





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Abu Sa’ēd Al-Khuduriy o sọ pe: Mu’āwiya lọ sibi àpéjọ kan ninu masalasi, ni o wa sọ pe: Kini nkan ti o mu yin jokoo? Wọn sọ pe: A jokoo fun iranti Ọlọhun, o sọ pe: Ẹ bura pẹlu Ọlọhun pe nkankan o mu yin jokoo ayaafi ìyẹn? Wọn sọ pe: A fi Ọlọhun bura ko si nkankan ti o mu wa jokoo ayaafi ìyẹn, o sọ pe: Mi o ni ki ẹ bura nítorí pé mo n fẹsun kan yin o, ko si si ẹnikankan ti o wa ni iru ipo mi si Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti ẹgbawa hadiisi rẹ lati ọdọ rẹ (Anabi) kere to temi: Ati pe dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jade si ibi akojọ awọn saabe rẹ, ni o wa sọ pe: Kini nkan ti o mu yin jokoo? Wọn sọ pe: A jokoo lati maa ranti Ọlọhun ati lati maa fi ẹyin fun Un lori bi O ṣe fi wa m'ọna si Isilaamu, ati idẹkun ti O fi i ṣe le wa lori, o sọ pe: «Ẹ bura pẹlu Ọlọhun ṣe nkankan o mu yin jokoo ayaafi ìyẹn?» Wọn sọ pe: A fi Ọlọhun bura ko si nkankan ti o mu wa jokoo ayaafi ìyẹn, o sọ pe : «Mi o ni ki ẹ bura nítorí pé mo n fẹsun kan yin o, ṣugbọn Jubril wa ba mi o si fun mi ni iro pe dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn n ṣe iyanran pẹlu yin ni ọdọ awọn malaika».
Muslim gba a waMu‘āwiyah ọmọ Abu Sufyaan- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- jade sibi akojọ kan ninu masalasi, ni o wa bi wọn pe kini nkan ti wọn tori rẹ kojọ, Wọn wa sọ pe: A n ranti Ọlọhun ni, Ni o wa sọ - ki Ọlọhun yọnu si i - pe ki wọn o fi Ọlọhun bura pe wọn o gbero nkankan nibi ijokoo wọn ati akojọpọ wọn yẹn ayaafi iranti Ọlọhun, Wọn si bura fun un, Lẹyin naa ni o wa sọ fun wọn pe: Dajudaju kii ṣe pe mo ni ki ẹ bura láti fi ẹsun kan yin ati lati ṣe iyemeji nipa ododo yin, lẹyin naa ni o sọ nipa ipo rẹ si Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati pe ko si ẹnikankan ti ipo rẹ sunmọ ọn - Anabi - to oun; latari pe Umu Habiibah ọmọ ìyá rẹ obinrin jẹ iyawo Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ati pe o tun wa ninu awọn ti wọn maa n kọ waayi (imisi), tòun ti bẹ́ẹ̀ náà ẹgbawa rẹ fun hadiisi kere, Ni o wa sọ fun wọn pe dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jade lati inu ile rẹ ni ọjọ kan, ni o wa ri wọn ti wọn jokoo ninu masalasi ti wọn n ṣe iranti Ọlọhun ti wọn si n yin In lori ọna Isilaamu ti O fi mọ wọn, ti O si fi ṣe idẹkun le wọn lori, ni o wa bi wọn leere - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti o si tun ni ki wọn o bura bi iru nkan ti Mu‘āwiya - ki Ọlọhun yọnu si i - ṣe pẹlu awọn eeyan rẹ, Lẹyin naa ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ fun wọn idi ibeere rẹ fun ibura wọn: Oun ni pe Jubril - ki ọla Ọlọhun maa ba a - wa ba oun ti o si fun oun ni iro pe Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn n fi yin ṣe iyanran niwaju awọn malaika, ti O si n ṣe afihan ọla yin fun wọn, ti O si tun n fi didaa iṣẹ yin han wọn, ti O si tun n yin yin loju wọn.
Lati ọdọ Jabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- pe o gbọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ pé: "Ti ọkùnrin ba wọ inu ile rẹ, ti o wa ranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ ati nibi oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ pé: Ko si ibusun fun yin ko si si oúnjẹ alẹ naa, ti o ba wa wọle, ti ko ṣe iranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ, Shaitan maa sọ pé: Ẹ ti ri ibùsùn, ti ko ba ti dárúkọ Ọlọhun nibi oúnjẹ rẹ, o maa sọ pe: Ẹ ti ri ibusun ati oúnjẹ alẹ".
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pàṣẹ pẹlu riranti Ọlọhun nigba wiwọ inu ile ati ṣíwájú jijẹ oúnjẹ, ti o ba ranti Ọlọhun pẹlu sisọ pe: (Bismillah) nigba ti o ba wọ inu ile rẹ ati ìbẹ̀rẹ̀ jijẹ oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ fun awọn oluranlọwọ rẹ pé: Ko si ipin fun yin lati sun tabi lati jẹun alẹ ninu ile yii ti ẹni ti o ni i ti wa iṣọra kuro lọdọ yin pẹlu riranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-. Ṣugbọn ti ọkùnrin ba wọ ile rẹ ti ko ranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ tabi nigba jijẹ oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ fun awọn oluranlọwọ rẹ pe wọn ti ri ibusun ati oúnjẹ alẹ ninu ile yii.
