





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ 'Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Gbogbo yín ni adaranjẹ, ẹni ti a maa beere awọn ti o dajẹ lọwọ rẹ ni ẹni kọọkan yín,, adari fun awọn eniyan jẹ adaranjẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa wọn, ọkunrin ni adaranjẹ lori awọn ara ile rẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa wọn, obinrin ni adaranjẹ lori ilẹ baale rẹ ati ọmọ rẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa wọn, ẹru jẹ adaranjẹ lori dukia olowo rẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa rẹ, ẹ tẹti ẹ gbọ́, gbogbo yin ni adaranjẹ ati pe gbogbo yin ni wọn maa bi leere nipa ẹni ti o dajẹ".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ojúṣe kan jẹ dandan fun gbogbo Musulumi ni awujọ ti o ma maa ṣọ ọ ti o si maa gbe e ru, Imam ati adari jẹ adaranjẹ nibi nnkan ti Ọlọhun fi wọn ṣọ́, sisọ awọn ofin wọn jẹ dandan fun un, ati didaabo bo wọn kuro lọdọ ẹni ti o ba ṣe abosi si wọn, ati gbigbe ogun ti ọta wọn, ati aima ra awọn ẹtọ wọn lare, Ati pe ọkunrin nipa awọn ara ile rẹ jẹ ẹni ti ninawo fun wọn jẹ dandan le e lori, ati biba wọn lo daadaa, ati kikọ wọn nimọ ati kikọ wọn lẹkọọ, Ati obinrin ninu ile ọkọ rẹ jẹ adaranjẹ pẹlu didari ile rẹ daadaa, ati titọ awọn ọmọ rẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa ìyẹn, Ati pe ọmọ ọdọ ti o jẹ ẹrú ati alagbaṣe jẹ adaranjẹ nibi dukia olowo rẹ pẹlu sisọ nnkan ti o n bẹ lọwọ rẹ lati ọdọ rẹ, ati sinsin in, oun ni wọn maa bi leere nipa ìyẹn, Ati pe gbogbo olúkúlùkù ni adaranjẹ nibi nnkan ti wọn fi ṣọ́, ati pe gbogbo olúkúlùkù ni wọn maa bi leere nipa ẹni ti o n dajẹ.
Lati ọdọ 'Uthman- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: "Ko si ninu ọmọniyan to jẹ musulumi ti irun ọran-anyan kan wa ba a, ti o wa ṣe aluwala rẹ daadaa ati ipaya rẹ ati rukuu rẹ, afi ki o jẹ ipa ẹṣẹ rẹ fun nnkan ti o ṣíwájú ninu awọn ẹṣẹ, niwọn igba ti ko ba mu ẹṣẹ nla wa, gbogbo igba si ni ìyẹn maa ri bẹ́ẹ̀".
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ko si ninu musulumi kan ti asiko irun ọran-anyan maa wọle ba a ti o si ṣe aluwala rẹ daadaa ti o si pe e, lẹyin naa o n paya nibi irun rẹ pẹlu pe ọkan rẹ ati awọn orikee rẹ gbogbo rẹ dojukọ Ọlọhun ti wọn n ranti titobi Rẹ lori irun, O si pe awọn iṣẹ irun gẹgẹ bii rukuu ati iforikanlẹ ati eyi ti o yàtọ̀ si i, afi ki irun yii jẹ ipa ẹṣẹ rẹ fun nnkan ti o ṣíwájú ninu awọn ẹṣẹ kekere, niwọn igba ti ko ba ti da ẹṣẹ nla kan ninu awọn ti o tobi ninu awọn ẹṣẹ, ati pe ọla yii ma maa lọ bẹẹ pẹlu lilọ igba ati nibi gbogbo irun.
Lati ọdọ Ka‘bu ọmọ ‘Ujroh - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Awọn gbolohun ẹyin irun kan n bẹ ti o ṣe pe ẹni ti o ba sọ wọn - tabi ti o ṣe wọn - ni ẹyin gbogbo irun ọranyan, ko ni mofo, subhānallāh ọgbọn ati mẹta, ati alhamduliLlāhi ọgbọn ati mẹta, ati Allāhu akbar ọgbọn ati mẹẹrin».
