





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Láti ọ̀dọ̀ Abu Dharr- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki ni àwọn ife ìmumi odo adágún naa? O sọ pe: “Mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad wa lọ́wọ́ Rẹ bura, àwọn ife ìmumi rẹ pọ̀ ju onka awọn irawọ sanmọ lọ ni alẹ́ ti o ṣókùnkùn ti ko ni ẹsujo, àwọn ife imumi alujanna, ẹni tí o ba fi wọn mu omi, òùngbẹ ko tun gbẹ ẹ mọ láéláé, omi n dà sínú rẹ lati inú gọ́tà méjì nínú alujanna, ẹni tí ó bá mu nínú rẹ̀, òùngbẹ ko tun gbẹ ẹ mọ, ibu rẹ da gẹgẹ bii òró rẹ, gígùn rẹ ni odiwọn ohun ti n bẹ láàrin ìlú Hammaan si ìlú Aelah, omi rẹ̀ funfun ju wàrà lọ, o si dùn ju oyin lọ”
Muslim gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- búra pe àwọn ife imumi odo adágún rẹ ni ọjọ igbende pọ̀ ju onka awọn irawọ sanmọ lọ, Iyẹn maa hàn ni oru ti o ṣókùnkùn ti ko si òṣùpá nínú ẹ; torí pé oru ti o ba ni òṣùpá, àwọn ìràwọ̀ rẹ ki i hàn; torí pé imọlẹ òṣùpá maa bo wọ́n mọlẹ, ati òru ti ko si ẹsujo nibẹ; torí pé bibẹ ẹsujo maa kọdi rírí àwọn ìràwọ̀, Ati pe àwọn ife imumi alujanna, ẹni tí ó bá mu omi inú rẹ ko nii gbẹ òùngbẹ láéláé, òùngbẹ ti o si maa gbẹ ẹ́ kẹ́yìn nìyẹn, Àti pé odo adágún rẹ, gọ́tà méjì lati inú alujanna n dà sínú rẹ, ìbú rẹ da gẹgẹ bii òró rẹ; Bákan náà ni àwọn origun odo adágún naa ṣe ri, gígùn rẹ maa ṣe déédéé ohun ti n bẹ laarin Hammaan, ìlú kan ni ti o wa ni ìpínlẹ̀ Balkọọhu ni ilẹ Shaam, titi dé Aelah, ilu kan ni ti a mọ ti o wa ni etí Shaam, Omi adágún naa funfun ju wàrà lọ, itọwo rẹ dùn ju oyin lọ.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pé Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Iná yin jẹ ẹ̀yà kan nínú ẹ̀yà àádọ́rin ti ina Jahannama ni”, wọn sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, iná ayé gan ti tó. O sọ pe: “Ina Jahannama ju ti aye lọ pẹ̀lú ẹ̀yà mọkandinlaadọrin, gbígbóná ọkọọkan ninu ẹ da gẹgẹ bii gbígbóná iná ayé”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, sọ fun wa pe ina aye yii jẹ ọkan ninu aadọrin awọn ẹya ina Jahannama, Gbígbóná iná ọjọ́ ìkẹyìn lágbára ju gbígbóná iná ayé lọ pẹ̀lú ẹ̀yà mọkandinlaadọrin, ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan nínú rẹ̀ ṣe déédéé gbígbóná ina ayé. Wọ́n sọ pé: Ìwọ Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun, iná ayé yìí ti tó láti fi fi ìyà jẹ àwọn ti wọn ba wọ̀ ọ́, O sọ pé: Ina Jahannama ju ina ayé lọ pẹ̀lú ẹ̀yà mọkandinlaadọrin, ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú rẹ̀ da gẹgẹ bii rẹ nibi gbígbóná gidi gan.
