





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ó sọ pé: Wọ́n sọ pé: Iwọ Ojiṣẹ Ọlọhun, ta ni yoo ṣoriire jù ninu awọn eniyan pẹlu ìṣìpẹ̀ rẹ ni ọjọ Igbende? Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - dahun bayii wi pe: "Irẹ Abu Hurairah, mo ti rò naa pé ko si ẹnikan ti yoo bi mi leere nipa hadiisi yii saaju rẹ, nigba ti mo ti ri itaraṣaṣa rẹ si imọ hadiisi, Ẹnití ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ mi ní ọjọ Igbende, oun ni ẹniti ó bá sọ pé ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, tí ó ṣo bẹẹ pẹlu ododo lati inu ọkàn rẹ̀".
Bukhaariy gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fun wa ni iro pé dajudaju ẹniti ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ oun ni ọjọ Igbende ni ẹnikẹni tí ó bá sọ pé: "Ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah pẹlu ododo lati inu ọkan rẹ̀" iyẹn ni pe: ko si ẹnikẹni ti a gbọdọ jọsin fun pẹlu ododo ayafi Ọlọhun Allah, ati pe ó gbọdọ là kuro nibi ẹbọ ati kárími.
Lati ọdọ ‘Ubadah - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Ẹni ti o ba jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu ni ọkan soso ti ko si akẹgbẹ fun Un, ati pe dajudaju Muhammad ẹrusin Rẹ ati ojiṣẹ Rẹ ni, ati pe Isa ẹrusin Ọlọhun ni ojiṣẹ Rẹ si tun ni ati pe ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (kun fayakūn) tí Ó sọ ránṣẹ́ sí Mọryam l’Ó sì fi ṣẹ̀dá rẹ̀. Ẹ̀mí kan (tí Allāhu ṣẹ̀dá) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni, ati pe al-jannah ododo ni, ina ododo ni, Ọlọhun a mu u wọ al-jannah lori èyíkéyìí iṣẹ ti o ba wa lori rẹ»
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niOjiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fun wa ni iro pe dajudaju ẹni ti o ba sọ gbolohun mimu Ọlọhun lọkan (Laa illaha illā Allāhu) l'ẹni ti o mọ itumọ rẹ ti o si n ṣiṣẹ tọ nkan ti o n pepe si, ti o si tun jẹrii si jijẹ ẹrusin Muhammad - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati ijẹ ojiṣẹ rẹ, tí o si tun fi jíjẹ́ ẹrusin ati jijẹ ojiṣẹ Isa rinlẹ, Àti pé dajudaju Ọlọhun da a pẹlu gbolohun Rẹ pe "kun" (jẹ bẹ́ẹ̀) ti o si jẹ bẹ́ẹ̀, ati pe o jẹ ẹmi kan ninu awọn ẹmi ti Ọlọhun da, ti o si tun fọ iya rẹ mọ kuro nibi nkan ti awọn Yahudi fi ti si i lọdọ, Ti o si tun ni igbagbọ pe dajudaju al-jannah ododo ni, ati pe ina ododo ni, lẹniti o ni adisọkan bíbẹ mejeeji, ati pe dajudaju awọn mejeeji idẹra Ọlọhun ati ijiya Rẹ ni, Ti o si ku lori iyẹn; nitori naa ibudesi rẹ ni Aljannah koda ki o jẹ alaseeto nibi itẹle, ti awọn ẹṣẹ si n bẹ fun un.
Lati ọdọ Jabir ọmọ Abdullah - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - ó sọ pé: Mo gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti n sọ pe: "Ẹniti ó bá pade Ọlọhun ni ẹniti kò mú orogun kankan pẹlu Rẹ̀, onitọhun yoo wọ Alujanna, ṣugbọn ẹniti ó bá pade Rẹ̀ ni ẹniti ó mú orogun pẹlu Rẹ̀, onitọhun yoo wọ Ina".