Lati ọdọ Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Dajudaju àpèjúwe olubajokoo rere ati olubajokoo burúkú da gẹgẹ bi ẹni ti o gbe almisiki ati eni ti o n fẹ ina alagbẹdẹ ẹni ti o gbe almisiki: Ninu ki o fun ọ nínú ẹ, tabi ninu ki o ra ọjà lọwọ rẹ, tabi ki o ri oorun ti o daa latara rẹ, ati pe ẹni ti o n fẹ iná alagbẹdẹ: Ninu ki o jo aṣọ rẹ, tabi ki o ri oorun ti o buru".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi apejuwe lelẹ fun iran meji ninu awọn eniyan: Iran akọkọ: Alabajokoo ati ọrẹ rere ti o maa tọka lọ sọ́dọ̀ Ọlọhun ati nnkan ti O yọnu si, ti o maa n ṣe iranlọwọ lori itẹle, Ati pe apejuwe rẹ da gẹgẹ bii ẹni ti o n ta almisiki, ninu ki o fun ẹ, tabi ki o ra a lọwọ rẹ, tabi ki o si gbooorun daadaa lati ọdọ rẹ. Iran keji: Alabajokoo ati ọrẹ burúkú; ti o maa n ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, ti o si maa n ṣe ikunlọwọ lori dida awọn ẹṣẹ, ti waa maa ri iṣẹ buburu lọdọ rẹ, ti yoo maa ko eebu ba ẹ nitori mimu u lọrẹ ati iba iru rẹ jokoo, Iru rẹ da gẹgẹ bii alagbẹdẹ ti o n fẹ ina rẹ: ninu ki o jo aṣọ rẹ latara ẹta parapara ina rẹ ti o n fo tẹle ara wọn, tabi ki o ri oorun buruku latara asunmọ rẹ.
Lati ọdọ Thaobān - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Dinar (owo) ti o lọla julọ ti ọmọniyan n na ni dinar (owo) ti o na fun awọn ara ilé rẹ, ati owo ti o na lori nkan ọ̀gùn rẹ lọ si oju-ọna Ọlọhun, ati owo ti o na lori awọn ẹmẹwa rẹ ni oju-ọna Ọlọhun» Abu Qilābah wa sọ pe: O bẹrẹ pẹlu ara ilé, lẹyin naa ni Abu Qilābah wa sọ pe: Ẹni wo ni ẹsan rẹ fi wa n tobi ju ẹni ti o n na owo lori awọn ọmọ rẹ kéékèèké, ti ko nii jẹ ki wọn maa tọrọ jẹ, tabi ti Ọlọhun o fi i ṣe wọn ni anfaani ti yio si tun rọ wọn lọrọ.
Muslim gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye oríṣiríṣi ọ̀nà téèyàn lè gbà náwó, ti o si tun to o ti awọn ọna inawo ba fún pọ̀ ni ibamu si bi wọn ṣe jẹ dandan le ọ l'ori si, ni o wa bẹrẹ pẹlu eyiti o pataki julọ lẹyin naa eyiti o pataki tẹle e. Ni o wa sọ pe dajudaju owo ti ẹsan rẹ pọ ju ni eyi ti musulumi na lori awọn ti inawo wọn jẹ dandan fun un; bii iyawo ati ọmọ, Lẹyin naa ni inawo lori nkan ọ̀gùn ti wọn pese kalẹ fun ijagun si oju-ọna Ọlọhun, Lẹyin naa ni inawo lori awọn ọrẹ ati alabaarin ni igba ti wọn n jagun si oju-ọna Ọlọhun.
Lati ọdọ baba Sa'eed Al-khudiriy - Ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - Ó ní oun gbọ́ tí Òjíṣẹ Ọlọhun - Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ̀ máa ba - tí ńsọ bayii pé: "Nígbàtí ẹnikan nínú yín bá lá àlá tí ó nifẹ sí, dajudaju ala naa lati ọdọ Ọlọhun ni ó ti wá, nitori naa ki ó fi ọpẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, kó sì sọ ọ́ fún ẹniti ó bá fẹ́, ṣugbọn tí ó bá lá àlá tí ó yàtọ̀ sí eleyii, ti kò sì wuu, dajudaju lati ọdọ èṣù ni o ti wá, ki iru ẹni bẹẹ yaa bẹ Ọlọhun fún ààbò àti iṣọ nibi aburu àlá naa, bẹẹ ni ki ó má rọ́ àlá náà fún ẹnikankan, ti kò bati rọ ọ fún ẹnikankan àlá náà kò ní kó ìnira ba a".
