





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: “Ọlọhun, Oníbùkún ti O ga jùlọ, sọ pe: Èmi ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kan, ti o mu orogun ninu rẹ̀ pẹlu Èmi Ọlọhun, Emi yóò fi òun àti orogun rẹ̀ sílẹ̀.
Muslim gba a waAnabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n fun wa ni iro pe: Ọlọhun, Onibukun ti O ga julọ sọ pe: Òun ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún, Òun ni Ẹni tí Ó rọrọ̀ tayọ gbogbo nkan, ati pe ti eniyan bá ṣe iṣẹ ijọsin kan, ti o sì ṣe e fun Ọlọhun ati ohun miiran tó yatọ si Ọlọhun; Ọlọ́hun yoo gbe e ju sílẹ̀, kò nii gbà á lọ́wọ́ rẹ̀, yoo sì dá a padà fún un. Nitori naa, ọranyan ni ki iṣẹ́ jẹ́ mimọ fun Ọlọ́hun Ọba Aleke ọla, nítorí pé, Ọlọ́hun – mimọ fun Un – kò nii gba iṣẹ kan ayafi eyiti ó jẹ́ mimọ lati lè fi ri ojú rere Rẹ̀.
Lati ọdọ Jundub, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Mo gbọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ní o ku ọdún márùn-ún tí ó fi maa jáde láyé, ti o ń sọ wípé: “Dajudaju emi n bọpabọsẹ lọ si ọdọ Ọlọhun pe ki n ní ọrẹ aayo kan laarin yin, nitori pe Ọlọhun Ọba Aleke ọla ti mú mi ní ọrẹ aayo gẹgẹ bi O ti mu Ibrahim ni ọrẹ aayo, ti emi ba ti ẹ fẹ mu ẹnikan ninu awọn ijọ mi ni ọrẹ aayo, emi i ba mu Abu Bakr ni ọrẹ aayo, ẹ gbọ o, dajudaju awọn ijọ tí wọ́n ti lọ síwájú yin a maa mú saare awọn Anabi ati awọn ẹniire inu wọn ni mọṣalaṣi, nitori naa, ẹ má ṣe mú awọn saare ni mọṣalaṣi, dajudaju emi n kọ ọ fún yín”.
Muslim gba a waAnabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n fun wa ni iro nipa ipo rẹ̀ lọdọ Ọlọhun Ọba, ó n sọ pé ipo naa dé ipo ifẹ tó ga julọ, gẹgẹ bi Anabi Ibrahim – Alaafia fun un – ṣe de bẹ, nitori eyi ni Anabi fi sọ pe òun ò ni ọrẹ aayo kankan yatọ si Ọlọhun; nitori pé ọkàn oun ti kún kẹ́kẹ́ fún ìfẹ́ Ọlọhun Ọba ati gbigbe E tobi àti mímọ̀ ọ́n, nítorí náà kò sí ààyè ninu rẹ̀ fún ẹnikẹ́ni yàtọ̀ sí Ọlọ́hun. Tí ó bá jẹ́ pé ó ní ọ̀rẹ́ aayo ninu àwọn ẹ̀dá ni, ìbá jẹ́ Abu Bakr As-Siddiq, kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i. Lẹyin naa ó ní ka sọra kuro nibi ikọja aala ninu ifẹ, gẹgẹ bi awọn Yahudi ati Nasara ti ṣe sí saare awọn anabi ati awọn ẹni rere inu wọn, titi ti wọn fi sọ wọn di ọlọrun ẹbọ ti wọn n jọsin fun wọn dipo Ọlọhun Allah, ti wọn sì kọ mọṣalaṣi ati ile ijọsin sori awọn saare wọn, Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ̀ fun awọn ijọ rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe gẹgẹ bi awọn Yahudi ati Nasara ṣe ṣe.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Dajudaju Ọlọhun maa n jowu, ati pe dajudaju olugbagbọ naa maa n jowu, owu jijẹ Ọlọhun ni ki olugbagbọ maa ṣe nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ fun".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju Ọlọhun maa n jowu, O si maa n binu O si maa n korira, gẹgẹ bi olugbagbọ naa ṣe maa n jowu, ti o si maa n binu, ti o si maa n korira, ati pe okunfa jijowu Ọlọhun ni ki olugbagbọ ṣe nnkan ti O ṣe ni eewọ ninu iwa ibajẹ gẹgẹ bii ṣìná ati ki ọkùnrin maa ba ọkùnrin lò pọ̀, ati ole jija ati ọti mimu, ati eyi ti o yàtọ̀ si wọn ninu awọn iwa ibajẹ.
Lati ọdọ ọmọ umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - ó ní oun gbọ lẹnu ọkunrin kan ti n sọ pe: Rara o, oun fi Kaabah búra, ọmọ umar wa sọ fun un pe: A kò gbọdọ̀ fi nnkan tó yatọ si Ọlọhun Allah búra, tori dajudaju emi gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń sọ pe: "Ẹnikẹni tí ó bá fi ohun miran búra yatọ si Ọlọhun Allah, onitọhun ti ṣe aigbagbọ tabi ka ní ó ti ṣẹbọ."
