





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ 'Irbaad ọmọ Saariyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- duro laaarin wa ni ọjọ kan, o wa ṣe waasu kan ti o de ògòńgó fun wa ti awọn ọkan ń gbọn riri latara rẹ, ti awọn oju n dami latara rẹ, wọn wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o ṣe waasu idagbere fun wa, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun wa. O sọ pe: "Ibẹru Ọlọhun dọwọ yín, ati gbigbọ ati itẹle, ko da ki o jẹ ẹru dúdú, ẹ maa pada ri iyapa ẹnu ti o le koko lẹyin mi, sunnah mi ati sunnah awọn arole ẹni imọna ti a ti fi wọn mọna dọwọ yin, ẹ di wọn mu pẹlu eyin ọgan, ẹ ṣọra fún awọn adadaalẹ, ati pe dajudaju gbogbo adadaalẹ anu ni".
Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe waasu kan ti o de ogongo fun awọn saabe, ti awọn ọkan gbọn ti awọn oju dami latara rẹ, Wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun o da gẹgẹ bii waasu idagbere fun nnkan ti wọn ri ninu wiwọnu rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi waasu náà, wọn wa beere fun àsọtẹ́lẹ̀ ki wọn le gba a mu lẹyin rẹ, O sọ pe: Mo n sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yin pẹlu ibẹru Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn-, ìyẹn maa rí bẹ́ẹ̀ pẹlu ṣíṣe awọn nnkan ti wọn jẹ dandan ati gbigbe awọn eewọ ju silẹ, Ati gbigbọ ati itẹle, o n túmọ̀ si: Fun awọn adari, ko da ki ẹru jẹ adari fun yin, o n túmọ̀ si ki ẹni ti o kere julọ ninu ẹda di adari le yin lori, ẹ ko gbọdọ kọ ìyẹn, ki ẹ si tẹle e, ni ti ipaya dídá fitina sílẹ̀, dajudaju ẹni ti o ba ṣẹmi ninu yin maa pada ri iyapa ti o pọ, Lẹyin naa o ṣàlàyé ọna àbáyọ fun wọn kuro nibi iyapa yìí, ìyẹn pẹlu gbigba sunnah rẹ mu ati sunnah awọn arole ẹni imọna ti a fi ọna mọ wọn lẹyin rẹ, Abu Bakr, ati Umar ọmọ Khattaab, ati Uthman ọmọ 'Affan, ati Aliy ọmọ Abu Toolib- ki Ọlọhun yọnu si wọn lapapọ-, ati gbigba a mu pẹlu ẹyin ọgan, o n túmọ̀ si- awọn ẹyin ẹgbẹ ti o kẹ́yìn-: O n túmọ̀ ẹyin ọgan yẹn si didunnimọ sunnah daada ati didirọmọ ọn, O ṣe ikilọ fun wọn kuro nibi awọn alamọri ti a da wọn silẹ sinu ẹsin, ati pe dajudaju gbogbo adadaalẹ anu ni.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba mọọmọ parọ mọ mi, ki o yaa lọ wa ibùjókòó rẹ ninu ina".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba mọọmọ parọ mọ ọn, pẹlu fifi ọrọ kan tabi iṣẹ kan ti si ọdọ rẹ ni ti irọ, dajudaju ibujokoo kan n bẹ fun un ni ọrun ninu ina; ki o maa jẹ ẹsan fun un lori pipa irọ mọ ọn.
Lati ọdọ Abu Huraira, lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Awọn eniyan kan maa wa ni igbẹyin ijọ mi, ti wọn maa maa sọ fun yin nnkan ti ẹyin gangan tabi awọn baba yin ko gbọ, ẹ ṣọra fun wọn ”.
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe awọn eniyan kan maa han ni igbẹyin ìjọ rẹ ti wọn maa maa da adapa-irọ, ti wọn maa maa sọ nnkan ti ẹnikẹni ko sọ ṣíwájú wọn, ti wọn maa maa sọrọ pẹlu awọn hadiisi irọ ati agbelẹrọ, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla maa ba a- pa wa láṣẹ lati jina si wọn ki a si ma jokoo pẹlu wọn, ki a si ma tẹti si awọn hadiisi wọn; ki hadiisi ti wọn hun yii ma baa duro ninu awọn ẹ̀mí, ki a ma baa kagara kuro nibi lila kuro nibẹ.
