





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Tamīm ad-Dāriy - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe: «O daju pe ẹsin yii a de gbogbo ibi tí oru ati ọsan de, ati pe Ọlọhun o nii fi ile kankan silẹ bóyá ilé alámọ̀ ni abi ilé onírun ayafi ki O mu ẹsin yii wọ ibẹ, pẹlu iyi abiyi tabi iyẹpẹrẹ ẹni yẹpẹrẹ, ni iyi kan ti Ọlọhun maa fi fun Isilaamu niyi ati iyẹpẹrẹ kan ti Ọlọhun maa fi yẹpẹrẹ iṣe keferi» Tamīm ad-Dāriy maa n sọ pe: Mo mọ ìyẹn ni ara awọn ara-ile mi, oore ati iyì ti ṣẹlẹ̀ fun ẹni tí o gba Isilaamu nínú wọn, ti iyẹpẹrẹ ati sísan isakọlẹ si ṣẹlẹ fun ẹni ti o jẹ keferi ninu wọn.
Ahmad ni o gba a waOjiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju ẹsin yìí maa pada kari gbogbo àwọn ipin ilẹ̀, èyíkéyìí aaye ti oru ati ọsan de ni ẹsin yìí maa pada de, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ko nii fi ile kan sílẹ̀ láéláé ni awọn ilu ati awọn oko tabi ni aṣalẹ afi ki O mu ẹsin yii wọnu rẹ, Ẹni ti o ba gba ẹsin yii ti o si ni igbagbọ ninu rẹ dajudaju o maa di abiyi pẹlu iyi Isilaamu, Ẹni ti o ba kọ ọ ti o saigbagbọ pẹlu rẹ o maa di ẹni yẹpẹrẹ ati eni ẹtẹ. Lẹyin naa, saabe ti o n jẹ Tamiim Ad-Daari- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe oun mọ ìyẹn ti ojiṣẹ Ọlọhun sọ lara awọn ara ile rẹ, torí pé ẹni ti o gba Isilaamu ninu wọn ri oore ati iyi, ẹni ti o ṣe aigbagbọ ninu wọn si ri iyẹpẹrẹ ati ẹtẹ pẹlu owo ti o tun n san fun awọn Mùsùlùmí.
Lati ọdọ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo sọ pé: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, Ibnu Jud’aan maa n da ibi pọ ni asiko ki Isilaamu to de, o si maa n fun awọn alaini ni oúnjẹ, njẹ ìyẹn maa ṣe e ni anfaani? O sọ pe: “Ko lee ṣe e ni anfaani, nitori pe ko fi ọjọ kan sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fori awọn àṣìṣe mi jin mi ni ọjọ ẹsan".
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nipa Abdullahi Bn Jud’aan, o si wa ninu awọn aṣiwaju Kuraiṣi ṣíwájú Isilaamu, Ninu awọn iṣẹ daadaa rẹ ni pé: O maa n da awọn ẹbi pọ, o si maa n ṣe daadaa si wọn, o si maa n fun alaini ni oúnjẹ, ati eyi ti o yàtọ̀ si wọn ninu awọn iwa ọlọla ti Isilaamu ṣe wa lojukokoro lori ṣíṣe wọn, ati pe awọn iṣẹ yii ko lee ṣe e ni anfaani ni ọjọ igbedide rẹ; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ fun okunfa ṣíṣe aigbagbọ rẹ ninu Ọlọhun, ati pe ko fi ọjọ kan sọ pé: Irẹ Oluwa mi, forí awọn àṣìṣe mi jin mi ni ọjọ ẹsan.