Abu Daud ati Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fún wa niroo pé ẹnikẹni tí ó bá fi nkan miran búra yatọ si Ọlọhun Allah ati awọn orukọ Rẹ̀ ati awọn iroyin Rẹ̀, onitọhun ti ṣaigbagbọ si Ọlọhun, tabi ka ní ó ti ṣẹbọ pẹlu Rẹ̀; nítorí pé ìbúra ní í ṣe pẹ̀lú ìgbétítóbi fún nkan tí a fi búra, títóbi sì jẹ́ ti Ọlọ́hun Allah nìkan ṣoṣo; nitori naa, a kò gbọdọ̀ bura pẹlu nkankan ayafi Ọlọhun Allah ati awọn orukọ Rẹ̀ ati awọn iroyin Rẹ̀, Mimọ ni fun Un, Ati pé ìbúra yii wà ninu ẹbọ kekere; ṣùgbọ́n bí ẹni tí ó búra bá fi gbé títóbi fun nkan tó fi bura gẹgẹ bii ìgbétítóbi fún Ọlọ́hun Allah tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ; nigba naa, ó ti wà ninu ẹbọ nla niyẹn.
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: «Dajudaju irun ti o wuwo ju fun awọn munaafiki ni irun Ishai ati Asunbaa, ka ni wọn mọ nkan ti n bẹ ninu rẹ - ni ẹsan – ni, wọn o ba wa ki i koda ki o jẹ ni irakoro, ati pe mo ti wa gbero lati paṣẹ ki wọn o gbe irun duro, lẹyin naa ki n wa pa ẹnikan laṣẹ ki o ki i, lẹyin naa ki n wa gbera pẹlu awọn ọkunrin kan ti idi igi wa pẹlu wọn lọ si ọdọ awọn ijọ kan ti wọn o ki n wa ki irun ni masalaasi, ki n si sun ile wọn mọ wọn lori».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ nipa awọn munaafiki ati kikọlẹ wọn nibi wiwa ki irun, agaga julọ irun Ishai ati Asunbaa, ati pe dajudaju ti wọn ba mọ odiwọn ẹsan ati laada ti o wa nibi wiwa ki mejeeji pẹlu janmọọn ni, wọn o ba wa ki i koda ki o jẹ rirakoro gẹgẹ bi ọmọde ṣe maa n rakoro pẹlu ọwọ ati orunkun. Ati pe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ti pinnu lati paṣẹ pe ki wọn o gbe irun duro, ki o wa fi ọkunrin kan si aaye rẹ lati ṣiwaju awọn eeyan, lẹyin naa ki o wa gbera ti awọn ti wọn gbe idi igi lọwọ si wa pẹlu rẹ, lati lọ ba awọn ọkunrin ti wọn o ki n ki irun janmọọn ninu masalaasi, lẹyin naa ki o wa da’na sun ile wọn; latari ini-agbara ẹṣẹ ti wọn ko si nibi iyẹn, - ṣugbọn ko ṣe e – latari awọn ti wọn wa ninu ile bii awọn obinrin ati awọn ọmọde ti wọn o mọ nkankan ati awọn to yatọ si wọn ninu awọn ti wọn ni idiwọ (ti wọn ni awijare), awọn ti ko si ẹṣẹ kankan fun wọn.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: "Dajudaju ninu awọn eniyan ti o buru julọ ni ẹni ti ọjọ igbedide ba ba ti wọn si wa ni alààyè, ati ẹni ti o ba mu awọn saare ni mọsalasi".
Ahmad ni o gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ nipa awọn ti wọn buru julọ ninu awọn eniyan, awọn ni ẹni ti ọjọ igbedide to le wọn lori ti wọn si wa ni alààyè, ati awọn ti wọn maa n mu awọn saare ni awọn mọsalasi, ti wọn maa n kirun nibẹ ati si wọn lara.
Lati ọdọ Mahmud ọmọ Labiid- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Dajudaju nnkan ti mo n bẹru julọ nipa yin ni ẹbọ kekere" wọn sọ pe: Ki ni ẹbọ kekere irẹ ojiṣẹ Ọlọhun? O sọ pe: "Ṣekarimi ni, Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ fun wọn ni ọjọ igbedide ti wọn ba ti san awọn eniyan lẹsan pẹlu awọn iṣẹ wọn pé: Ẹ lọ ba awọn ti ẹ maa n ṣe karimi fun ni aye, ki ẹ si wo boya ẹ maa ri ẹsan kankan lọdọ wọn?"
