Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way






























Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
Òjíṣẹ Ọlọhun (kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) fún wa ní ìró idunnu pé ẹni tí eruku bá bo ẹsẹ rẹ mejeeji nígbàtí o njagun sí oju-ọna Ọlọhun pe iná kò ní jó ẹni na.
Abu Qotaada ará Madinah ki Ọlọhun yonu si nsọ nipa onígbèsè rẹ kan ti n fara pamọ́ fún, ni o ba ri, ni onígbèsè náà bá sọ pé: "ará o dé mi, mi o ti ni owó lati fi sàn gbèse rẹ. Ní Abu Qotaada ki Ọlohun yọnu si bá ní kí ofi orúkọ Ọlọhun búra pé kò sí òwò lọwọ oun? Ni o ba fi orukọ Ọlọhun búra fún pe ootọ ní òun sọ, Ni Abu Qotaada ki Ọlọhun yọnu si bá sọ pé òun gbọ ti Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati Ọlá Rẹ má ba) ti nsọ pe: Ẹní tí yóò bá dún mọ ki Ọlọhun sakoyọ rẹ ni bi ìbànújẹ ọjọ igbende àti ilékoko ọjọ náà ati awọn ìbẹrù rẹ ko yá se idẹra fún ẹni tí kò lágbára láti san gbèse rẹ lasiko, pẹlú pe ko fi kun àsìkò ṣiṣan tábì ki o dín kù tabi ki o bùn ní gbogbo ẹ.
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe wa lojukokoro lori akolekan irun tutu mejeeji, awọn mejeeji ni irun Asunbaa ati irun Alaasari, o si fun wa ni iro idunnu pe ẹni ti o ba mu mejeeji wa pẹlu ẹtọ mejeeji ninu asiko ati ni janmọọn ati eyi ti o yàtọ̀ si ìyẹn, mejeeji maa jẹ okunfa wiwọ alujanna rẹ.
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- sọ fun wa wí pé ti musulumi ba ki Irun ni janmọọn, Irun rẹ ni ọla ju Irun rẹ ni ile tabi ni ọja lọ ni ọ̀nà igba ti o le ni ogún. Lẹ́yìn naa ni o sọ okùnfà ìyẹn: Oun naa ni pé ti ọkùnrin kan ba ṣe aluwala ti o si pari aluwala naa ti o si ṣe e daadaa, ti o wa jade lọ si mọ́sálásí, ti ko si si ohun ti o gbe e jade ayafi ìrun, ko nii gbe ẹsẹ kan àyàfi ki wọn ṣe ipo to ga ati aaye to ga fun un, ki wọn si tun fi pa àṣìṣe rẹ rẹ. Ti eniyan ba wọ inu mọṣalaṣi ti o si jokoo ti o n duro fun Irun, yìo gba ẹ̀san Irun lopin ìgbà tí ó bá ṣi n retí irun, àwọn Malaika a maa se adua fun un, ni igba ti o ba wa ni ori ìjókòó ti o ti kirun, wọn maa sọ pe: Ọlọhun, dárí jin in, Ọlọhun, ṣãnu fun un, Ọlọrun, gba ironupiwada rẹ,” , lopin ìgbà tí aluwala rẹ ko ba i tii bajẹ, ti ko si ṣe ipalara fun eniyan tabi awọn angẹli.
Annabi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ o máa ba a- ṣe alaye pé eewọ ni lati ta ẹjẹ musulumi silẹ, àyàfi tí o ba ṣe ọkan nínú awọn nkan mẹta (wọnyi): Alakọkọ: ẹni tí o ba ṣe àgbèrè (zina), tí o si jasi pe o ti ṣe ìgbeyàwó l'ọna tí o lalaafia, nigbanaa o tọ kí a o sọ l'oko pa (titi ti ẹmi o fi bọ lara rẹ). Ẹlẹẹkeji: ẹnikẹni ti o ba maama pa ẹmi kan (ti a se l'eewọ lati pa) laisi ẹtọ, a o pa oun naa di pẹlu awọn majẹmu (ati ofin) ti o ro papọ mọ. Ẹlẹkẹta: ẹni tí o ba yapa kúrò láàrin awujọ awọn musulumi, bóyá nipa fífi ẹṣin Islam silẹ nipasẹ (Ridda), tabi ẹni tí o nya pá l'ọtọ lai ṣe (Ridda) nipasẹ fífi apakan (ofin Islam) silẹ, gẹgẹ bi awọn obilẹjẹ ènìyàn, àti awọn adigun jàle, ati awọn olujagun nínú àwọn Khawaarij àti awọn miran.
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi àwọn irun maraarun-un lojoojumọ nibi imukuro rẹ ati pipa awọn ẹṣẹ kéékèèké rẹ ati awọn àṣìṣe, o fi we akeremọdo kan ti o wa ni ẹnu ọ̀nà ọmọniyan ti o n wẹ ninu rẹ lojoojumọ ni ẹẹmaraun-un, ti ko nii ṣẹ nnkan kan ku ninu ìdọ̀tí rẹ ati ẹgbin rẹ.
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju o jẹ dandan lori baba lati pa awọn ọmọ rẹ láṣẹ- lọkunrin ati lobinrin- pẹlu irun ti awọn ọjọ ori wọn ba wa ni ọdun meje, ki o si kọ wọn ni nnkan ti wọn bukaata si lati gbe e duro. Ti wọn ba ti pe ọdun mẹwaa, o maa lekun ninu alamọri náà, o maa na wọn lori aṣeeto nibẹ, o si maa ya wọn nibi ibùsùn.
Àwọn saabe beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa bi wọn ṣe maa ṣe asalatu fun un? Lẹyin mimọ bi wọn ṣe maa salamọ fun un nibi ataya: "As salaamu alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu...."? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun wọn bi wọn ṣe maa ṣe asalatu fun un, ìtumọ̀ rẹ ni pe: "Allahumo solli 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin" O túmọ̀ si pe: Ṣe ẹyin fun un pẹlu iranti ti o rẹwa ni ọdọ àwọn malaika, ati fun awọn olutẹle rẹ ninu ẹsin rẹ, ati awọn olugbagbọ ninu awọn alasunmọ rẹ. "ka maa sollaita 'alaa aali Ibrahim" Gẹgẹ bi o ṣe da ọla lori awọn ara ile Ibrahim- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- awọn ni Ibrahim ati Isma'il ati Ishaq ati awọn arọmọdọmọ wọn ati awọn olutẹle wọn ti wọn jẹ olugbagbọ, nitori naa, so ọla Rẹ mọ Muhammad- kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-. "Innaka Hamiidun Majeedun" O n túmọ̀ si pe: Ọba ti a n gbe ẹyin fun nibi paapaa Rẹ ati awọn iroyin Rẹ ati awọn iṣẹ Rẹ, Ọba ti O gbòòrò nibi titobi Rẹ ati àṣẹ Rẹ ati ọrẹ Rẹ. "Allahumo baarik 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin, ka maa baarokta 'alaa aali Ibrahim" O n túmọ̀ si pe: Fun un ninu oore ati apọn-ọnle eyi ti o tobi julọ ninu rẹ, ki o si ṣe alekun rẹ ki o si fi i rinlẹ.
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju irun o le ni alaafia ayaafi pẹlu kika suuratul Faatiha, o si jẹ origun kan ninu awọn origun irun nibi gbogbo rakaha.