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amr – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji – o sọ pe: Mo jẹ ẹni ti maa n kọ gbogbo nkan ti mo ba gbọ lẹnu ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – silẹ ni erongba ati de e mọlẹ, ni awọn Qurayshi ba kọ fun mi, wọn si sọ pe: Ṣé wa maa kọ gbogbo nkan ti o ba gbọ lẹnu ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni, ti o si jẹ pe ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – abara ni ti o maa n sọrọ ni asiko ibinu ati iyọnu? Ni mo ba dawọ duro nibi kikọ, ni mo wa sọ iyẹn fun ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ni o wa na ọmọ ika rẹ si ẹnu rẹ, ni o wa sọ pe: «Maa kọ, mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, nkankan o nii jade nibẹ (ẹnu rẹ) ayaafi ododo».
Abu Daud ni o gba a waAbduLlaah ọmọ ‘Amr – ki Ọlọhun yọnu si i– sọ pe: Mo jẹ ẹni ti maa n kọ gbogbo nkan ti mo ba gbọ lẹnu ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ki n le baa de e mọlẹ pẹlu kikọ, ni awọn ọkunrin kan ninu Qurayshi ba kọ fun mi, wọn si sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – abara ni ti o maa n sọrọ ni asiko iyọnu ati ibinu, ti o si le ṣe aṣiṣe, ni mo ba dawọ duro nibi kikọ. Ni mo ba sọ fun Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – nipa nkan ti wọn sọ, ni o wa na ọmọ ika rẹ si ẹnu rẹ o wa sọ pe: Maa kọ, mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ ni ọwọ Rẹ bura, nkankan o nii jade nibẹ (ẹnu rẹ) ayaafi ododo ni eyikeyi ìṣesí ti ko baa jẹ, ati ni asiko iyọnu ati ibinu. Ati pe Ọba ti ọla Rẹ ga ti sọ nipa Anabi Rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- pe: {Àti pé kò níí sọ̀rọ̀ ìfẹ́-inú * Kò níí sọ ohun kan tayọ ìmísí tí A fi ránṣẹ́ sí i} [An-Najmu 3-4].
Lati ọdọ baba Abdul Rahman ọmọ Umar ọmọ Alkhattob kí Ọlọhun yọnu sí o s'ọpe: mogbọ tí òjíṣẹ Ọlọhun kí ikẹ àti ọlá Rẹ má bà nsọ. pe : «Wọn mọ Isilaamu pa lori nkan márùn-ún: Ijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad ẹru Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni, ati imaa gbe irun duro, ati imaa yọ zakah, ati imaa gbero ile Oluwa, ati gbigba aawẹ Ramadan».
رواه البخاري ومسلمAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fi Isilaamu jọ ile kan ti wọn mọ daadaa pẹlu origun maarun ti o gbe ile naa duro, ti awọn iwa Isilaamu ti o sẹku jẹ pipari ile naa. Akọkọ awọn origun yii ni: Ijẹrii mejeeji; ijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Rẹ ni, ati pe origun kan ni mejeeji; ti ọkan o lee ja kuro lara ìkejì, ẹru o sọ mejeeji ni ẹni ti n fi ijẹ ọkan ṣoṣo Ọlọhun ati lilẹtọọ Rẹ si ijọsin ni Oun nikan ṣoṣo laisi ẹlòmíràn yatọ si i rinlẹ, ti yio si maa ṣiṣẹ tọ awọn nkan ti o n tọka si, ki o si tun gba iransẹ Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - gbọ ni ẹni ti yio maa tẹle e. Origun keji ni: Gbigbe irun duro, oun naa ni awọn irun ọranyan marun-un ni ojumọ kan ati oru kan: Alufajari, ati Àílà, ati Alaasari, ati Magribi, ati Ishai, pẹlu awọn majẹmu wọn ati awọn origun wọn ati awọn ọranyan wọn. Origun kẹta ni: Yiyọ zakah ọranyan, oun naa ni ijọsin owo ti o jẹ dandan nibi gbogbo dukia ti o ba ti to odiwọn ti wọn fi aala si ninu shariah, ti wọn o fun awọn ti wọn ni ẹtọ si i. Origun kẹrin ni: Hajji, oun naa ni gbigbero Makkah lati gbe awọn iṣẹ ìjọsìn duro, ni ti jijọsin fun Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn. Origun karun-un ni: Aawẹ Ramadan, oun naa ni kikoraro nibi jijẹ ati mimu ati nkan ti o yatọ si mejeeji ninu awọn nkan ti o le ba aawẹ jẹ pẹlu aniyan jijọsin fun Ọlọhun, lati igba ti alufajari ba ti yọ titi ti oorun yio fi wọ.