Bukhaariy gba a waAnọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa bá a - fún wa ní ìró pé dajudaju àlá daada tí ó ń múnú ẹni dùn lójú orun wá lati ọdọ Ọlọhun, Anọbi sì tọ wa sọna pe kí a fi ọpẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, ẹni naa sì lè sọ jade, ṣugbọn ti ó bá lálàá rí nkan tí kò fẹ́, tabi nkan tó ba a nínú jẹ́, lati ọdọ eṣu ni ó tiwa, ki o yáa wá iṣọra lọdọ Ọlọhun kuro nibi aburu rẹ, kí ó má ṣe rọ́ àlá náà tabi sọfún ẹnikankan, dájúdájú kò nii kó ìnira bá a nígbàtí o jẹ wipe Ọlọhun ti fi nkan táa sọ yii ṣe okunfa ọlà ati akoyọ kuro nibi nkan ti a kò fẹ, eyi ti ó lè fẹ ṣẹlẹ latara àlá náà.
Lati ọdọ Suhayb - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Eemọ ni alamọri mumini, dajudaju gbogbo alamọri rẹ oore ni, iyẹn o si si fun ẹnikankan ayaafi mumini, ti idunu ba ṣẹlẹ si i yio dupẹ, ti yio si jẹ oore fun un, ti inira ba si tun ṣẹlẹ si i yio ṣe suuru, ti yio si tun jẹ oore fun un».
Muslim gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe eemọ nipa ọrọ mumini ati awọn iṣesi rẹ ni ti daadaa; ìyẹn ni pe gbogbo ìṣesí rẹ patapata ni oore, ti ìyẹn o si si fun ẹnikankan ayaafi mumini; Ti daadaa ba ṣẹlẹ si i yio dupẹ fun Ọlọhun lori rẹ; ti yio si gba ẹsan pẹlu ọpẹ dida, Ti inira ba si tun ṣẹlẹ si i yio ṣe suuru ti yio si tun retí ẹsan lọdọ Ọlọhun, ti yio si tun gba ẹsan suuru, nitori naa inu ẹsan ni o wa ni gbogbo ìṣesí rẹ.
Lati ọdọ Abu Hurayra– ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba sin, o maa n gbe ọwọ rẹ- tabi aṣọ rẹ- si ẹnu rẹ, ti o maa fi rẹ ohun rẹ nilẹ.
Abu Daud ati Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a waTi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba sin, o maa n: Akọkọ: O maa gbe ọwọ rẹ, tabi aṣọ rẹ sori ẹnu rẹ; ki nnkan kan ma baa jade lati ẹnu rẹ tabi imu rẹ ti o le ko suta ba alabajokoo rẹ. Ikeji: O maa n rẹ ohun rẹ nilẹ, ko si nii gbe e soke.
Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik, ki Ọlọhun bá wa yọnu si i, o sọ bayi pe: Òjíṣẹ Ọlọhun - Ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa ba - sọ bayi pe: "Ẹnikẹni ti ó bá ṣamojuto ọmọ obinrin meji tabi tí ó tọ́ wọn dagba titi ti wọ́n fi di ẹni ọkunrin, irufẹ ẹni bẹẹ yóò wá ní ọjọ igbende ti èmi rẹ̀ yóò wà papọ̀" Anọbi pa ọmọnika rẹ papọ̀ mọ́nrawọn.
Muslim gba a waAnọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ̀ máa bá a - jẹ kí amọn pé: ẹnikẹni ti Ọlọhun bá fun ni ọmọbirin meji tabi arabinrin meji, ti o wa mojuto itọju wọn daada pẹlu ẹkọ ati titọwọn sọna lọ sibi iṣẹ rere, ti o sì ṣọwọn lára kuro nibi aburu ati bẹẹ bẹẹ lọ titi ti wọ́n fi dagba, irufẹ ẹnibẹẹ yóò wà pẹlu Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - ní ọjọ igbende gẹgẹ bi ika ọwọ méjèjì yii, Anọbi ṣe àpèjúwe rẹ̀ pẹlu ika ilabẹ ati ika mogajuwọnlọ tí ó pa wọ́n pọ̀ mọ́nrawọn.
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹ ko lee wọ alujanna titi ti ẹ fi maa gbagbọ, ati pe e ko lee gbagbọ titi ti ẹ fi máa nífẹ̀ẹ́ ara yin, ẹ wa jẹ ki n juwe yin si nkankan ti o jẹ pe ti ẹ ba ṣe e ẹ máa nífẹ̀ẹ́ ara yin? Ẹ maa tan salamọ ka laarin ara yin».
Muslim gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ẹnikankan o lee wọ alujanna ayaafi muumini, ati pe igbagbọ o lee pe ati pe ìṣesí awujọ musulumi o lee daa titi ti wọn o fi nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Lẹyin naa ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa juwe lọ sibi eyiti o lọla julọ ninu awọn alamọri eyiti o ṣe pe pẹlu rẹ ni ifẹ fi maa n kari, oun naa ni fifọn salamọ ka laarin awọn musulumi, eleyii ti Ọlọhun ṣe ni kiki fun awọn ẹru Rẹ.