Ahmad ni o gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju nnkan ti o pọ julọ ti oun n bẹru rẹ lori awọn ijọ rẹ ni: Ẹbọ kékeré, oun ni: Ṣekarimi; ki o maa ṣiṣẹ nitori awọn eniyan. Lẹyin naa o sọ nipa iya awọn oniṣekarimi ni ọjọ igbedide, pe wọn maa sọ fun wọn pé: Ẹ lọ ba awọn ẹni ti ẹ n ṣiṣẹ nitori wọn, ki ẹ si wo boya wọn kapa sisan yin lẹ́san ati fifun yin ni ẹsan lori iṣẹ yẹn?!
Lati ọdọ ọmọ Abbas - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ fun Muaz ọmọ Jabal, nigba ti ó ran an lọ sí ilu Yemen pé: "Iwọ yoo lọ sí ọdọ awọn eniyan kan ti wọ́n jẹ́ oni-tira sánmọ̀, tí o bá dé ọdọ wọn, pẹ̀ wọn kí o sọ fún wọn pé kí wọ́n jẹrii pé dajudaju ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, ati pé dajudaju Anabi Muhammad Ojiṣẹ Ọlọhun ní n ṣe, tí wọ́n bá gba ẹ gbọ́ nínú ìyẹn, sọ fún wọn pé dajudaju Ọlọhun ti ṣe irun wakati márùn-ún ní ọranyan lé wọn lori ni ojoojumọ, tí wọ́n bá gba e gbọ́ nínú ìyẹn, sọ fún wọn pé Ọlọ́hun ti ṣe zakat ní ọranyan lé wọn lori, kí wọ́n maa gbà a lọ́wọ́ àwọn olówó inu wọn, kí wọ́n sì maa fún awọn talaka inu wọn, tí wọ́n bá gba ẹ gbọ́ nínú ìyẹn, ó wá dọwọ́ ẹ o nibi awọn nkan tó niye lori ninu awọn dukia wọn, kí o sì bẹ̀rù ipepe eni tí a ṣe àbòsí sí, nítorí pé kò sí gaga kankan láàrín rẹ̀ àti Ọlọ́hun".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niNigba ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - rán muaz ọmọ Jabal - ki Ọlọhun yọnu si i - lọ sí ilu Yemen lati lọ kéde ẹ̀sìn Ọlọhun fún wọn, kí ó sì kọ́ wọn ní ìmọ̀ ẹ̀sìn Islam, ó ṣalaye fun un pé dajudaju ó máa ṣalabapade awọn ọmọ Kristẹni kan nibẹ; nitori naa, ki o gbaradi fun wọn, lẹyin naa, ki o bẹrẹ ikede ẹsin Islam fun wọn pẹlu sísọ nkan tó pataki julọ, lẹyin naa ki o wá sọ nkan tó pataki tèlé e, Kí ó kọ́kọ́ pè wọ́n lọ síbi ṣiṣatunṣe igbagbọ wọn; iyẹn ni pé kí wọ́n jẹrii pé dajudaju kò sí ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, ati pé dajudaju Anabi Muhammad Ojiṣẹ Ọlọhun ní n ṣe; Nítorí pé eyi ni ó máa mú wọn wọ inu ẹsin Islam, tí wọ́n bá ti gbà lati ṣe iyẹn, kí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ waa pa wọ́n laṣẹ pé kí wọ́n maa gbé ìrun duro; nitori pe irun ni iṣẹ ọranyan tí ó tóbi jùlọ lẹyin tí a bá ti ṣe Ọlọhun lọ́kan, tí wọ́n bá gbé irun naa duro, kí o pa àwọn olówó inu wọn láṣẹ pé kí wọ́n yọ zakat owó wọn fún àwọn tálákà inu wọn, lẹ́yìn náà, Anabi ṣe ìkìlọ̀ fún Muaz pé kó má ṣe gba owó tó níye lórí jù lọ; nitori pe eyi tó jẹ́ ọranyan ni eyi tó wà ní iwọntun-wọnsì lẹyin naa, ó tún gbà á nímọ̀ràn pé kó jìnà sí àbòsí; nitori ki ẹni tí ó bá ṣabosi sí má baa ṣepe fun un, nitori pé dajudaju adura rẹ̀ maa gbà.
Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattab - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń ṣo pé: "Ẹ má ṣe yìn mi jù gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe yin ọmọ Maria jù; ẹrú Ọlọhun ni ẹmi n ṣe, nitori naa, ẹ wi pe: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀".
Bukhaariy gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n kọ̀ fun wa kuro nibi ìyinnijù ati ikọja aala ofin sharia nibi yiyin-in ati riroyin rẹ̀ pẹlu awọn iroyin Ọlọhun Ọba ati awọn iṣẹ tó jẹ́ ti Ọlọhun nikan ṣoṣo, tabi kí a sọ pé Anabi ní imọ kọ̀kọ̀, tabi ki a maa pe e papọ mọ Ọlọhun, gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe ṣe pẹlu Isa ọmọ Maria - ki alaafia Ọlọhun maa ba a. Lẹyin naa, Anabi ṣalaye pé ẹru kan ninu awọn ẹru Ọlọhun ni oun, ó sì paṣẹ pé ki a maa sọ nipa oun bayii pé: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀.