





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ mi ni ataya, ti atẹlẹwọ mi wa laaarin atẹlẹwọ rẹ mejeeji, gẹgẹ bi o ṣe maa n kọ mi ni Surah ninu Kuraani: "At-tahiyyaatu lillah, was solawaatu wat toyyibaatu, as salaamu alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu, as-salaamu alaina wa 'alaa 'ibaadillahis soliheen, ash-hadu an laa ilaaha illallohu wa ash-hadu anna Muhammadan 'abduHu wa rosuuluHu". Ninu ẹgbawa kan ti o jẹ ti awọn mejeeji: "Dajudaju Ọlọhun ni Ọba alaafia, ti ẹnikẹni ninu yin ba jokoo nibi irun, ki o ya sọ pe: "At-tahiyyaatu lillah was solawaatu wat toyyibaatu, As-salaamu alaika ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu, as-salaamu alaina wa 'alaa'ibaadillahis soliheen. Ti o ba ti sọ ọ, o maa ba gbogbo ẹru Ọlọhun rere ni oke ati ilẹ, ash-hadu an laa ilaaha illallohu, wa ash-hadu anna Muhammadan 'abduHu wa rosuuluHu, lẹyin naa o maa ṣe ẹṣa nnkan ti o ba fẹ ninu ibeere".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- ni ataya ti wọn maa n ka lori irun, o wa fi ọwọ rẹ si ọwọ rẹ mejeeji, lati jẹ ki o kọ ibi ara si i. Gẹgẹ bi o ṣe maa n kọ ọ ni Surah ninu Kuraani ninu nnkan ti o tọka lori iko akolekan Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si ataya yii ni gbolohun ati ni ìtumọ̀. O si sọ pe: "At-tahiyyaatu lillah": Oun ni gbogbo ọrọ ati iṣẹ ti o da lori igbetobi, gbogbo ẹ ni o tọ si Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn. "As-solawaatu": Oun ni ìrun ti a mọ, ọran-anyan rẹ ati awọn nafila rẹ jẹ ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-. "At-toyyibaatu": Òun ni awọn ọrọ ati awọn iṣẹ ati awọn iroyin ti wọn daa ti wọn si n da lori pipe, gbogbo rẹ tọ si Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-. "As-salaamu alaika ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu": Adura ni o jẹ fun un pẹlu lila kuro nibi gbogbo aleebu ati nnkan ti a koriira, ati alekun ati ọpọlọpọ ninu gbogbo oore. "As-salaamu alaina wa 'alaa'ibaadillahis soliheen": Adura ni o jẹ pẹlu ọlà fun olukirun ati fun gbogbo ẹru rere ni sanmọ ati ilẹ. "Ash-hadu an laa ilaaha illallohu": O n túmọ̀ si pe mo n fi i rinlẹ ni ifirinlẹ ododo pẹlu rẹ pe ko si ẹni ti a le jọsin fun lododo afi Ọlọhun. "Wa anna Muhammadan 'abduHu wa rosuuluHu": Mo n fi ijẹ ẹru ati ìránṣẹ́ ti o jẹ opin rinlẹ fun un. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe olukirun lojukokoro lati ṣe ẹṣa ninu adura ti o ba fẹ.
