Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way






























Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n pa awọn olukirun láṣẹ lati maa to saafu wọn daadaa, ki apakan wọn si ma yọ siwaju ju apakeji lọ, ki wọn si ma sun sẹyin, ati pe didọgba saafu ninu pipe irun lo wa, ati pe wiwọ saafu si jẹ aayẹ ati adinku ninu rẹ.
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé awọn kan ninu awọn idajọ imọra, ninu wọn ni: Akọkọ: Dajudaju ẹni ti o ba ṣe aluwala, o jẹ dandan fun un lati fi omi si imu rẹ pẹlu èémí, lẹyin naa yoo mu u jade pẹlu eemi bakannaa. Ikeji: Ẹni ti o ba fẹ mọ ẹgbin ti o n jade lati ara rẹ, ti o fẹ mu u kuro pẹlu nnkan ti o yàtọ̀ si omi gẹgẹ bii okuta ati nnkan ti o jọ ọ, ki mimọra rẹ jẹ lori onka ti meji o le pin ti eyi ti o kere julọ nibẹ jẹ mẹta, ti eyi ti o pọ julọ nibẹ jẹ nnkan ti nnkan ti o n jade fi maa dá pẹlu rẹ ti aaye naa si fi maa mọ. Ikẹta ni: Ẹni ti o ba ji lati oju orun oru ko nii ti atẹlẹwọ rẹ bọ inu igba lati ṣe aluwala titi yoo fi fọ ọ lẹẹmẹta sita igba, nitori pe ko mọ ibi ti ọwọ rẹ wa mọju, ko lee fọkanbalẹ nipa ẹgbin lori rẹ, Shaitan ti le ba a ṣere ti o le ti gbe awọn nnkan ti o le ko inira ba eniyan sibẹ tabi nnkan ti o le ba omi jẹ.
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju aye dun nibi itọwo, o si tutu nibi riri, ti ọmọniyan maa gba ẹtanjẹ pẹlu rẹ ti yoo si tẹ̀rì sinu rẹ ti yoo si sọ ọ di eyi ti o tobi julọ ninu ironu rẹ. Ati pe dajudaju Ọlọhun- mimọ ni fun Un- fi awọn kan ninu wa role fun awọn kan ni igbesi aye yìí, ki O le maa wo bi a ṣe maa ṣiṣẹ, njẹ a maa tẹle E, tabi a maa yapa Rẹ? Lẹyin naa, o sọ pe: Ẹ ṣọ́ra ki igbadun aye ati ọṣọ rẹ ma tan yin jẹ, ti o wa maa mu yin gbe nnkan ti Ọlọhun pa yin láṣẹ rẹ ju silẹ, ati kiko si nnkan ti O kọ kuro fun yin nibẹ. Ati pe ninu nnkan ti o jẹ dandan julọ lati ṣọ́ra kuro ninu rẹ ninu awọn wahala aye ni wahala obinrin, ati pe o jẹ akọkọ wahala ti awọn ọmọ Ísírẹ́lì ko síbẹ̀.
Abdullahi ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- n ṣàlàyé pe: Dajudaju ninu awọn nafila ti oun ha lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jẹ rakah mẹwaa ti wọn pe wọn ni sunanur rawaatib, Rakah meji ṣíwájú irun Zuhr, ati rakah meji lẹyin rẹ, Ati rakah meji lẹyin irun Magrib ni ile rẹ, Ati rakah meji lẹyin irun Ishai ni ile rẹ, Ati rakah meji ṣíwájú irun alufajari, Ni rakah mẹwaa ba pe. Ṣugbọn irun Jimọh o maa n ki rakah meji lẹyin rẹ.
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ fun ọkọ ki o maa korira iyawo rẹ ni ikorira ti yio ti i debi ki o maa ṣe abosi rẹ ati ki o pa a ti ati ki o ma ya si i; nitori pe dajudaju ọmọniyan wọn da a mọ aipe ni, ti o ba wa korira iwa buruku kan ni ara rẹ, yio ri iwa miran ti o daa; nitori naa yio yọnu si èyí tí o daa ti o ṣe deede, ki o si ṣe suuru lori èyí tí ko daa ti ko yọnu si, èyí tí yio mu un ṣe suuru ti ko si nii korira rẹ ni ikorira ti yio gbe e lọ s'ibi kikọ ọ.
Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- kọ fun ẹni ti o ba fẹ gbọ bukaata itọ tabi igbẹ ki o da oju kọ kibula ati agbegbe kaaba, ki o si ma tun da ẹyin kọ ọ; amọ o jẹ dandan fun un ki o yi si ila oorun tabi iwọ oorun ti kibula rẹ ba jọ kibula awọn ara Madinah. Lẹyin naa ni Abu Ayyūb wa funni ni iro pe nígbà tí wọn de Shām wọn ri awọn ile igbọnsẹ nibẹ ti wọn ti pese kalẹ fun gbigbọ bukaata ti wọn da oju wọn kọ kaaba, nitori naa wọn maa n yi ara wọn kuro ni kibula, ti wọn si tun maa n toro aforijin Ọlọhun pẹlu bẹ́ẹ̀.
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé awọn ẹkọ kan; nigba ti o kọ ki ọkunrin fi ọwọ ọtun rẹ gba oko re mu nigba ti o ba n tọ, ati lati mu ẹgbin kuro niwaju tabi ẹyin pẹlu ọwọ rẹ ọtun; nitori pe ọwọ ọtun wọn pese rẹ fun awọn iṣẹ rere ni, Gẹgẹ bi o ṣe kọ fun ọmọniyan lati mi sinu igba ti o fẹ mu nibẹ.
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye adehun iya ti o le gidi fun ẹni ti o ba gbe ori rẹ soke ṣaaju imaamu rẹ, pẹlu pe ki Ọlọhun o sọ ori rẹ di ori Kẹtẹkẹtẹ, tabi ki o sọ aworan rẹ di aworan Kẹtẹkẹtẹ.
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n gbe ọwọ rẹ mejeeji soke nibi aaye mẹta ninu irun ni iwájú ejika ti o ṣe pe: Oun ni ibi ti egungun ejika ati apa ti papọ. Aaye akọkọ: Ti o ba ti bẹ̀rẹ̀ irun nibi kikabara iwọ irun. Ikeji: Ti o ba ti kabara fun rukuu. Ikẹta: Ti o ba ti gbe ori rẹ sókè lati rukuu, ti o wa sọ pe: Sami'alloohu liman hamidaHu Robbanaa wa laKal hamdu. Ko ki n gbe ọwọ rẹ mejeeji sókè nibi ìbẹ̀rẹ̀ fifi ori kanlẹ, tabi nibi gbigbe ori sókè lati ibẹ.