Láti ọ̀dọ̀ Abdullah ọmọ Mas’huud- ki Ọlọhun yọnu si i-: Ojiṣẹ Ọlọhun- kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba wa sọrọ, olódodo ni, ẹni tí a sọ òdodo fún si ni: “Wípé wọ́n maa kó ẹ̀dá ẹnikan nínú yín jọ sínú ikùn ìyá rẹ̀ fún ogójì ọjọ́, lẹ́yìn náà yóò di ẹjẹ dídì fun ogójì ọjọ́, lẹyin naa yoo di baaṣi ẹran fun ogójì ọjọ́, lẹ́yìn náà wọn maa ran malaika si i, wọ́n maa pa a láṣẹ pẹ̀lú gbólóhùn mẹrin kan, wọn maa waa kọ: Arisiki rẹ, ati àsìkò rẹ, ati iṣẹ rẹ, ati pe ṣe oloriburuku ni abi oloriire, lẹ́yìn naa wọn maa fẹ́ ẹ̀mí si i lára, dájúdájú ẹnikan ninu yin yoo maa ṣe iṣẹ́ ọmọ alujanna, titi ti ohun ti o ṣẹku láàrin rẹ ati láàrin alujanna ko fi nii ju apá lọ, àkọsílẹ̀ maa wa borí rẹ, yoo waa maa ṣe iṣẹ́ ọmọ iná, yoo si wọ ọ, dájúdájú ẹnikan nínú yin, yoo maa ṣe iṣẹ́ ọmọ ina, titi ti ohun ti o ṣẹku láàrin rẹ ati láàrin iná ko fi nii ju apá lọ, àkọsílẹ̀ maa wa borí rẹ, yoo waa maa ṣe iṣẹ́ ọmọ alujanna, yoo si wọ̀ ọ́”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niIbnu Mas’ud sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba wa sọ̀rọ̀, olódodo ni nibi ọ̀rọ̀ rẹ, ẹni tí wọ́n sọ òdodo fun ni; torí pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ òdodo fun un, O sọ pe: Dajudaju ẹnìkan nínú yin, wọn ko ẹ̀dá rẹ jọ, ìyẹn ni pe ti ọkùnrin ba sunmọ ìyàwó rẹ, wọn maa ko àtọ̀ rẹ ti o fọnka jọ ninu ikun obìnrin ti o maa wa ni àtọ̀ fun ogójì ọjọ́, Lẹ́yìn náà yoo di ẹ̀jẹ̀ dídì, oun naa ni ẹjẹ ti ó ki ti kò sàn, eyi ni ogójì ọjọ́ kejì, Lẹyin naa yoo di baaṣi ẹran, oun naa ni egige kan ninu ẹran ni odiwọn nǹkan ti a le rún lẹ́nu, èyí ni ogójì ọjọ́ kẹta, Lẹyin naa ni Ọlọhun maa ran malaika si i lati fẹ́ ẹ̀mí si i lára lẹyin ti ogójì ọjọ́ kẹta bá parí, Wọn maa pa malaika naa láṣẹ ki o kọ àwọn nǹkan mẹ́rin kan, àwọn naa ni: Arisiki rẹ, oun naa ni odiwọn ohun ti o maa rí ninu idẹra ni ayé rẹ, Ati asiko rẹ, òun naa ni igba ti o fi maa wa láyé, Ati iṣẹ rẹ, ki ni? Ati pe ṣe oloriburuku ni abi oloriire. Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- búra pé ẹnikan yoo maa ṣe iṣẹ́ ọmọ alujanna, ti iṣẹ rẹ maa jẹ́ iṣẹ rere ni eyi ti o hàn si awọn èèyàn, yoo wà bẹ́ẹ̀ titi ti ohun ti o maa wa láàrin rẹ ati alujanna ko fi nii ju apá lọ, itumọ ni pe: Ohun ti o maa ku fun un lati de inu alujanna naa maa da gẹgẹ bii ẹni tí ohun ti o ṣẹku láàárín rẹ ati ààyè kan lórí ilẹ̀ ko ju déédéé apá lọ, àkọsílẹ̀ maa wa borí rẹ ati ohun ti wọn kadara fun un, ìgbà náà ni yoo maa ṣe iṣẹ́ ọmọ ina, yoo si pari ayé rẹ lórí ẹ, yoo si wọ ina; Torí pé májẹ̀mú gbígba iṣẹ ni ki èèyàn má kúrò lórí rẹ, ki o si ma yi i padà, àwọn èèyàn míràn ma maa ṣiṣẹ́ ọmọ iná titi ti o fi maa sunmọ ki o wọ̀ ọ́, ti ohun ti o maa ṣẹku láàrin rẹ àti ina ko nii ju odiwọn apá ninu ilẹ̀ lọ, ni àkọsílẹ̀ ati kádàrá ba maa borí rẹ, yoo waa maa ṣiṣẹ́ ọmọ alujanna, yoo si wọ̀ ọ́.