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti maa n ṣe adua ti o si maa n sọ pe: «Irẹ Ọlọhun dajudaju emi wa iṣọra pẹlu Rẹ kuro nibi iya saare, ati nibi iya ina, ati nibi fitina iṣẹmi ati iku, ati nibi fitina al-Masiihu ad-Dajjāl». Nibi ti gbolohun ti Muslim: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba ti pari ataaya igbẹyin, ki o yaa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi awọn nkan mẹẹrin: Nibi iya jahannamọ, ati nibi iya saare, ati nini fitina iṣẹmi ati iku, ati nibi aburu al-Masiihu ad-Dajjāl».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti maa n wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi nkan mẹẹrin, lẹyin ataaya igbẹyin ati siwaju salamọ ninu irun, o si tun pa wa laṣẹ ki a maa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibẹ, Ikinni: Nibi iya saare. Ẹẹkeji: Nibi iya ina ati pe ìyẹn ni ọjọ igbedide. Ẹẹkẹta: Nibi fitina iṣẹmi bi awọn adun aye ti o jẹ eewọ ati awọn iruju ti maa n sọni nu, ati nibi fitina iku, ìyẹn ni àsìkò pipọka iku, bii yiyẹ kuro ninu Isilaamu tabi Sunnah, tabi fitina saare gẹgẹ bii ibeere awọn malaika mejeeji. Ẹẹkẹrin: Fitina al-Masiihu ad-Dajjāl eleyii ti yio jade ni igbẹyin aye, Ọlọhun yio fi i dan awọn ẹru Rẹ wo; o wa darukọ rẹ lọ́tọ̀ latari titobi fitina rẹ ati isọninu rẹ.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jẹ ẹni ti o ṣe pe, ti o ba ti kabara nibi irun, o maa n dakẹ fun igba díẹ̀ ṣíwájú ki o to ka Fatiha, mo wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun mo fi baba mi ati iya mi ṣe ìràpadà fún ọ, njẹ o ri idakẹ rẹ laaarin kikabara ati kika Fatiha, ki ni nnkan ti o maa n sọ? O sọ pe "mo maa n sọ pe: Al-Lahumma Bā`id Baynī Wa Bayna Khaţāyāya Kamā Bā`adta Bayna Al-Mashriqi Wa Al-Maghribi Al-Lahumma Naqqinī Min Khaţāyāya Kamā Yunaqqá Ath-Thawbu 'Illābyađu Mina Ad-Danasi Al-Lahumma Aghsilnī Min Khaţāyāya Bith-Thalji Wa Al-Mā'i Wa Al-Barad".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niTi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ti kabara, o maa n dakẹ ni idakẹ díẹ̀ ṣíwájú ki o to ka Fatiha, o maa n bẹ̀rẹ̀ irun rẹ nibẹ pẹlu awọn adura kan, ninu eyi ti o wa ninu awọn adura yii ni ọrọ rẹ pé: "Al-Lahumma Bā`id Baynī Wa Bayna Khaţāyāya Kamā Bā`adta Bayna Al-Mashriqi Wa Al-Maghribi Al-Lahumma Naqqinī Min Khaţāyāya Kamā Yunaqqá Ath-Thawbu 'Illābyađu Mina Ad-Danasi Al-Lahumma Aghsilnī Min Khaţāyāya Bith-Thalji Wa Al-Mā'i Wa Al-Barad", O maa n bẹ Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- lati gbe awọn àṣìṣe jìnnà si oun ki oun ma ko si i, ni igbejinna kan ti ipadepọ ko lee ṣẹlẹ pẹlu rẹ, gẹgẹ bi ko ṣe le si ìpàdépọ̀ laaarin ibuyọ oorun ati ibuwọ oorun láéláé, ti oun ba wa ko si i, ki O fọ oun mọ kuro nibẹ ki O mu u kúrò bi wọn ṣe maa n mu ìdọ̀tí kuro lara aṣọ funfun, pe ki O fọ oun mọ kuro nibi awọn àṣìṣe rẹ ki O bu tutu si eyi ti o n jo ti o si gbóná nibẹ, pẹlu awọn nǹkan ti n mọ́ nǹkan ti o tutu yìí; omi ati yinyin.
Lati ọdọ Anas - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba fẹ wọ aaye ẹgbin yio sọ pe: «Allaahummọ inni a‘uudhu biKa minal khubuthi wal khabaaithi».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba fẹ wọ aaye ti yio ti biiya bukaata rẹ, itọ tabi igbẹ, yio wa iṣọra pẹlu Ọlọhun, yio si tun sa di I ki O la a nibi aburo awọn eṣu ni takọ tabi tabo. Wọn si tu al-khubuthi ati al-khabaaith sí aburu ati awọn ẹgbin.