Lati ọdọ baba Hamur - wàn tilẹ sọ pé Bàbá Hamrata ni - , òun ni Sufyan ọmọ Abdullahi kí Ọlọhun yọnu sí o sọ pé: Mo sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, sọ ọrọ kan fun mi ninu Isilaamu ti mi ko nii bi ẹnikẹni leere nípa rẹ yàtọ̀ si ẹ, o sọ pe: "Sọ pe: Mo gbagbọ ninu Ọlọhun, lẹyin naa ki o duro deedee".
Muslim gba a waSaabe Sufyan ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere lati kọ oun ni ọrọ kan ti o ko awọn ìtumọ̀ Isilaamu sinu, ti oun maa dirọ mọ ọn, ti oun ko si nii bi ẹni ti o yàtọ̀ si i leere nipa rẹ? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pé: sọ pe Mo mu Ọlọhun lọkan, mo si gbagbọ pe Oluwa mi ni ati Ọlọhun mi ati Aṣẹ̀dá mi ati Ẹni ti maa maa jọsin fun lododo ti ko si orogun fun Un, Lẹyin naa, yoo tẹ fun itẹle Ọlọhun pẹlu ṣíṣe awọn ọran-anyan Ọlọhun ati gbigbe awọn eewọ Ọlọhun ju silẹ ti yoo si maa tẹsiwaju lori rẹ.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Mo fi Ẹni ti ẹmi Muhammad n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa mi ninu ìjọ yìí, Juu ni tabi Nasara, lẹyin naa o wa ku ti ko si ni igbagbọ pẹlu nnkan ti wọn fi ran mi, afi ko wa ninu awọn ara ina".
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n bura pẹlu Ọlọhun pe ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa oun ninu ìjọ yìí, Juu ni tabi Nasara tabi ẹni ti o yatọ si awọn mejeeji, ti ipepe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- de etiigbọ rẹ, lẹyin naa o wa ku ti ko si ni igbagbọ ninu rẹ afi ki o wa ninu awọn ara ina ti o maa ṣe gbere nibẹ lailai.
Lati ọdọ ‘Aaisha ati Abdullahi ọmọ’Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- wọn sọ pé: Nigba ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pọka iku, o bẹ̀rẹ̀ si nii fi aṣọ nu oju rẹ, ti o ba ti wa di pe ko le mí mọ́ daadaa, o maa ka a kuro loju rẹ, o wa sọ bi o ṣe wa bẹẹ pe: “Egbe Ọlọhun ko lọ maa ba awọn Juu ati Nasara, ti wọn mu awọn saare awọn Anabi wọn ni mọsalasi” ti o n ṣe ikilọ kuro nibi nnkan ti wọn ṣe.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni‘Aaisha ati Ibnu ‘Abbas- ki Ọlọhun yọnu si wọn- n sọ fun wa pé, nigba ti iku de ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o fi egige aṣọ soju rẹ, ti mimi ba ti ṣoro fun un latara awọn irora iku yoo mu u kuro loju rẹ, o wa sọ ninu isẹsi ti o le koko yẹn pé: Ọlọhun ṣẹbi le awọn Juu ati Nasara, O si le wọn jina si ikẹ Rẹ; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nitori pe wọn kọ mọsalasi lori awọn saare awọn Anabi wọn, bi ko ba ṣe bi alamọri naa ṣe lewu to ni ko nii darukọ rẹ nibi iru aaye yìí, fun idi eyi ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe kọ fun ijọ rẹ kuro nibi ṣíṣe afijọ iṣe yẹn; nitori pe o wa ninu ìṣe awọn Juu ati Nasara, ati pe nitori pe o jẹ oju ọna kan ti o le múni debi ṣiṣe ẹbọ pẹlu Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn.
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, ó gba a wá lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a: “Ọlọhun, má ṣe sọ saare mi di òrìṣà, Ọlọhun ti ṣẹbi lé awọn ijọ kan tí wọ́n sọ saare awọn Anabi wọn di mọṣalaṣi”.
Ahmad ni o gba a waAnabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, képe Oluwa rẹ̀ pé kí o má ṣe sọ saare oun dà gẹ́gẹ́ bí oriṣa ti awọn eniyan n sìn nipa gbigbe titobi fun un ati fífi orí kanlẹ fun un. Lẹhin naa, Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, fún wa ní ìró pé Ọlọhun ti gbe ikẹ Rẹ̀ jìnnà sí awọn tí wọ́n sọ saare awọn Anabi di mọṣalaṣi; nitori sísọ ọ di mọṣalaṣi lè di ọna awawi lati jọsin fún wọn, ati níní adiọkan sí wọn.