





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Láti ọ̀dọ̀ Abu Sirmah- ki Ọlọhun yọnu si i- pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá kó ìpalára ba ẹlòmíràn, Ọlọhun maa ko ìpalára ba oun naa, ẹni tí ó bá ko ìnira ba ẹlòmíràn, Ọlọhun maa ko ìnira ba oun naa”.
Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣọ wa lara kuro nibi mimu ìpalára wọlé tọ Musulumi, tabi fifi ìnira kan an nibi èyíkéyìí àlámọ̀rí; yálà nibi ẹ̀mí rẹ ni, tabi dúkìá rẹ, tabi ará-ilé rẹ. Ẹni tí ó bá wa ṣe iyẹn, Ọlọhun maa san an ni ẹsan, O si maa fi ìyà jẹ ẹ ninu iran iṣẹ ti o ṣe.
Lati ọdọ Jeriir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: A wa lọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o wa wo òṣùpá ni alẹ ọjọ́ kan- o n túmọ̀ si òṣùpá ọjọ kẹrinla- o wa sọ pe: "Dajudaju ẹ maa ri Oluwa yin gẹgẹ bi ẹ ṣe n ri òṣùpá yìí, ẹ o nii ri inira nibi riri rẹ, ti ẹ ba ni ikapa ki wọn maa kọdi yin kuro nibi irun ṣíwájú yiyọ oorun ati ṣíwájú wiwọ rẹ, ki ẹ yaa ṣe bẹẹ" lẹyin naa o ka:"(Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa Rẹ ṣíwájú yíyọ òòrùn àti wíwọ̀ (rẹ̀).)"
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAwọn saabe wa pẹlu Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni alẹ ọjọ kan, o wa wo òṣùpá- ni ale ọjọ kẹrinla-, o wa sọ pe: Dajudaju awọn olugbagbọ maa ri Oluwa wọn ni ti paapaa pẹlu oju laisi iruju, ati pe wọn ko nii fún papọ mọ́ra wọn, wahala tabi inira ko nii ṣẹlẹ̀ si wọn nibi riri Rẹ- Ọba ti ọla Rẹ ga-. Lẹyin naa, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ti ẹ ba ni ikapa lati ge awọn okunfa ti o le yi yin kuro nibi irun asunbaa ati irun Asr, ki ẹ yaa ṣe bẹẹ, ki ẹ si mu mejeeji wa ni pipe ni asiko mejeeji ni janmọọn, dajudaju ìyẹn wa ninu awọn okunfa wiwo oju Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn, Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ka aaya naa: (Wa sabbih bihamdi Robbika qobla tuluu'ish shamsi wa qoblal guruub)
Láti ọ̀dọ̀ Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun maa n lọ́ alabosi lára, titi ti yoo fi mu u ti ko si nii jẹ ki ó bọ́”, o sọ pe: Lẹ́yìn náà ni o ka: “{Báyẹn ni ìgbámú Olúwa rẹ. Nígbà tí Ó bá gbá àwọn ìlú alábòsí mú, dájúdájú Ó máa gbá a mú pẹ̀lú ìyà ẹlẹ́ta-eléro t’ó le} [Huud: 102]”
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣọ wa lara kúrò nibi itẹsiwaju ninu abosi dídá ẹṣẹ ati ṣíṣe ẹbọ, ati ṣíṣe abosi fun awọn èèyàn nibi ẹ̀tọ́ wọn; torí pé Ọlọhun maa n lọ alabosi lára, O si maa n jẹ ki ẹmi rẹ o gùn ti dúkìá rẹ si tun maa pọ̀, ko waa ni kanju fi ìyà jẹ ẹ, ti ko ba wa ronupiwada, O maa mu u ti ko si nii fi i sílẹ̀ fun abosi rẹ ti o pọ. Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ka: {Báyẹn ni ìgbámú Olúwa rẹ. Nígbà tí Ó bá gbá àwọn ìlú alábòsí mú, dájúdájú Ó máa gbá a mú pẹ̀lú ìyà ẹlẹ́ta-eléro t’ó le} [Huud: 102].
Lati ọdọ Abu Al-Hayyaaj Al-Asadiy, o sọ pe: Aliy ọmọ Abu Tọọlib sọ fun mi pe: Ṣe ki n gbe ọ dìde lori nnkan ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbe mi dìde lórí ẹ? Ma fi ère kan kan silẹ àfi ki o pa a rẹ, ma si fi sàréè ti o ga kan kan silẹ afi ki o jẹ ki o bá ilẹ̀ dọ́gba.