Lati ọdọ Zaid bn Khalid Al-Juhaniy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki irun asunbaa fun wa ni Hudaibiyah lẹ́yìn ojo ti o rọ̀ ni òru, lẹ́yìn tí ó kírun tán, o kọju si awọn eniyan, o sọ pe: “Njẹ ẹ mọ nnkan ti Oluwa yin sọ?” Wọn sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “O n bẹ ninu awọn ẹru Mi ẹni ti o ji ni onigbagbọ ati ẹni tí o ji ni alaigbagbọ, ẹni tí ó bá sọ pé: Wọ́n rọ òjò fun wa pẹlu ọla Ọlọhun ati aanu Rẹ, ìyẹn ni ẹni tí ó gbagbọ ninu Mi ti o si ṣe aigbagbọ si ìràwọ̀, ṣugbọn ẹni tí o ba sọ pe: Pẹ̀lú ìràwọ̀ bayii bayii, ìyẹn ni ẹni tí o ṣe aigbagbọ ninu Mi, ti o wa ni igbagbọ ninu ìràwọ̀”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki irun asunbaa ni Hudaibiya- oun ni oko kan ti o sunmọ Mẹka- lẹyin ti ojo rọ ni alẹ yẹn, Igba ti o salamọ ti o ki irun rẹ tan o doju kọ awọn eniyan, o si bi wọn pe: Njẹ ẹ mọ nnkan ti Oluwa yin- Alagbara ti O gbọnngbọn- sọ? Wọn da a lohun pe: Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, O sọ pe: Dajudaju Ọlọhun ṣàlàyé pe awọn eniyan pin si meji nigba ti ojo ba rọ: Ipin kan ti o ni igbagbọ ninu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, ati ipin ti o jẹ alaigbagbọ ninu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, Ṣugbọn ẹni ti o sọ pe: Wọn rọ ojo fun wa pẹlu ọla Ọlọhun ati ikẹ Rẹ, ti o fi rirọ ojo ti sọ́dọ̀ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-; ìyẹn ni olugbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Aṣẹ̀dá Aṣeyiowuu ninu aye, o si jẹ alaigbagbọ si irawọ. Ṣugbọn ẹni ti o ba sọ pe: Wọn rọ ojo fun wa pẹlu irawọ bayii bayii; ìyẹn ni alaigbagbọ ninu Ọlọhun, olugbagbọ ninu irawọ, o si jẹ aigbagbọ kekere nigba ti o ṣe afiti rirọ ojo si ara irawọ; ati pe Ọlọhun ko ṣe e ni okunfa ti sharia tabi ti kadara, Ṣugbọn ẹni ti o ba ṣe afiti rirọ ojo ati nnkan ti o yàtọ̀ si i ninu awọn ìṣẹ̀lẹ̀ ori ilẹ̀ si ara lilọ-bibọ àwọn ìràwọ̀ nibi yíyọ wọn ati jijabọ wọn, ti o n ni adisọkan pe oun ni ẹni ti o n ṣe e gangan, o ti jẹ alaigbagbọ ni aigbagbọ ti o tobi.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Àwọn eniyan wa ninu awọn saabe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, wọn bi i leere pé: Dajudaju a n ri ninu ẹ̀mí wa nnkan ti ẹnikẹni nínú wa ko lee sọ ọ, o sọ pe: “Ṣé ẹ ti ri i?” Wọn sọ pé: Bẹẹni, o sọ pe: “Iyẹn ni igbagbọ ododo ti ko rùjú".
Muslim gba a waÀwọn ìjọ kan ninu awọn saabe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa, wọn si bi i leere nipa nnkan ti wọn n ri ninu ẹ̀mí wọn ninu awọn alamọri nla ti sisọ rẹ tobi latara biburu rẹ ati sisa wọn fun un, O sọ- Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla maa ba a- pe: Dajudaju eyi ti ẹ ri ni igbagbọ òdodo ti ko ruju ati àmọ̀dájú ti o maa jẹ ki ẹ le kọ ohun ti èṣù n jù sinu ọkàn, ati kikọ wiwi i jade lẹ́nu, ati titobi ìyẹn ninu ẹ̀mí yin, ati pe èṣù ko ráyè ninu ọkàn yin, yatọ si ẹni ti èṣù ráyè ninu ọkan rẹ, ti ko si lee da a padà.
Lati ọdọ Ibnu Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Arakunrin kan wa ba Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, dajudaju ọ̀kan ninu wa n ri ninu ẹ̀mí rẹ- o n pẹ́ nǹkan náà sọ pẹ̀lú itọka- o nífẹ̀ẹ́ si ki oun jẹ eeru ju ki o sọ ọ lọ, o wa sọ pe: “ Ọlọhun tobi Ọlọhun tobi, ọpẹ ni fun Ọlọhun ti O da ete rẹ pada si royiroyi".
Abu Daud ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú al-KubrọArakunrin kan wa sọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Ojisẹ Ọlọhun, dajudaju ẹnikan ninu wa n ri alamọri kan ninu ẹ̀mí rẹ ti o wa sínú ẹ̀mí, ṣùgbọ́n o tobi láti sọ ọ jáde, débi pe o nífẹ̀ẹ́ ki oun jẹ eeru ju ki o sọ ọ jade lọ, Bayii ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbe Ọlọhun tobi ni ẹẹmeji, o si dupẹ fun Ọlọhun pe O da ete èṣù pada si royiroyi lasan.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Èṣù a maa wa ba ẹnikan ninu yin, yoo si sọ pe: Ta ni o ṣẹda èyí? Ta ni o ṣẹda èyí? Titi yoo fi sọ pé: Ta ni o ṣẹda Oluwa rẹ? Ti o ba ti ba a de ibẹyẹn, ki o yaa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun ki o si jawọ.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niOjiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọrọ nipa iwosan ti o ṣe anfaani fun awọn ibeere ti èṣù fi n ko royiroyi ba olugbagbọ, Èṣù o maa sọ pé: Ta ni o ṣẹda eyi? Ta ni o ṣẹda eyi? Ta ni o ṣẹda sanmọ? Ta ni o ṣẹda ilẹ? Olugbagbọ yoo da a lohun ni ti ẹsin ati ti adamọ ati ti laakaye pẹlu ọrọ rẹ pé: Ọlọhun ni, Ṣùgbọ́n èṣù ko nii duro sibi aala yii ninu awọn royiroyi, bi ko ṣe pe yoo kúrò nibẹ titi yoo fi sọ pé: Ta ni o ṣẹda Oluwa rẹ? Nibi ìyẹn ni olugbagbọ ti maa da awọn royiroyi yii padà pẹlu awọn alamọri mẹta kan: Nini igbagbọ ninu Ọlọhun. Wiwa isọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ èṣù. Kiko ara ro nibi titẹsiwaju pẹlu awọn royiroyi.