Muslim gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo nipa awọn iranti ti ẹni ti o ba n sọ ọ o le mofo ti ko si le kabamọ, bi ko ṣe pe ẹsan awọn gbolohun yii a maa bẹ fun un, wọn o si maa wa lẹyin ara wọn, ti wọn o si tun maa sọ wọn lẹyin irun ọranyan, oun naa ni: "Subhānallāh" ọgbọn ati mẹta, iyẹn ni fifọ Ọ mọ kuro nibi adinku. Ati "AlhamduliLlāhi" ni igba ọgbọn ati mẹta, ati pe oun ni ìròyìn Ọlọhun pẹlu pipe papọ mọ ninifẹẹ Rẹ ati gbigbe titobi fun Un. Ati "Allāhu akbar" ni igba ọgbọn ati mẹẹrin, nitori pe Ọlọhun tobi O si gbọnngbọn ju gbogbo nkan lọ.
Lati ọdọ Sadu ọmọ Abi waqqoosi, ki Ọlọhun yọnu si i, lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Ẹni ti o ba sọ nigba ti o n gbọ oluperun pe ash-hadu an laa ilaaha illa Allāhu wahdahu laa sharika laHu, wa anna muhammadan ‘abduHu wa rosuuluhu, rodiitu bil Laahi robban wa bi muhammadin rosuulan wa bil Isilaami diina, wọn a fi ori ẹṣẹ rẹ jin in.
Muslim gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju ẹni ti o ba sọ nigba ti o n gbọ oluperun pe Ash-hadu an laa illaha illā Allāhu wahdahu laa sharika laHu" itumọ rẹ ni: Mo n fi rinlẹ wipe dajudaju ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Ọlọhun, ati pe gbogbo nkan ti wọn n sìn yatọ si i ibajẹ ni in. Wa anna muhammadan ‘abduHu wa rosuuluhu" ìtumọ rẹ ni: Dajudaju ẹru ni wọn o ki n jọsin fun un, ati pe ojiṣẹ ni ti ko ki n parọ, Rodiitu bil Laahi Robban" itumọ rẹ ni: Pẹ̀lú ijẹ Oluwa Rẹ, ati ijẹ Ọlọhun Rẹ, ati awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ, Wa bi muhammadin rosuula" itumọ rẹ ni: Pẹlu gbogbo nkan ti wọn fi ran an, ti o si mu un de etiigbọ wa, wa bil Islam" itumọ rẹ ni: Pẹlu gbogbo awọn ìdájọ́ Isilaamu bii awọn aṣẹ ati awọn nnkan ti wọn kọ̀, "Diinan” itumọ rẹ ni: Ni ti adisọkan ati itẹle, "Gufiro lahu dhanbuhu" itumọ rẹ ni: Awọn ẹṣẹ kekere.
Lati ọdọ Jaabir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Umar ọmọ Khatob fun mi niroo pe: Dajudaju arakunrin kan ṣe aluwala ni o wa fi aaye eekanna silẹ nibi ẹsẹ rẹ, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ri i ti o si sọ pe: «Pada ki o si lọ ṣe aluwala rẹ daadaa» ni o ba pada, lẹyin naa ni o kirun.
Muslim gba a waUmar - ki Ọlọhun yọnu si i - funni niroo pe dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ri arakunrin kan ti o ti pari aluwala rẹ, ti o wa fi deedee eekanna silẹ nibi ẹsẹ rẹ ti ko mu omi aluwala de ibẹ, Ni o wa sọ lẹni ti o na'ka si aaye aṣeeto yẹn: Pada ki o lọ ṣe aluwala rẹ daadaa ki o si pe e ki o si tun fun oríkèé kọọkan ni ẹtọ rẹ ninu omi, Ni arakunrin naa ba pada ti o sì lọ pe aluwala rẹ lẹyin naa ni o kirun.
Lati ọdọ Umu ‘Atiyyah - ki Ọlọhun yọnu si i - o jẹ ẹni ti o gbe adehun (ibura) fun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o sọ pe: A jẹ ẹni ti kii ka omi ti awọ rẹ f'ara pẹ dúdú, ati omi alawọ iyeye lẹ́yìn imọra si nǹkan kan.
رواه أبو داود بهذا اللفظ ورواه البخاري بدون زيادة (بعد الطهر)Saabe lobinrin Umu ‘Atiyyah - ki Ọlọhun yọnu si i - sọ pe dajudaju awọn obinrin ni igba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o ki n ka omi ti o maa n jade ni oju ara obinrin- ti awọ rẹ f'ara pẹ dúdú, tabi awọ iyeye - lẹyin riri imọra nibi ẹjẹ nǹkan oṣu: wọn o ki n ka a si ẹjẹ nǹkan oṣu, nitori naa wọn o ki n fi irun ati aawẹ silẹ nitori rẹ.
Lati ọdọ 'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju o sọ pe: Dajudaju Ummu Habeebah ọmọ Jahsh ti o wa labẹ 'Abdur Rahman ọmọ 'Aof, o gbe ẹjọ́ ẹjẹ lọ sọ́dọ̀ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ fun un pé: "Ẹ koraro ni odiwon igba ti nnkan oṣu rẹ ba fi de ọ mọle, lẹyin naa ki o wẹ". O si jẹ ẹni ti maa n wẹ nibi gbogbo irun.
Muslim gba a waẸnikan ninu awọn saabe lobinrin fi ẹjọ àìdá ẹjẹ rẹ sun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, O wa pa a láṣẹ kí ó má kirun ni odiwọn igba ti ẹjẹ nnkan oṣu rẹ fi maa n dè é mọle ṣíwájú ki àlámọ̀rí pajawiri yii o to ṣẹlẹ̀ si i, lẹyin naa o maa wẹ, o si maa kirun, o si jẹ ẹni ti maa n fínnú-fíndọ̀ wẹ fun gbogbo irun kọọkan.
Lati ọdọ Amru ọmọ Sulaym Al-Ansari, o sọ pe: Mo n jẹ́rìí sí Abu Saheed pe o sọ pe: Mo n jẹrii si ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - o sọ pe: «Iwẹ ọjọ Jimoh jẹ dandan lori gbogbo ẹni ti o ti balaga, ki o si fi pako run awọn eyin rẹ, ki o si lo lọ́fíńdà ti o ba ri».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju iwẹ ọjọ Jimoh kanpa o da gẹgẹ bii ọranyan fun gbogbo ọkunrin ti o ti balaga ninu awọn musulumi ninu awọn ti Jimoh jẹ dandan fun. Ati pe ki o mọ awọn eyin rẹ pẹlu pákò ati nkan ti o jọ ọ. Ati ki o lo lọ́fíńdà pẹlu èyíkéyìí oorun aladidun.
Lati ọdọ Sa‘eed Al-Khuduriy - ki Ọlọhun yọnu si i - o jẹ ẹni ti o kopa ninu ogun mejila pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: Mo gbọ nkan mẹẹrin ni ẹnu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o si jọ mi l'oju, o sọ pe: «Obinrin ko gbọdọ ṣe irin-ajo ti o to ọjọ meji ayaafi ki ọkọ rẹ tabi eleewọ rẹ o wa pẹlu rẹ, ko si si aawẹ ni ọjọ meji: Itunu awẹ ati ileya, ko si tun si irun lẹyin asunbaa titi ti oorun o fi yọ, ko si si lẹyin Asri naa titi ti yio fi wọ, wọn o si tun gbọdọ di ẹru irin-ajo ayaafi lati lọ si masalasi mẹta: Masalasi abeewọ, ati masalasi aqsa, ati masalasi mi yii».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ kuro nibi awọn alamọri mẹẹrin kan: Alakọkọọ rẹ: Kikọ fun obinrin kuro nibi ṣiṣe irin-ajo ọjọ meji lai si pẹlu ọkọ rẹ tabi ẹnikan ninu awọn eleewọ rẹ oun naa ni ẹni ti wọn ṣe fifẹ ẹ (ọmọbinrin naa) ni eewọ fun un ni ṣiṣe leewọ gbere ninu awọn alasunmọ-ọn, gẹgẹ bii ọmọ ati baba, ọmọkùnrin ọmọ-iya rẹ ọkunrin ati ọmọkùnrin ọmọ-iya rẹ obinrin, ati ọmọ-iya baba rẹ l'ọkunrin ati ọmọ-iya iya rẹ l'ọkunrin, ati awọn to jọ bẹ́ẹ̀. Ẹlẹẹkeji rẹ: Kikọ kuro nibi gbigba aawẹ ọjọ ọdun itunu ati ọjọ ọdun ileya, ki baa ṣe pe musulumi gba mejeeji ni gbigba ti ẹ̀jẹ́, tabi aṣegbọrẹ, tabi itanran. Ẹlẹẹkẹta rẹ: Kikọ kuro nibi kiki irun naafila lẹyin irun Asri titi ti oorun o fi wọ, ati lẹyin yiyọ aarọ titi ti oorun o fi yọ. Ẹẹkẹrin rẹ: Kikọ kuro nibi ṣiṣe irin-ajo lọ si aaye kan ninu awọn aaye ati nini adisọkan ọla rẹ ati nini adisọkan pe adipele ẹsan wa nibẹ yatọ si awọn masalasi mẹta, nitori naa a ko gbọdọ di ẹru irin-ajo lọ si ibi ti o yatọ si wọn lati lọ kirun nibẹ, torí pé dajudaju adipele o ni maa ba ẹsan ayaafi ni awọn masalasi mẹta yii, masalasi abeewọ (kahbah), ati masalasi Anabi, ati masalasi aqsa.