





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Abdullah ọmọ Amru ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji o sọ pe: A ṣẹri pada pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - lati Makkah lọ si Madina titi ti a fi kan omi ni oju-ọna, awọn ikọ kan yara fun irun Asri, ti wọn si ṣe aluwala ni ẹni ti n kanju, ni a ba wa ba wọn ti awọn gigisẹ wọn han ti omi o si de ibẹ, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: «Egbe ki o maa ba gbogbo gigisẹ (ti omi o de) ninu ina, ẹ ṣe aluwala yin daadaa».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ṣe irin-ajo lati Makkah lọ si Madina ti awọn saabe rẹ si wa pẹlu rẹ, ni oju-ọna wọn wọ́n rí omi, ti apakan ninu awọn saabe sì yara ṣe aluwala fún irun Asri debi pe gbigbẹ awọn gigisẹ fun omi han si kedere, ni Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- wa sọ pe: Iya ati iparun ninu ina n bẹ fun gbogbo olùṣe aseeto nibi fifọ gigisẹ nibi aluwala, o si tun pa wọn lasẹ ki wọn maa ṣe aluwala ni pipe.
Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Ti oluperun ba sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, ti ẹnikẹni ninu yin naa wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Ash'adu an laa ilaaha illa Allāhu, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Ash'adu an laa ilaaha illa Allāhu, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Ash'adu anna Muhammadan rọsuuluLlaah, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Ash'adu anna Muhammadan rọsuuluLlaah, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Hayya‘ala sọlaah, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Laa haola walā quwwata illā biLlāh, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Hayya‘alal falaah, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Laa haola walā quwwata illā biLlāh, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Laa illaha illā Allāhu, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Laa illaha illā Allāhu lati inu ọkan rẹ wa yio wọ aljanna».
Muslim gba a waIrun pipe ni fifi mọ awọn eeyan wiwọle asiko irun, ati pe awọn gbolohun irun pipe jẹ awọn gbolohun ti wọn ko adisọkan igbagbọ sinu. Ati pe ninu hadīth yii Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye nkan ti wọn ṣe ni ofin nigba ti a ba n gbọ ipe irun, oun naa ni ki ẹni ti n gbọ o maa sọ gẹgẹ bi oluperun ṣe n sọ, nigba ti o ba sọ pe "Allāhu Akbar" ẹni ti o n gbọ naa maa sọ pe: "Allāhu Akbar", bayii ni yio ṣe maa lọ; ayaafi nigba ti oluperun ba sọ pe "ayya‘ala sọlaah", "ayya‘alal falaah", nigba naa ẹni ti n gbọ maa sọ pe: "Laa haola walā quwwata illā biLlāh". Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - si tun ṣe alaye pe dajudaju ẹni ti o ba paara nkan ti oluperun n wi ni ti imọkanga lati inu ọkan rẹ yio wọ alujanna. Itumọ awọn gbolohun irun pipe ni: "Allāhu Akbar": Itumọ rẹ ni pe dajudaju Oun mimọ fun Un ni O tobi julọ, Oun ni o si tun gbọnngbọn ju gbogbo nkan lọ. "Ash'adu an laa ilaaha illa Allāhu ": Itumọ rẹ ni pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu. "Ash'adu anna Muhammadan rọsuuluLlaah": Itumọ rẹ ni pe mo n fi rinlẹ mo si tun n jẹrii pẹlu ahọn mi ati ọkan mi pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ti Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn ran an ni'ṣẹ, ti itẹle e si jẹ dandan. "Hayya‘ala sọlaah", itumọ rẹ ni pe ẹ wa lọ ki irun, ati pe gbogbo olugbọ yio sọ pe: "Laa haola walā quwwata illā biLlāh", itumọ rẹ ni pe ko si ète kankan lati la kuro nibi awọn nkan ti maa n dena titẹle aṣẹ, kò sì tun si agbara lati ṣe e, bẹẹ ni ko si ikapa lori ikankan ninu awọn nkan wọnyii ayaafi pẹlu kongẹ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga. "Hayya‘alal falaah", itumọ rẹ ni pe ẹ wa sibi okunfa ọla, oun naa ni jijere pẹlu alujanna ati lila kuro nibi ina.
Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹni ti o ba gbagbe irun kan ki o yaa ki i nigba ti o ba ranti rẹ, ko si ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ fun un afi ìyẹn: (Kí o sì kírun fún ìrántí Mi.) (Ta-Ha: 14)”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba gbagbe lati ki eyikeyii irun kan ti a ṣe e ni ọran-anyan titi asiko fi lọ, o jẹ dandan fun un lati tete ki o si yara lọ san an ni kete ti o ba ti ranti rẹ, ko si ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ ati bibo fun ẹṣẹ gbigbe e ju silẹ afi ki Musulumi naa ki i nigba ti o ba ranti rẹ, Ọlọhun sọ ninu iwe Rẹ Alapọn-ọnle pé: (Kí o sì kírun fún ìrántí Mi.) (Ta-Ha: 14), o n túmọ̀ si pe: Ki o si ki irun ti a gbagbe nigba ti o ba ti ranti rẹ.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji-: Dajudaju wọn ri arabinrin kan ti wọn ti pa ninu ọkan ninu awọn ogun ti Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ja, nitori naa, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- kọ pipa awọn obinrin ati awọn ọmọde.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ri arabinrin kan ti wọn ti pa ni ọkan ninu awọn ogun ti o ja, nitori naa o kọ pipa awọn obinrin ati awọn ọmọde ti wọn o tii balaga.
Lati ọdọ ọmọ Umar ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji: Lati ọdọ Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- dajudaju o kọ kuro nibi ẹjẹ jijẹ, o wa sọ pe: “Dajudaju ẹjẹ jijẹ o ki n mu oore wa, bi ko ṣe pe wọn maa n fi gba nnkan jade lati ọwọ ahun ni”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ kuro nibi ileri, oun ni ki eniyan ṣe nnkan kan ni dandan fun ara rẹ ti Ọba aṣofin ko ṣe ni dandan fun un, o sọ pe: Nitori pe ileri ko ti nnkan ṣíwájú ko si lọ ọ lara, bi ko ṣe pe wọn maa n mu u jade lati ọdọ ahun ti ko ki n ṣe nnkan kan afi nnkan ti o jẹ dandan le e lori, ati pe dajudaju ileri ko ki n mu nnkan kan wa ti wọn ko tii kadara rẹ fun un.
Lati ọdọ Abu Mūsa - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Wọn bi ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere nipa arakunrin ti n jagun ni ti ijẹ akin, ati eyi ti n jagun ni ti ìgbónára, ati eyi ti n jagun ni ti karimi, ewo ninu rẹ ni o wa ni oju-ọna Ọlọhun? Ni ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: «Ẹni ti o ba jagun lati jẹ pe ọrọ Ọlọhun ni yio leke, oun ni o wa ni oju-ọna Ọlọhun».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niWọn bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere nipa ìyapa erongba awọn jagunjagun: Ẹni ti n jagun ni ti ijẹ akin, ati ẹni ti n jagun ni ti igbonara ati ẹni ti n jagun lati mọ ipo rẹ l'ọdọ awọn eeyan, ewo ni o wa ni oju-ọna Ọlọhun ninu wọn? Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe dajudaju ẹni ti n jagun si oju-ọna Ọlọhun ni: Ẹni ti n jagun lati jẹ ki o jẹ pe ọrọ Ọlọhun ni yio leke.