Muslim gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n ran àwọn saabe rẹ pe ki wọn ma fi ère- oun ni aworan nǹkan ti o ni ẹmi ti o jẹ abara tabi eyi ti ko ni ara- kan kan sílẹ̀ afi ki wọn mu u kuro tabi ki wọn pa a rẹ. Ki wọn si ma fi sàréè ti o ga kan kan sílẹ̀ ayafi ki wọn jẹ ki o ba ilẹ̀ dọ́gba, ki wọn si wó nǹkan ti wọn kọ́ sori ẹ, tabi ki wọn ṣe e ni nǹkan ti o maa tẹ́ pẹrẹsẹ ti ko nii ga nílẹ̀ pupọ, ṣùgbọ́n o maa ga ni odiwọn àlààfo ti o wa laarin ìka àtàǹpàkò ati ika ọmọndinrin.
Lati ọdọ Imraan ọmọ Husayn- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Kii ṣe ara wa ẹni ti o ba retí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú láti ara nǹkan tabi ti wọn ba a ṣe e, tabi ẹni ti o ba pe apemọra imọ kọ̀kọ̀ tabi ti wọn sọ imọ kọ̀kọ̀ fun, tabi ẹni ti o ba sà sí èèyàn tabi ti wọn ba a sà sí èèyàn, ati ẹni tí ó bá ta kókó kan, ẹni tí ó bá wa ba ẹni tí n pe apemọra imọ kọ̀kọ̀, ti o wa gba ohun ti o sọ gbọ́, onítọ̀hún ti ṣe aigbagbọ si nǹkan ti wọn sọ̀kalẹ̀ fun Muhammad, ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a”.
Al-Bazzaar ni o gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe adehun iya fun ẹni ti o ba ṣe àwọn nǹkan kan ninu ijọ rẹ pẹlu gbólóhùn rẹ pe: “Kii ṣe ara wa”, ninu rẹ naa ni: Akọkọ: “Ẹni ti o ba retí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú láti ara nǹkan tabi ti wọn ba a ṣe e”, ipilẹ rẹ ni: Titu ẹyẹ sílẹ̀ nígbà tí èèyàn ba fẹ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ kan bii ìrìn-àjò, tabi òwò, ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti o ba fò lọ si apá ọ̀tún, o maa retí ìṣẹ̀lẹ̀ rere, o si maa ṣe nǹkan ti o gbèrò láti ṣe, ti o ba wa fò lọ sí apá òsì, o maa retí aburú, ko si nii ṣe nnkan ti o gbero lati ṣe mọ, ko ni ẹtọ ki èèyàn ṣe èyí fúnra rẹ, tabi ki o ni ki ẹlòmíràn ba oun ṣe e, ìrètí ìṣẹ̀lẹ̀ aburu latara èyíkéyìí nǹkan maa ko sínú ìyẹn, yálà nǹkan ti a n gbọ́ ni tabi nǹkan ti a n rí, bii ẹyẹ, tabi awọn ẹranko, tabi awọn alaabọ ara, tabi nọmba, tabi awọn ọjọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ẹẹkeji: “Ẹni ti o ba pe apemọra imọ kọ̀kọ̀ tabi ti wọn sọ imọ kọ̀kọ̀ fun”, ẹni tí ó bá pe apemọra imọ kọkọ pẹlu lílo ìràwọ̀ ati nǹkan mìíràn, tabi ti o wa si ọdọ ẹni ti n pe apemọra imọ kọ̀kọ̀ bii adágbigba ati ẹni ti o jọ ọ, ti o wa gba ohun ti o n sọ gbọ́ pẹ̀lú pipe apemọra imọ kọ̀kọ̀, o ti ṣe aigbagbọ si nǹkan ti wọn sọ̀kalẹ̀ fun Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a). Ẹẹkẹta: “Ẹni ti o ba sà sí èèyàn tabi ti wọn ba a sà sí èèyàn”, oun naa ni ẹni tí o ṣe oogun funra rẹ, tabi o ni ki ẹlòmíràn ba oun ṣe e; lati fi ṣe ẹnikan ni anfaani, tabi ko inira bá a, tabi ti o ta kókó kan pẹlu dídi òwú ati oogun le e lori pẹlu kika àwọn gbólóhùn iṣọra ti o jẹ eewọ le e lori, ki o tun wa fẹnu fátẹ́gùn túẹ́túẹ́ sínú rẹ.
Lati ọdọ àwọn kan ninu awọn ìyàwó Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹni ti o ba lọ ba yẹmiwo kan ti o wa bi i leere nipa nnkan kan, wọn ko nii gba irun rẹ fun ogoji ọjọ”.