Láti ọ̀dọ̀ Toowus, o sọ pe: Mo ba àwọn èèyàn kan nínú àwọn saabe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti wọn maa n sọ pe gbogbo nǹkan pẹ̀lú kadara ni, o sọ pe: Mo gbọ ti Abdullah ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- ti n sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Gbogbo nnkan pẹlu kádàrá ni, titi dórí ikagara ati ijafafa, tàbí ijafafa ati ikagara”.
Muslim gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe gbogbo nnkan pẹ̀lú kádàrá ni; Titi dórí ikagara, oun naa ni: Gbígbé ohun ti o jẹ dandan láti ṣe jù silẹ ati dídá ìgbà si i ati lilọ ọ lára tayọ asiko rẹ, ninu ọrọ ayé ati ti alukiyaamọ. Ati ijafafa, oun naa ni: Ijafafa ati ọgbọ́n nípa àwọn àlámọ̀rí ayé àti alukiyaamọ. Ati pe Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ti kádàrá ikagara ati ijafafa ati gbogbo nǹkan, nǹkan kan ko nii ṣẹlẹ̀ ni ayé àyàfi ki o ti ṣaaju ninu imọ Ọlọhun ati fifẹ Rẹ.
Láti ọ̀dọ̀ Matọr ọmọ Ukaamis- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ti Ọlọhun ba kádàrá fun ẹrú kan pé o maa kú si ilẹ̀ kan, O maa jẹ ki o ni bukaata si i.”
Tirmiziy ni o gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: Ti Ọlọhun ba kádàrá fun ẹrú kan pe ki o kú sí ilẹ̀ kan ti ko si si nibẹ; O maa jẹ ki o ni bukaata si i, yoo waa wa si ibẹ, wọn si maa gba ẹ̀mí rẹ nibẹ.
