọn ẹṣẹ wọn pe Oun maa n ṣe aforijin fun awọn ẹru Oun ti wọn jẹ olugbagbọ ododo.
Lati ọdọ Abu Marthad Al-ganawiy – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹ ma ṣe jokoo si ori awọn sàréè, ẹ ko si gbọdọ kirun si i lara».
Muslim gba a waAnabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – kọ kuro nibi jijokoo si ori awọn sàréè. Gẹgẹ bi o ṣe kọ kuro nibi kiki irun si awọn sàréè, bii ki sàréè o wa ni agbegbe idojukọ olukirun; nitori pe dajudaju ìyẹn wa ninu awọn atẹgun imu-orogun-mọ Ọlọhun.
Lati ọdọ 'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju Ummu Salamah dárúkọ ṣọọṣi kan ti o ri ni ilẹ̀ Habasha fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, wọn n pe e ni Maariyah, o wa sọ nnkan ti o ri nibẹ fun un ninu awọn aworan, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pe: "Awọn wọnyẹn ni ìjọ kan, ti ẹru rere ba ku ninu wọn tabi ọkùnrin rere, wọn maa kọ mọsalasi kan sori saare rẹ, wọn yoo si ya awọn aworan yẹn síbẹ̀, awọn wọnyẹn ni awọn ti wọn buru julọ ninu ẹda lọdọ Ọlọhun".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niIya awọn olugbagbọ Ummu Salamah- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe dajudaju nigba ti oun fi wa lori ilẹ Habasha, oun ri ṣọọṣi kan- wọn n pe e ni Maariyah- ti awọn aworan ati awọn ẹṣọ ati awọn fọto n bẹ nibẹ; ni ti ìyàlẹ́nu latara ìyẹn! Bayii ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ṣàlàyé awọn okunfa gbigbe awọn aworan yii síbẹ̀; O sọ pe: Dajudaju awọn ti o dárúkọ wọnyii ti ẹni rere ba ku laaarin wọn, wọn maa kọ mọsalasi kan sori saare rẹ ti wọn ma maa kirun nibẹ, ti wọn si maa ya awọn aworan yẹn, O ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe yẹn jẹ ẹni ti o buru julọ ninu ẹda lọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-; nitori pe iṣe rẹ maa ja si dida orogun pọ mọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Wọn mọ Isilaamu pa lori nkan márùn-ún: Ijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad ẹru Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni, ati imaa gbe irun duro, ati imaa yọ zakah, ati imaa gbero ile Oluwa, ati gbigba aawẹ Ramadan».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fi Isilaamu jọ ile kan ti wọn mọ daadaa pẹlu origun maarun ti o gbe ile naa duro, ti awọn iwa Isilaamu ti o sẹku jẹ pipari ile naa. Akọkọ awọn origun yii ni: Ijẹrii mejeeji; ijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Rẹ ni, ati pe origun kan ni mejeeji; ti ọkan o lee ja kuro lara ìkejì, ẹru o sọ mejeeji ni ẹni ti n fi ijẹ ọkan ṣoṣo Ọlọhun ati lilẹtọọ Rẹ si ijọsin ni Oun nikan ṣoṣo laisi ẹlòmíràn yatọ si i rinlẹ, ti yio si maa ṣiṣẹ tọ awọn nkan ti o n tọka si, ki o si tun gba iransẹ Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - gbọ ni ẹni ti yio maa tẹle e. Origun keji ni: Gbigbe irun duro, oun naa ni awọn irun ọranyan marun-un ni ojumọ kan ati oru kan: Alufajari, ati Àílà, ati Alaasari, ati Magribi, ati Ishai, pẹlu awọn majẹmu wọn ati awọn origun wọn ati awọn ọranyan wọn. Origun kẹta ni: Yiyọ zakah ọranyan, oun naa ni ijọsin owo ti o jẹ dandan nibi gbogbo dukia ti o ba ti to odiwọn ti wọn fi aala si ninu shariah, ti wọn o fun awọn ti wọn ni ẹtọ si i. Origun kẹrin ni: Hajji, oun naa ni gbigbero Makkah lati gbe awọn iṣẹ ìjọsìn duro, ni ti jijọsin fun Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn. Origun karun-un ni: Aawẹ Ramadan, oun naa ni kikoraro nibi jijẹ ati mimu ati nkan ti o yatọ si mejeeji ninu awọn nkan ti o le ba aawẹ jẹ pẹlu aniyan jijọsin fun Ọlọhun, lati igba ti alufajari ba ti yọ titi ti oorun yio fi wọ.
Lati ọdọ Jaabir- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju arakunrin kan beere lọwọ Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: Fun mi ni iro nipa ti mo ba ki awọn irun ọran-anyan, ti mo gba awẹ Ramadan, ti mo ṣe ẹtọ ni ẹtọ, ti mo ṣe eewọ ni eewọ, ti mi ko le nnkan kan kun lori ìyẹn, njẹ maa wọ alujanna? O sọ pe: “Bẹẹni”, o sọ pe: Mo fi Ọlọhun bura pe mi ko nii le nnkan kan kun lori ìyẹn.
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba ki awọn irun ọran-anyan maraarun-un ti ko le nnkankan kun ninu awọn nafila, ti o si gba awẹ Ramadan ti ko gba awọn aṣegbọrẹ, ti o ni adisọkan jijẹ ẹtọ nnkan ẹtọ ti o si ṣe é, ti o ni adisọkan jijẹ eewọ nnkan eewọ ti o si jina si i, dajudaju yoo wọ alujanna.