





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun àbúrò bàbá rẹ̀ pé: “Sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOOH, maa fi jẹ́rìí fun ọ ni Ọjọ́ Àjíǹde”, o sọ pe: Ti kii ba ṣe pe àwọn Quraysh maa bu mi ni, ti wọn maa sọ pé: Ìbẹ̀rù ni o mu un sọ ọ́, mi o ba fi dùn ọ́ nínú. Ni Ọlọhun wa sọ aaya yii kalẹ̀: {Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́} [Al-Qasas: 56].
Muslim gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa lati ọdọ aburo baba rẹ tii ṣe Abu Toolib ti o si n pọ́kàkà ikú lọ́wọ́- pe ki o pe LAA ILAAHA ILLALLOOH, ki o fi le ṣìpẹ̀ fun un ni Ọjọ́ Àjíǹde, tí o si maa jẹrii fun un pe o gba Isilaamu, ó kọ̀ lati wí gbólóhùn ijẹrii naa ni ìpayà pe ki awọn Quraysh ma bu oun, ti wọn a maa sọ nipa oun pé: O gba Isilaamu tori ibẹru ikú ati ọ̀lẹ! O wa sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe: Ti kii ba ṣe iyẹn ni, mi o ba dùn ọ́ nínú pẹ̀lú ki n wí gbólóhùn ijẹrii naa, mi o ba ṣe nǹkan ti o n fẹ́ titi ti wàá fi yọnu! Ni Ọlọhun ti ọla Rẹ ga wa sọ aaya kalẹ̀ ti n tọka si pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko ni ikapa ìtọ́sọ́nà ti kòńgẹ́ sinu Isilaamu, ṣùgbọ́n Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn nìkan ni O maa n fi ẹni tí Ó ba fẹ ṣe kongẹ. Ati pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n fi ẹ̀dá mọ̀nà pẹlu itọka ati àlàyé ati ìtọ́sọ́nà ati ipepe lọ si ojú ọ̀nà tààrà.
Lati ọdọ Anas ọmọ Mālik – ki Ọlọhun yọnu si i: Dajudaju Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe afẹku Thābit ọmọ Qaysi, ni arakunrin kan wa sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, maa mu iro rẹ wa fun ọ, ni o ba wa ba a ti o si ba a ni ẹni ti o jokoo si inu ile rẹ, ti o da ori rẹ kodo, ni o wa sọ pe: Ki lo ṣe ẹ? O sọ pe: Aburu ni, o maa n gbe ohun rẹ soke tayọ ohun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, nitori naa iṣẹ rẹ ti bajẹ, ati pe oun ti wa ninu awọn ọmọ ina, ni arakunrin naa ba pada wa ti o si fun un niroo wí pé o sọ bai bai, o tun wa pada wa ni igba ikẹhin pẹlu iro idunnu ti o tobi, nigba naa ni o wa sọ pe: «Lọ ba a ki o si sọ fun un pe: Dajudaju irẹ ko si ninu awọn ọmọ ina, ṣugbọn o wa ninu awọn ọmọ alujanna».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe afẹku Thābit ọmọ Qaysi – ki Ọlọhun yọnu si i – o wa beere nipa rẹ, ni arakunrin kan wa sọ pe: Maa mu iro rẹ wa fun ọ, ati idi ti o fi sa, ni o wa lọ si ọdọ rẹ ti o si ba a ni ẹni ti n banujẹ ti o si da ori kodo ninu ile rẹ, ni o wa bi i leere pe: Ki lo ṣe ọ? Ni Thābit wa sọ fun un nkan ti o ṣe e ninu aburu; latari pe oun maa n gbe ohun oun soke tayọ ohun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ti Ọlọhun si ti ṣe adun fun ẹni ti o ba ṣe iyẹn pẹlu bibajẹ iṣẹ rẹ, ati pe ninu awọn ọmọ ina ni yio wa. Ni arakunrin naa wa pada si ọdọ Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – o si fun un niroo nipa iyẹn, ni Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – wa pa a laṣẹ ki o ṣẹri pada si ọdọ Thābit ki o si fun un ni iro idunnu wipe dajudaju ko si ninu awọn ọmọ ina, ṣugbọn o wa ninu awọn ọmọ alujanna, ati pe lilọ soke ohun rẹ iṣẹda rẹ ni, ati pe o jẹ agbẹnusọ fun Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – o si tun jẹ agbẹnusọ fun awọn An-soor.