Muslim gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye pé ẹnikẹni tí ó bá kú, tí kò mu orogun kankan pẹlu Ọlọhun, Alujanna ni ibupadasi rẹ̀ kódà bí wọ́n bá jẹ ẹ niya nitori apakan ninu awọn ẹṣẹ rẹ̀, ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ku, ni ẹniti n mu orogun pẹlu Ọlọhun, onitọhun yoo wọ inu Ina gbere.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ọrọ kan, emi naa sọ omiran, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba ku ti o si n pe akẹgbẹ kan ti o yàtọ̀ si Ọlọhun, o maa wọ ina" emi naa sọ pe: Ẹni ti o ba ku, ti ko si kii n pe akẹgbẹ kan mọ Ọlọhun, o maa wọ alujanna.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fun wa pe dajudaju ẹni ti o ba yi nnkan kan ninu nnkan ti o jẹ dandan lati jẹ ti Ọlọhun fun ẹni ti o yàtọ̀ si I, gẹgẹ bii pipe ẹni ti o yàtọ̀ si Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- tabi wiwa iranlọwọ lọ sọdọ ẹni ti o yàtọ̀ si I, ti o si ku lori rẹ, dajudaju o maa wa ninu awọn ara ina. Ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- ṣalekun pe dajudaju ẹni ti o ba ku ti ko da nnkan kan pọ mọ Ọlọhun, dajudaju ibuṣẹripadasi rẹ ni alujanna.
Lati ọdọ Abdullah ọmọ Mas'ud ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pé: "Awọn alakatakiti ti parun " ó sọ bẹẹ ni ẹẹmẹta.
Muslim gba a waOjiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fún wa niroo nipa ìpòfo ati ipadanu awọn onilekoko - laisi ìmọ̀nà ati ìmọ̀ - ninu ẹsin ati igbesi aye wọn, ati ninu awọn ọrọ wọn ati awọn iṣẹ wọn, awọn tí wọ́n máa ń tayọ aala ofin sharia tí Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - mú wá fún wa.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Ẹni ti o ba lọ onigbese lára, tabi ti o ba a din in ku tabi ki o ni ki o ma san an mọ́, Ọlọhun maa fi i sábẹ́ ibòji Ìtẹ́-ọlá Rẹ̀ ni Ọjọ́ Àjíǹde, ni ọjọ́ ti ko nii si ibòji kankan àyàfi ibòji Rẹ̀”.
Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé ẹni tí o ba lọ onigbese lára, tabi ti o ba a din gbese rẹ ku, ẹsan rẹ ni pe: Ọlọhun maa fi i sábẹ́ ibòji Itẹ-ọla Rẹ̀ ni Ọjọ́ Àjíǹde ti oorun maa sunmọ orí àwọn ẹrú ti ooru rẹ si maa lágbára, Ẹni kankan ko nii ri ibòji àyàfi ẹni tí Ọlọhun ba fi si abẹ ibòji.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí Ọlọhun ba fẹ oore fún, O maa fi àdánwò kàn án”.
Bukhaariy gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ti Ọlọhun ba fẹ oore fun ọkan ninu awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ mumini, o maa fi àdánwò kan wọn ninu ẹmi wọn ati dúkìá wọn ati ẹbi wọn, torí ìsádi Ọlọhun ti o maa ṣẹlẹ̀ si mumini ninu ẹ pẹ̀lú adua ati pipa awọn iṣẹ buruku rẹ́ ati agbega ní ipò.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Ẹ fi mi sílẹ̀ lópin ìgbà tí mo ba fi yin sílẹ̀, dajudaju nnkan ti o pa awọn ti wọn ṣáájú yin run ni ibeere wọn ati iyapa wọn si awọn anabi wọn, ti mo ba kọ nnkan kan fun yin ẹ jinna si i, ti mo ba pa yin láṣẹ àlámọ̀rí kan ẹ mu u wa de ibi ti ikapa yin ba mọ".