Láti ọ̀dọ̀ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Nígbà tí a jokoo pẹlu Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nínú mọṣalaaṣi, ọkùnrin kan ba wọlé lórí ràkúnmí, o da ràkúnmí rẹ̀ gunlẹ, o si dè é, lẹ́yìn naa o sọ fún wọn pé: Èwo ni Muhammad nínú yin? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si rọ̀gbọ̀kú láàrin wọn, ni a wa sọ pé: Ọkunrin pupa ti o rọ̀gbọ̀kú yii ni. Arákùnrin naa wa sọ fún un pé: Irẹ ọmọ Abdul Muttọlib, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Mo ti da ẹ lóhùn”. Arákùnrin naa wa sọ fún Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Maa bi ọ léèrè, ti mo si ma le mọ́ ọ lori ìbéèrè naa, ma ṣe bínú sí mi. O wa sọ pe: “Bèèrè ohun ti o ba fẹ”, o wa sọ pé: Mo fi Oluwa rẹ bẹ ọ ati Olúwa àwọn ti wọn ṣiwaju rẹ, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O ran ọ si gbogbo àwọn èèyàn? O sọ pe: “Bẹẹni”. O sọ pe: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki a maa ki irun wákàtí márùn-ún ni ojúmọ́? O sọ pe: “Bẹẹni”. O sọ pé: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, njẹ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki a maa gba aawẹ oṣù yii nínú ọdún? O sọ pe: “Bẹẹni”. O sọ pe: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, njẹ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki o gba sàká yii lọ́wọ́ àwọn olówó wa ki o si pin in fun awọn talika wa? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Bẹẹni”. Arákùnrin naa wa sọ pé: Mo gba ohun ti o mu wa gbọ́, èmi si ni ojiṣẹ fun awọn ijọ mi, emi ni Dimaam ọmọ Tha’labah, láti ìdílé Banuu Sahd ọmọ Bakr.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pé: Nígbà tí àwọn saabe jókòó pẹ̀lú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nínú mọṣalaaṣi, ni ọkùnrin kan ba wọlé lórí ràkúnmí, o wa da a gunlẹ, lẹ́yìn náà o si dè é, Lẹ́yìn naa o bi wọn leere pé: Ewo ninu yin ni Muhammad? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- rọgbọku láàrin àwọn èèyàn, ni a wa sọ pé: Ọkunrin pupa ti o rọgbọku yii ni, Ọkunrin naa sọ fun un pe: Iwọ ọmọ Abdul Muttalib, Ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ fún un pé: Mo gbọ́ ẹ, bèèrè, maa da ẹ lóhùn. Arákùnrin naa wa sọ fún Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Dajudaju èmi maa bi ọ léèrè, mo si maa le mọ́ ọ nibi ibeere naa, ma ṣe binu si mi. Ìtumọ̀ ni pé: Ma bínú si mi, ma si jẹ ki ipọnju ba ọ, O sọ pé: Beere ohun ti o fẹ, O wa sọ pe: Mo n fi Olúwa rẹ àti Olúwa àwọn ti wọn ṣáájú rẹ bẹ̀ ọ́, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O ran ọ si awọn èèyàn? O sọ pé: Bẹẹni, lati fi kanpá mọ́ òdodo rẹ, Ọkùnrin náà sọ pé: ANSHUDUKA BILLAAH, itumọ rẹ ni pé: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki a maa ki ìrun wákàtí márùn-ún ni ojúmọ́? Àwọn náà ni àwọn irun ọran-anyan, O sọ pe: Beeni, O sọ pe: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, njẹ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki a maa gba aawẹ oṣù yìí ninu ọdún? Ìtumọ̀ rẹ ni: Oṣù Ramadan, O sọ pé: Bẹẹni, O sọ pe: Mo n fi Ọlọhun bẹ ọ, ǹjẹ́ Ọlọhun ni O pa ọ láṣẹ ki o gba sàráà yii lọ́wọ́ awọn olowo wa ki o si pin in fun awọn talika wa? Oun naa ni sàká, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: Bẹẹni, Dimaam wa gba Isilaamu, o wa sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé oun maa pe ìjọ oun sinu Isilaamu. Lẹ́yìn náà ni o wa ṣe àfihàn ara rẹ pé oun ni Dimaam ọmọ Tha’labah lati ìdílé Banuu Sahd ọmọ Bakr.
Láti ọ̀dọ̀ Ziyaad ọmọ Labiid- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dárúkọ nǹkan kan, o wa sọ pé: “Ìyẹn nigba ti imọ bá lọ”, mo sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, bawo ni imọ ṣe máa lọ ti a si n ka Kuraani, ti a si n mu awọn ọmọ wa ka a, ti àwọn ọmọ wa naa si n mu awọn ọmọ wọn ka a titi di ọjọ igbende? O sọ pe: “Ó ṣe fún ẹ, irẹ Ziyaad, ti mo si n lérò pé ó wa ninu awọn ti wọn ni agbọye ẹsin ju ninu ilu Mẹdina, ṣe àwọn Júù ati awọn Kristẹni o maa ka Taoreeta ati Injiila ni, ti wọn kò sì ṣiṣẹ pẹlu nǹkan kan ninu nǹkan ti o wa nínú méjèèjì?!”.