Muslim gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣọ wa lara kuro nibi lílọ bá adagbigba- orúkọ kan ni ti o kárí fun yẹmiwo, ati awòràwọ̀, ati ẹni ti n tẹ yanrìn, ati bẹẹ bẹẹ lọ, ninu awọn ti maa n mu ẹri wa fun mímọ kọ̀kọ̀ pẹ̀lú àwọn itisiwaju kan ti o maa n lò- ati pe ọ̀wọ́ọ pe èèyàn kan bi i leere nipa nǹkan kan ninu kọ̀kọ̀, Ọlọhun ko nii fun un ni ẹsan ìrun rẹ fun ogójì ọjọ́; ki ìyẹn le maa jẹ ìyà fun un lórí ẹṣẹ ńlá yìí.
Lati ọdọ ọmọ Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ latara ìràwọ̀, onítọ̀hún ti gba ẹka kan ninu oògùn, bi o ba ṣe n lekun ninu imọ ìràwọ̀ naa ni kikọ oògùn rẹ naa ṣe maa lékún”.
Abu Daud ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ẹni ti o ba kọ́ imọ ìràwọ̀, ati fifi lílọ-bíbọ̀ rẹ, ati ìwọlé rẹ, ati ìjáde rẹ ṣe itọka si awọn ìṣẹ̀lẹ̀ orí ilẹ̀, bii ikú lagbaja, tabi iṣẹmi rẹ, tàbí àìsàn rẹ, ati nǹkan ti o jọ ìyẹn ninu nnkan ti o maa ṣẹlẹ̀ ni ọjọ́ iwájú, onítọ̀hún ti kọ́ ẹ̀yà kan ninu oògùn, bi èèyàn ba ṣe n kọ́ ọ sí naa ni yoo ṣe maa pọ̀ ni oògùn sí.
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: “Igbagbọ jẹ ipin aadọrin ati nnkankan- tabi ọgọta ati nnkankan-, eyi ti o ni ọla julọ nibẹ ni gbolohun Laa ilaaha illallohu, eyi ti o kere julọ nibẹ ni mimu suta kuro lọna, ati pe itiju jẹ ipin kan ninu igbagbọ”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju igbagbọ jẹ awọn ipin kan ati awọn iwa ti wọn pọ, o ko awọn iṣẹ ati awọn adisọkan ati awọn ọrọ kan sinu. Ati pe eyi to ga julọ ninu iwa igbagbọ ti o si daa julọ nibẹ ni gbolohun: “Laa ilaaha illallohu”, ni mimọ ìtumọ̀ rẹ, ni ṣíṣe iṣẹ pẹlu nnkan ti o da le lori, bii pe dajudaju Ọlọhun ni Ọlọhun Ọba Ọkan ṣoṣo ti O lẹtọọ si ijọsin ni Oun nikan ṣoṣo yatọ si ẹni ti o yatọ si I. Ati pe eyi ti o kere julọ ninu awọn iṣẹ igbagbọ ni mimu gbogbo nnkan ti o le ko suta ba awọn eniyan kuro ni awọn oju ọna wọn. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju itiju wa ninu iwa igbagbọ, oun ni awọn iwa kan ti o maa n muni ṣe nǹkan daadaa, ti o si maa n muni gbé iwa buruku ju silẹ.
Lati ọdọ Abu Bashir Al-Ansari- ki Ọlọhun yọnu si i-: O wa pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni apakan awọn irin ajo rẹ, o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ran ojiṣẹ kan niṣẹ- ti awọn eniyan si wa ninu ibusun wọn pe-: “Ẹ̀gbà ọrùn kan ti wọn fi okùn ọfà tín-ín-rín ṣe ko gbọdọ ṣẹku ni ọrun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tabi ẹgba ọrun kan afi ki wọn ge e”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ni apakan awọn ìrìn-àjò rẹ, ti awọn eniyan wa ni aaye orun wọn ti wọn maa n sun ni ìrìn-àjò wọn ati tẹnti wọn, bayii ni o wa ran ẹnikan si awọn eniyan ki o pa wọn láṣẹ láti gé awọn ẹgba ọrun ti wọn gbé kọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọrun, boya o jẹ eyi ti wọn ṣe latara okun tín-ín-rín ni- tàbí ti wọn ṣe latara nǹkan mìíràn gẹgẹ bii agogo tabi irin ẹsẹ ẹranko, ìyẹn ri bẹẹ; nitori pe wọn maa n gbe e kọ́ ọ lọrun lati fi ṣọ́ra kuro nibi ojúkójú, wọn wa pa wọn láṣẹ lati ge e; nitori ko lee dá aburu padà kuro fun wọn, ati pe anfaani ati inira, ọwọ Ọlọhun nìkan ṣoṣo ni o wa ti ko si orogun fun Un.