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dárúkọ pe dajudaju awọn idajọ ti Sharia pin si awọn ipin mẹta: Nnkan ti wọn dakẹ lori rẹ, ati awọn nnkan ẹkọ, ati awọn àṣẹ. Akọkọ: Oun ni nnkan ti ofin dakẹ nipa rẹ: Pe ko si idajọ, ati pe dajudaju ipilẹ nibi awọn nnkan ni aijẹ dandan; Ṣugbọn ni igba aye rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbigbe ibeere ju silẹ nipa nnkan kan ti ko ṣẹlẹ̀ jẹ dandan ni ti ipaya ki ijẹ dandan tabi ṣíṣe ni èèwọ̀ ma sọkalẹ nipa rẹ, dajudaju Ọlọhun fi i kalẹ ni ti ikẹ fun awọn ẹru, Ṣùgbọ́n lẹyin iku rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti ibeere ba jẹ láti béèrè nipa idajọ ẹsin, tabi lati kọ eeyan ni nnkan ti wọn n bukaata si ninu àlámọ̀rí ẹsin, o lẹtọọ, bi ko ṣe pe o jẹ nnkan ti wọn pa wa láṣẹ pẹlu rẹ, ṣùgbọ́n ti o ba jẹ ọ̀nà láti béèrè ni tipátipá ni, oun ni a gba lero pẹlu gbigbe ibeere ju silẹ nipa rẹ ninu hadiiisi yìí; ìyẹn ri bẹ́ẹ̀ nitori pe o le ja si iru nnkan ti o ṣẹlẹ̀ si awọn ọmọ Ísírẹ́lì, ti wọn pa wọn láṣẹ pe ki wọn du màlúù kan, ka ni pe wọn du èyíkéyìí màlúù ni, wọn ti mu àṣẹ naa ṣẹ, ṣùgbọ́n wọn le koko wọn si le koko mọ wọn. Ikeji: Awọn èèwọ̀; àwọn ni: Nnkan ti wọn maa san ẹni ti o ba gbe e ju silẹ lẹ́san, ti wọn maa fi iya jẹ ẹni ti o ba ṣe e, jijinna si gbogbo rẹ jẹ dandan. Ẹlẹẹkẹta: Awọn aṣẹ; àwọn naa ni nkan ti wọn maa san ẹni ti o ba ṣe e ni ẹsan, ti wọn o si jẹ ẹni ti o ba fi i silẹ ni iya, nitori naa o jẹ dandan ki a ṣe ninu rẹ èyí tí agbara ba ka.
Lati ọdọ Ibnu Abbaas (ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji) Lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu nǹkan ti o gba wa lati ọdọ Oluwa rẹ ti O lágbára ti O gbọnngbọn, o sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun kọ daadaa ati aburu, lẹyin naa O ṣalaye ìyẹn, ẹni tí ó bá gbèrò dáadáa, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pé, ti o ba wa gbero rẹ, ti o wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa mẹ́wàá titi de ìlọ́po ẹẹdẹgbẹrin, titi de ìlọ́po ti o pọ̀, ẹni ti o ba gbèrò aburu, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pe, ti o ba wa gbero rẹ ti o si ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni aburu ẹyọkan”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niÒjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe Ọlọhun ti kádàrá dáadáa ati aburú, lẹyin naa O ṣàlàyé fun awọn malaika méjèèjì bi wọn ṣe maa kọ ọ: Ẹni tí ó bá gbèrò ṣíṣe dáadáa, wọn maa kọ ọ fun un ni dáadáa ẹyọkan koda ki o ma ṣe e, ti o ba wa ṣe e, wọn maa ṣe adipele rẹ pẹlu ìlọ́po mẹ́wàá irú rẹ titi de ìlọ́po ẹẹdẹgbẹrin, titi de ìlọ́po ti o pọ, alekun naa maa wa ni ibamu si bi ọkàn ba ṣe ni imọkanga sí, ati bi àwọn èèyàn ba ṣe ṣe anfaani latara rẹ̀ si, ati ohun ti o jọ ìyẹn. Ẹni tí ó bá gbèrò lati ṣe aburu, lẹyin naa o wa gbe e ju silẹ, wọn maa kọ ọ fun ni dáadáa, ti ko ba wa raye ṣe e pẹlu pe ko ṣe àwọn okunfa rẹ, wọn ko nii kọ nǹkan kan, ti o ba gbe e ju silẹ ni ti ikagara, wọn maa kọ àníyàn rẹ fun un, ti o ba wa ṣe e, wọn maa kọ ọ fun un ni aburu ẹyọkan.