Lati ọdọ Maymūna iya gbogbo mumini - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbe omi iwẹ fun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - mo si fi aṣọ kan bo o, o wa da omi si ọwọ rẹ mejeeji, ti o si fọ wọn, lẹyin naa ni o fi ọwọ ọtun rẹ da omi si ọwọ osi, o si fọ abẹ rẹ, ni o wa fi ọwọ rẹ lu ilẹ, ti o si nu un, lẹyin naa ni o fọ ọ, ni o wa fi omi yọ ẹnu o si tun fin in si imu, o si tun fọ oju rẹ ati apa rẹ mejeeji, lẹyin naa ni o da omi si ori rẹ ti o si da a si ara rẹ, lẹyin naa ni o bọ́ sí ẹgbẹ kan, ti o si fọ ẹsẹ rẹ mejeeji, ni mo wa fun un ni aṣọ kan ti ko si gba a, ni o wa jade lẹni ti o n gbọn owo rẹ mejeeji.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niIya awọn olugbagbọ Maimuunah- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ nipa alaye iwẹ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- latara janaba, nigba ti o gbe omi fun un lati fi wẹ, ti o si da gaga kan bo o, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣe awọn nnkan ti o n bọ yìí: Akọkọ: O da omi si ọwọ rẹ mejeeji o si fọ mejeeji ṣíwájú ki o to ti mejeeji bọ inu igba. Ikeji: O da omi pẹlu ọwọ rẹ ọtun lori osi o si fọ abẹ rẹ; lati mọ ọn kuro nibi nnkan ti o ba lẹ̀ mọ́ ọn ninu oripa janaba. Ikẹta: O fi ọwọ rẹ lu ilẹ̀, o si nù ún, lẹ́yìn náà o fọ ọ lati le mu ẹgbin kuro nibẹ. Ikẹrin: O fi omi yọ ẹnu rẹ: pẹlu ki o fi omi si ẹnu rẹ, o si mi I, o yi i lẹyin naa o tu u, o fin omi simu; pẹlu ki o fi omi simu rẹ pẹlu èémí rẹ, lẹyin naa o mu u jade lati fi mọ ọn. Ikarun-un: O fọ oju rẹ ati awọn apa rẹ mejeeji. Ikẹfa: O da omi si ori rẹ. Ikeje: O da omi si awọn toku ninu ara rẹ. Ikẹjọ: O kuro nibi aaye rẹ o si fọ ẹsẹ rẹ mejeeji ní ibòmíì tí kò tíì fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Lẹyin naa, o mu aṣọ kan wa fun un lati nu ara rẹ pẹlu rẹ, ṣùgbọ́n ko gba a, o bẹ̀rẹ̀ si n nu omi kuro lara rẹ pẹlu ọwọ rẹ ti o si n gbọn ọn.
Lati ọdọ Aaisha Iya awọn Mumuni - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba ti fẹ wẹ janaba, yio fọ ọwọ rẹ mejeeji, yio si tun ṣe aluwala rẹ ti maa n ṣe fun irun, lẹyin naa yio wẹ, lẹyin naa yio fi ọwọ rẹ mejeeji ya irun rẹ, titi ti yio fi ro ni ẹmi rẹ pe o ti kan awọ isalẹ irun rẹ, yio wa da omi si ara ni ẹẹmẹta, lẹyin naa yio wẹ ara rẹ yoku, ni o wa sọ pe: Mo jẹ ẹni ti emi pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - maa n wẹ papọ ninu igba kan náà, ti a si jọ maa n fi ọwọ bu omi papọ ninu rẹ.
Bukhaariy gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba fẹ wẹ janaba yio bẹrẹ pẹlu fifọ ọwọ rẹ mejeeji, Lẹyin naa ni yio wa ṣe aluwala gẹgẹ bi o ṣe maa n ṣe aluwala fun irun, lẹyin naa yio fi ọwọ rẹ mejeeji ya irun ori rẹ, titi ti yio fi ni lọkan pe omi ti de isalẹ irun, ti o si ti jẹ ki awọ ori mumi yo, yio waa da omi si ori ni ẹẹmẹta lẹyin naa yio wẹ ara rẹ yoku. Aaisha - ki Ọlọhun yọnu si i - wa sọ pe: Mo jẹ ẹni ti emi pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - maa n wẹ ninu igba kan náà ti a o jọ maa fi ọwọ bu omi ninu rẹ papọ.