Lati ọdọ Anas ọmọ Malik- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dajudaju Ọlọhun ko nii ṣe abosi olugbagbọ kan ni ti daadaa ti o ba ṣe, wọn yoo fun un ni ẹsan rẹ ni aye, wọn si tun maa san an ni ẹsan pẹlu rẹ ni ọrun, sugbọn alaigbagbọ wọn maa fun un ni oúnjẹ jẹ pẹlu awọn daadaa nnkan ti o ba ṣe ni iṣẹ́ nitori Ọlọhun ni aye, ti o ba ti wa de ọrun, daadaa kan ko nii maa jẹ tirẹ ti wọn maa san an lẹsan pẹlu rẹ”.
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé titobi ọla Ọlọhun lori awọn olugbagbọ, ati ṣíṣe deedee Rẹ pẹlu awọn alaigbagbọ. Ṣugbọn olugbagbọ, ẹsan daadaa ti o ba ṣe ko nii dínkù; bi ko ṣe pe wọn maa fun un ni dáadáa pẹlu rẹ ni aye lori itẹle rẹ, pẹlu nnkan ti wọn maa fi pamọ fun un ninu ẹsan ni ọrun; wọn si le tọju gbogbo ẹsan naa fun un ni ọrun. Ṣugbọn alaigbagbọ, Ọlọhun maa fun un ni ẹsan nnkan ti o ba ṣe ninu awọn daadaa pẹlu awọn daadaa aye, ti o ba ti wa de ọrun, ko nii si ẹsan kan ti wọn yoo san an lẹsan rẹ; nitori pe iṣẹ rere ti yoo ṣeni ni anfaani ni aye ati ọrun dandan ni ki ẹni ti o ṣe e jẹ olugbagbọ.
Lati ọdọ Hakeem ọmọ Hizaam- ki Ọlọhun yọnu si i-, o sọ pe: Mo sọ pé: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, fun mi ni iro nipa nnkan ti mo maa n se wọn ni asiko aimọkan bii saara ṣíṣe ati bibọkun kúrò lọrun ẹru ati dida ibi pọ, njẹ ẹsan wa nibẹ? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “O gba Isilaamu lori nnkan ti o ṣáájú ninu daadaa”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe alaigbagbọ ti o ba gba Isilaamu wọn maa san an lẹsan lori nnkan ti o n ṣe ni asiko aimọkan ṣíwájú gbigba Isilaamu rẹ ninu awọn iṣẹ oloore bii saara ṣíṣe ati bibọkun kúrò lọrun ẹru tabi siso ibi papọ.
Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: “Apejuwe ṣọbẹ-ṣelu da gẹgẹ bii apejuwe aguntan ti o n lọ ti o n bọ laaarin agbo aguntan meji, yoo lọ sibi fun ìgbà kan, yoo tun lọ si ọ̀hún nigba mii”.
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé iṣesi ṣọbẹ-ṣelu pe o da gẹgẹ bii aguntan ti o n ṣe iyemeji ti ko mọ eyi ti o maa tẹle ninu agbo aguntan méjèèjì, O maa lọ ba agbo yii nigba mii, a tun lọ ba omiran nigba mii, Wọn wa ninu idaamu-daabo laaarin igbagbọ ati aigbagbọ, wọn ko si pẹlu awọn olugbagbọ ni ti gbangba ati ni kọkọ, wọn ko si tun si pẹlu awọn alaigbagbọ ni gbangba ati ni kọkọ, bi ko ṣe pe gbangba wọn wa pẹlu awọn olugbagbọ, ti kọkọ wọn si wa nibi iyemeji ati aisi lojukan, nigba mii wọn maa yi lọ sọ́dọ̀ awọn yii, nigba mii wọn maa yi lọ sọ́dọ̀ awọn yii.