Lati ọdọ Abu Sa‘ēd Al-khudriyy - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Tí ẹ ba ti gbọ ipe irun, ki ẹ yaa maa sọ iru nkan ti oluperun ba n sọ».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣeni lojukokoro lori jijẹ ipe oluperun nigba ti a ba n gbọ ọ, ati pe ìyẹn ni ki a maa sọ nkan ti o n sọ, ni gbolohun gbolohun. Nigba ti o ba wa sọ gbolohun Allāh Akbar àwa naa o wi i lẹyin rẹ, ati pe nigba ti o ba mu gbolohun ijẹrii mejeeji wa, awa naa o mu un wa lẹ́yìn rẹ, Ati pe wọn ṣe ayaafi gbolohun: (Hayya ‘alas sọlāt, Hayya ‘alal falāh) wọn maa sọ lẹyin awọn mejeeji pe: lā haola walā quwwata illā biLlāh.
Lati ọdọ Al-Mughiirah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe. Mo wa pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni irin-ajo kan, ni mọ ba bẹrẹ lati bọ abọsẹsẹ alawọ rẹ mejeeji, ni o wa sọ pe: «Fi wọn silẹ, nitori pe dajudaju mo ti mejeeji bọ ọ ni mimọ ni» ni o wa fi ọwọ pa mejeeji.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ni ọkan ninu awọn irin-ajo rẹ, ni o wa ṣe aluwala, Nigba ti o wa débi fifọ ẹsẹ mejeeji, Al- Mughiirah ọmọ Shu‘bah - ki Ọlọhun yọnu si i - na ọwọ rẹ mejeeji lati bọ nkan ti o wa ni ẹsẹ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni abọsẹsẹ alawọ lati fọ ẹsẹ rẹ mejeeji. Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: Fi mejeji silẹ ma bọ wọn, torí pé dajudaju mo ti ẹsẹ mi mejeeji bọ inu abọsẹsẹ alawọ mejeeji ti mo si wa lori imọra, Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa fi ọwọ pa abọsẹsẹ alawọ rẹ mejeeji lati fi jirọ fifọ ẹsẹ mejeeji.
Lati ọdọ Aaisha iya àwọn Mumuni - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju Faatimah ọmọ Abu Hubaysh bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere o wa sọ pe: Dajudaju mo jẹ ẹni ti maa n ri ẹjẹ awaada ti mii si ki n si ni imọra, njẹ mo le fi irun silẹ? Ni o wa sọ pe: «Rara, dajudaju ẹjẹ iṣan niyẹn, ṣugbọn maa fi irun silẹ ni odiwọn awọn ọjọ ti o fi maa n ri ẹjẹ nkan oṣu, lẹyin naa ki o wa wẹ ki o si kirun».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niFaatimah ọmọ Hubaysh beere lọwọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni o wa sọ pe: Dajudaju ẹjẹ o ki n da lara mi ati pe o si maa n wa titi di igba ti kii ṣe igba ẹjẹ nkan oṣu, njẹ idajọ iyẹn le jẹ idajọ ẹjẹ nkan oṣu bii ti maa wa maa gbe irun ju silẹ? Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ fun un pe: Dajudaju ẹjẹ awaada ni, oun si ni ẹjẹ aisan kan ti o maa n ṣẹlẹ lati ipasẹ jija iṣan kan nibi apo ibimọ, ati pe kii ṣe ẹjẹ nkan oṣu, Ti asiko ẹjẹ nkan oṣu ba de, eyi ti o maa n ri ẹjẹ nkan oṣu níbẹ̀ lori ìṣesí oṣooṣu rẹ siwaju ki o to lugbadi aisan ẹjẹ awaada, ki o yaa fi irun ati aawẹ ati nkan ti o yatọ si mejeeji silẹ ni awọn nkan ti wọn kọ fun ẹni ti n ri ẹjẹ nkan oṣu kuro nibẹ ni asiko ẹjẹ nkan oṣu. Ti odiwọn igba yẹn ba ti wa tan, nigba naa wa jẹ ẹni ti o ti mọra kuro nibi ẹjẹ nkan oṣu, ki o yaa fọ aaye ẹjẹ yẹn, lẹyin naa ki o wẹ ara rẹ ni iwẹ ti o pe lati gbe ẹgbin kuro, lẹyin naa ki o wa ki irun.