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amru ọmọ al-‘Aas – ki Ọlọhun yọnu si i – dajudaju o gbọ ti Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe: «Ti ẹ ba ti gbọ oluperun ki ẹ yaa maa sọ gẹgẹ bi o ṣe n sọ, lẹyin naa ki ẹ wa ṣe asalaatu fun mi, torí pé dajudaju ẹni ti o ba ṣe asalaatu kan fun mi Ọlọhun a fi ṣe mewaa fun un, lẹyin naa ki ẹ beere al-Wasiilah fun mi lọdọ Ọlọhun, ati pe dajudaju oun ni ipo kan ninu al-jannah, ti ko si lẹtọọ ayaafi fun ẹru kan ninu awọn ẹru Ọlọhun, mo si fẹ ki o jẹ emi, nitori naa ẹni ti o ba beere al-Wasiilah fun mi iṣipẹ ti di ẹtọ fun un».
Muslim gba a waAnabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – juwe ẹni ti o ba gbọ oluperun lọ sibi pe ki o maa sọ tẹle e nǹkan ti o ba n wi, nitori naa yio maa sọ iru ọrọ rẹ (oluperun), yatọ si Hayya‘ala mejeeji (Hayya‘alas sọlaah ati Hayya‘alal falaah), yio sọ lẹyin mejeeji pe: Laa haola walā quwwata illā biLlāh, lẹyin naa yio ṣe asalaatu fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lẹyin ti o ba pari irun pipe, torí pé dajudaju ẹni ti o ba ṣe asalaatu kan Ọlọhun a titori rẹ ṣe asalaatu mẹwaa fun un, ati pe itumọ asalaatu Ọlọhun fun ẹru Rẹ ni: Ẹyin Rẹ fun ẹru Rẹ lọdọ awọn malaaika. Lẹyin naa ni o wa paṣẹ pẹlu bibi Ọlọhun leere al-Wasiilah fun oun– ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ati pe oun (al-Wasiilah) naa ni ipo kan ninu al-jannah, ati pe oun lo ga jùlọ ninu rẹ, ko si lẹtọọ bẹẹ ni ko rọrun ayaafi fun ọkan ninu gbogbo awọn ẹru Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ti mo si n tanmọọn ki n jẹ ẹni naa, ati pe o sọ iyẹn – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni ti itẹriba; torí pé dajudaju ti ipo giga yẹn o ba nii wa ayaafi fun ẹnikan, ko wa si ẹni ti o lẹ jẹ ẹnikan yẹn ayaafi oun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -; torí pé oun ni o lọla julọ ninu awọn ẹda. Lẹyin naa o – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ṣe alaye pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe adua al-Wasiilah fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – iṣipẹ rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – a jẹ tiẹ.
Lati ọdọ Uthman ọmọ Abul 'Aas- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju o wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju Shaitan ti wa laaarin mi ati irun mi ati kika mi, ti o n da a ru mọ mi loju, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Iyẹn ni Shaitan kan ti wọn n pe ni Khinzab, ti o ba ti fura mọ ọn, ki o wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ, fẹ atẹgun si ẹgbẹ osi rẹ lẹẹmẹta", o sọ pe: Mo wa ṣe bẹẹ ni Ọlọhun ba mu u kuro lọdọ mi.
Muslim gba a waUthman ọmọ Abul 'Aas- ki Ọlọhun yọnu si i- wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju Shaitan kọdi laaarin mi ati laaarin irun mi, ti o kọ ipaya fun mi nibẹ, ti o da kika mi ru ti o si ko iyemeji ba mi nibẹ, Ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba sọ fun un pe: Ìyẹn ni Shaitan ti wọn n pe ni Khinzab, ti o ba ri eyi ti o si fura mọ ọn, dirọ mọ Ọlọhun, ki o si wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ, ki o si fẹ atẹgun si ẹgbẹ osi rẹ pẹlu itọ diẹ lẹẹmẹta, Uthman sọ pe: Mo ṣe nnkan ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pa mi láṣẹ pe ki n ṣe, ni Ọlọhun si mu u kuro lọdọ mi.
Lati ọdọ Abu Musa Al-Ash’ariy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: «Ẹni ti o ba kọ oju ija si wa pẹlu ohun ìjà, ko kii ṣe ara wa».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n kilọ fun ẹni ti o ba da oju ija kọ awọn Musulumi pẹlu nnkan ìjà, lati le dẹru ba wọn ati lati fi tipa gba nkan wọn, nitori naa ẹni ti o ba ṣe ìyẹn lai lẹtọọ, o ti da ọran nla ati ẹṣẹ nla kan ninu awọn iya ẹṣẹ, ti o si lẹtọọ si adehun iya ti o le.