Ibnu Maajah ni o gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jókòó laarin awọn saabe rẹ, o wa sọ pé: Eyi ni àsìkò ti wọn maa ká imọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn, Ziyaad ọmọ Labiid Al-Ansọọriy wá ṣe eemọ- ki Ọlọhun yọnu si i- o wa beere lọwọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, O wa sọ pé: Báwo ni wọ́n ṣe maa ká imọ kúrò lọ́dọ̀ wa?! Ti a si ti ka Kuraani ti a si ha a; mo fi Ọlọhun búra, a o maa ka a, a si maa jẹ ki awọn ìyàwó ati awọn ọmọ wa ka a, ati awọn ọmọ-ọmọ wa, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ni ẹni tí n ṣe eemọ pé: O ṣe fun ẹ, irẹ Ziyaad! Tí mo si n ka ọ kun ara àwọn onimimọ nínú àwọn ará ilu Mẹdina! Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣàlàyé fun un pé: Pipadanu imọ kii ṣe pẹ̀lú pipadanu Kuraani; ṣùgbọ́n pipadanu imọ ni ki èèyàn má lò ó, Taoreeta ati Injiila n bẹ lọdọ awọn Juu ati awọn Kristẹni, tòun ti bẹ́ẹ̀ ko ṣe wọn ni anfaani, wọn ko si ṣe àǹfààní latara erongba àwọn méjèèjì; òun naa ni ki wọn lo ohun ti wọn mọ̀.
Láti ọ̀dọ̀ Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Wọn sọ ìmísí kalẹ fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nígbà tí o pe ọmọ ogójì ọdún, o lo ọdún mẹtala ni ìlú Makkah, lẹyin naa ni wọn pa a láṣẹ ki o ṣe hijra, o wa ṣe hijra lọ sí ìlú Madina, o wa lo ọdún mẹ́wàá nibẹ, lẹyin naa ni o wa kú (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a).
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niIbnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- n sọ pe: Wọn sọ ìmísí kalẹ fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wọn si gbé e dìde nígbà tí o pe ọmọ ogójì ọdún, o wa ni ilu Makkah fun ọdún mẹtala lẹ́yìn ìmísí, lẹyin naa ni wọn pa a láṣẹ lati ṣe hijra lọ sí ìlú Madina, o wa wa nibẹ fun ọdún mẹ́wàá, lẹyin naa ni o wa kú ni ọmọ ọdún mẹtalelọgọta.
Lati ọdọ Qataadah- ki Ọlọhun kẹ́ ẹ- o sọ pe: Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ fún wa pe arákùnrin kan sọ pé: Irẹ Anọbi Ọlọhun, bawo ni wọn ṣe maa gbé keferi dìde lori ojú rẹ? O sọ pe: “Njẹ Ẹni tí Ó mu un rìn lori ẹsẹ méjèèjì ni ayé ko ni ikapa lati jẹ ki o fi ojú rẹ rìn ni Ọjọ́ Àjíǹde ni?”, Qataadah sọ pé: Bẹ́ẹ̀ ni, mo fi agbára Olúwa wa búra.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niWọn bi Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pe: Báwo ni wọn ṣe maa gbe Kèfèrí dìde lori ojú rẹ ni Ọjọ́ Àjíǹde?! Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: Ǹjẹ́ Olọhun tí Ó mu un rìn lori ẹsẹ méjèèjì ni ayé ko ni ikapa lati jẹ ki o fi ojú rẹ rìn ni Ọjọ́ Àjíǹde ni?! Ọlọhun ni ikapa lori gbogbo nǹkan.