Lati ọdọ Aliy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo jẹ ọkùnrin kan ti o maa n da atọ ireke lọpọlọpọ, mo maa n tiju lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nitori ipo ọmọbinrin rẹ, mo wa pa Miqdad ọmọ Al-Aswad láṣẹ o si beere lọwọ rẹ, o sọ pe: "O maa fọ nnkan ọmọkunrin rẹ yoo si ṣe aluwala ". O n bẹ fun Bukhari: O sọ pe: "Ṣe aluwala ki o si fọ nnkan ọmọkunrin rẹ".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAliy ọmọ Abu Toolib- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe atọ ireke- oun ni omi funfun ti kò ki ti o maa n fà tìkọ̀, o maa n jade lati inu nnkan ọmọkunrin nigba adun tabi ṣíwájú ibalopọ- maa n jáde lara oun lọpọlọpọ, Ko si mọ bi o ṣe maa ṣe pẹlu jijade rẹ, o wa tiju lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-; nitori pe o jẹ ọkọ Fatimah ọmọbìnrin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, O wa tọrọ lọdọ Miqdad ọmọ Al-Aswad lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa ìyẹn, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- da a lohun pe: Ki o fọ nnkan ọmọkunrin rẹ lẹyin naa ki o ṣe aluwala.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu iṣẹ ni Ọlọhun nifẹẹ si julọ? O sọ pe: "Irun kiki ni asiko rẹ", o sọ pe: Lẹyin naa èwo? O sọ pe: "Lẹyin naa ṣíṣe daadaa si awọn obi mejeeji" o sọ pe: Lẹyin naa èwo? O sọ pe: "Jija ogun si oju ọna Ọlọhun" o sọ pe: O sọ wọn fun mi, ti mo ba wa alekun rẹ dajudaju o maa ṣe alekun rẹ fun mi.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niWọn bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu iṣẹ ni Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ? O sọ pe: Irun ọran-anyan kiki ni asiko rẹ ti Ọba aṣofin pa aala rẹ, Lẹyin naa, ṣíṣe daadaa si awọn obi mejeeji, pẹlu ṣíṣe daadaa si awọn mejeeji, ati mimojuto ẹtọ awọn mejeeji, ati gbigbe ṣiṣẹ awọn mejeeji ju silẹ, Lẹyin naa, jija ogun si oju ọna Ọlọhun, fun gbigbe ọrọ Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- soke, ati dida aabo bo ẹsin Isilaamu ati awọn Musulumi, ati fifi awọn ami rẹ han, ìyẹn pẹlu ẹmi ati owo. Ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe: O sọ awọn iṣẹ yii fun mi; ti mo ba sọ fun un pe: Lẹyin naa èwo? Dajudaju o maa ṣe alekun rẹ fun mi.
Lati ọdọ Abu Hurayrah, kí Ọlọhun bá wa yọnu si, o sọ pe: dájúdájú Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba - sọ bayi pe: Kosi ọjọ kan ti awọn ẹrusin yóò jí ní àárọ̀ ayaafi kí ó jasipe awọn malaika (iranṣẹ Ọlọhun) meji yoo sọkalẹ sí ọdọ ẹnikọọkan, ọkan ninu awọn mejeeji yóò máa ṣọ pe: "Irẹ Ọlọhun dakun bá mi ṣe irọpo owo fún ẹni tí n nawo rẹ, bẹẹ ni ikeji yóò máa ṣọ pe: "Bami fi iparun ati ibajẹ sinu owo ẹni tí ó kọ̀ lati ma na owo, tí ó wowọ́ mọ́n owo kankan.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ti fún wa ni iro pe kosi ọjọ kan ti oorun yọ ayaafi ki awọn malaika meji sọkale ti wọn yóò sì máa pe Ọlọhun, ọkan ninu wọn yóò sọ pé: "Ọlọhun bami fi ọpọ rọpo fún ẹni tí n nawo rẹ ni itẹle aṣẹ Ọlọhun, ati fún awọn ẹbi (ọmọ, iyawo, baba, ati iya....) ati igbalejo, ati sí bi awọn iṣẹ àṣegbọrẹ, bami fi èyí to lóore pupọ ju èyí to na lọ rọpo fun un, ki o si ṣe ibukún Rẹ fun". Ẹnikeji awọn malaika náà yóò máa sọ pe: "Ọlọhun bá mi ṣe iparẹ ati ibajẹ sí owo ẹni tí ó kọ̀ lati maa na owo rẹ, bá mi ko iparun ba owo tabi dukia tí ó kọ̀ lati na fún awọn ti o lẹtọọ sí i".