Láti ọdọ bàbá Sa'eed Al-kuhdiry kí Ọlọhun yọnu sí dájú dájú òjíṣẹ Ọlọhun kí ikẹ àti ọlá Rẹ má bà s'ọpe: « Tí wan ba gbé òkú kalẹ tí awàn ènìyàn (Ọkunrín ) gbé si gbee sí ọrùn wan , tí o ba se pé ẹniire ni yóò sọpe : ẹtete tí mí síwájú, tí o ba se pé kìí se eniire yóò sọ pé : ha o má se fún òunh nibo ni wan ngbé òunh lọ bayi? Gbogbo nkán ni yóò má gbọ òunh rẹ ayaafi ènìyàn nìkan, tí ènìyàn a gbọ òunh rẹ ní wan ba daku ni » .
Bukhaariy gba a waAnọbi kí ikẹ Ọlọhun àti Ọlá rẹ máa ba fún wa niro pé tí wan ba gbé òkú kalẹ lórí ibùsùn, tí awàn eniyan l'ọkunrin sí gbé sórí ọrùn wan , tí o ba ṣepe ẹniire ni yóò sọ pé: etimi síwájú sí bí idẹra tí o wa níwájú rẹ, tí kí baa se eniire yóò parí wo pẹlu òunh tí arà kọ pé : ìparun tí dé ba òun nibo ni wan ngbé òunh lọ yì ?! Nitori ìyá tí o tiri ni iwájú rẹ, gbogbo nkán ni yóò gbọ òunh rẹ ayaafi ènìyàn, tí ènìyàn ba gbọ kò bà daku lẹkan náà latara lilagbara nkán to fí etí ará rẹ gbọ.
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Mo gbọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ti n sọ pe: "Ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj nitori ti Ọlọhun, tí kò ba obinrin lopọ, tí kò sì rú ofin Ọlọhun, onitọhun yoo pada sile gẹgẹ bi ọjọ ti iya rẹ̀ bi i."
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n ṣe alaye pé ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj nitori ti Ọlọhun Ọba Aleke ọla, tí kò sì bá obinrin lopọ, itumọ ibalopọ ni ibasun ati awọn ohun ti o ṣiwaju rẹ̀ gẹgẹ bii ifẹnukonu ati ifarakanra, wọn si maa n túmọ̀ rẹ̀ si ọrọ buruku, tí kò sì rú ofin Ọlọhun, nípa dídá ẹ̀ṣẹ̀ àti ṣíṣe aburú. Ninu rírú ofin Ọlọhun ni ṣiṣe awọn èèwọ̀ gbígbé harami, yoo pada sile lati Hajji rẹ̀ ní ẹniti Ọlọhun ti darijin, gẹgẹ bi wọn ti n bi ọmọde lai ni ẹṣẹ kankan lọrun.
Lati ọdọ ‘Aaisha- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Dajudaju mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “ko si irun pẹlu ikalẹ ounjẹ, tabi nigba ti igbẹ ati itọ ba n gbọ̀n ọ́n”.
Muslim gba a waOjiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ kuro nibi kiki irun pẹlu ikalẹ ounjẹ ti ẹmi olukirun n fa síbẹ̀, ti ọkan rẹ si n so mọ ọn. Gẹgẹ bẹẹ ni o ṣe kọ kuro nibi kiki irun pẹlu dídá Al-Akhbathaan- awọn mejeeji ni itọ ati igbẹ- padà, nitori kiko airoju rẹ pẹlu dídá ẹgbin náà padà.
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ti o ba sọ fun ọrẹ rẹ pe: Dakẹ, ni ọjọ jimọ, ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, o ti sọ ọrọ kọrọ».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye wipe dajudaju ninu awọn ẹkọ ti o jẹ dandan fun ẹni ti o ba wa gbọ khutuba jimọ ni: Didakẹ jẹjẹ fun ẹni ti n ṣe khutuba; lati le ba maa ronu si awọn iṣiti yẹn, ati pe dajudaju ẹni ti o ba sọrọ - koda ko jẹ ọrọ diẹ - ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, ti o wa sọ fun ẹni ti o yatọ si i pe: "Dakẹ" ki o si tun "tẹti", ọla irun jimọ ti bọ fun un.