





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Abu Hurayra- ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-: «Ẹni ti o ba ṣe afọmọ fun Ọlọhun (Subhānallāh) ni ẹyin gbogbo irun kọọkan ni igba mẹtalelọgbọn, ti o si tun dupẹ fun Ọlọhun (AlhamduliLlāhi) ni igba mẹtalelọgbọn, ti o tun wa gbe titobi fun Ọlọhun (Allāhu akbar) ni igba mẹtalelọgbọn, ìyẹn jẹ ọgọrun din ẹyọkan, ti o wa sọ ni ipari ọgọ́rùn-ún pe: Lā ilaha illā Allāhu wahdahu lā sharīka laHu, laHul mulku, wa laHul hamdu, wa Huwa alā kulli shayhin qadīr, wọn o fi ori gbogbo ẹṣẹ rẹ jin in kódà ki o to deede fóòmù ori omi okun».
Muslim gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ẹni ti o ba sọ lẹyin ti o ba pari awọn irun ọranyan: Ni igba mẹtalelọgbọn pe: “Subhaanollooh”, oun naa ni mimọ Ọlọhun kuro nibi àléébù. Ati ni igba mẹtalelọgbọn: "AlhamduliLlāhi" oun naa ni yiyin In pẹlu awọn iroyin pipe pẹlu inifẹẹ Rẹ ati gbigbe E tobi. Ati ni igba mẹtalelọgbọn: "Allāhu akbar” oun ni pe Ọlọhun ni O tobi ju Oun si ni O gbọnngbọn ju gbogbo nkan lọ. ki o mu onka naa pe ọgọ́rùn-ún pẹlu gbolohun: "Lā ilaha illā Allāhu wahdahu lā sharīka laHu, laHul mulku, wa laHul hamdu, wa Huwa ala kulli shayhin qadeer" itumọ rẹ si ni pe: Ko si ẹni ti ijọsin tọ si pẹ̀lú ẹtọ ayaafi Ọlọhun ni Oun nikan ṣoṣo ko si orogun fun Un, ati pe Oun- mimọ n bẹ fun Un- nìkan ni O ni ìjọba ti o pe, ti O si lẹtọọ si ẹyin pẹlu ifẹ ati igbetobi yatọ si ẹlòmíràn tí ó yatọ si I, ati pe Oun ni Olukapa ti nkankan o si le da A ni agara. Ẹni ti o ba wa sọ ìyẹn wọn yio pa aṣiṣe rẹ rẹ wọn o si ṣe aforijin rẹ, koda ki o pọ bi foomu funfun ti maa n leke omi okun nígbà tí o ba n ru soke.
Lati ọdọ Abu Umāmah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹni ti o ba ka āyatul kursiyyu ni ẹyin irun ọranyan kọọkan, ko si nkan ti yio di i lọwọ wiwọ al-jannah ayaafi ki o ku.
رواه النسائي في الكبرىAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba ka āyatul kursiyyu lẹyin ipari irun ọranyan, ko si nkankan ti o le ma jẹ ki o wọ alujanna ayaafi iku; o si wa ninu sūratul Baqorah, gbolohun Ọlọhun ti ọla rẹ ti o sọ pe: {Allahu la ilaha illa Huwa al-Hayyu al-Qayyoomu la ta‘khuthuHu sinatun wala nawmun laHu ma fis samāwāti wama fil ardi man dha ladhī yashfa‘u indaHu illa bi-idhniHi ya‘lamu mā bayna aydīhim wamā khalfahum wala yuhītūna bishayin min ‘ilmiHi illa bimā shaa'a wasi‘a kursiyyuHus samāwāti wal-arda wala ya’ūduHu hifdhuhumā waHuwal ‘aliyyu alAadhīm} [Al-Baqorah: 255]
Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khudriy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ti ẹnikẹni ninu yin ba ṣe iyemeji nibi irun rẹ, ti ko si mọ iye ti o ki boya mẹta ni tabi mẹrin, ki o yaa ju iyemeji naa nù, ki o mọ irun rẹ lori nnkan ti o da a loju, lẹyin naa, o maa forikanlẹ ni iforikanlẹ ẹẹmeji ṣíwájú ki o to salamọ, ti o ba ki marun-un wọn maa ṣe irun rẹ ni nǹkan ti eéjì le pin fun un, ti o ba ki i lati pe mẹrin, mejeeji maa jẹ iyẹpẹrẹ fún èṣù".
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju olukirun ti o ba ṣe iyemeji nibi irun rẹ ti ko mọ iye ti o ki, boya mẹta ni tabi mẹrin? Ki o gbe onka ti o lekun ti o n ṣe iyemeji nipa rẹ jinna ki o ma lo o: mẹta ni o da a loju, o maa ki rakah kẹrin, lẹyin naa o maa forikanlẹ ni iforikanlẹ ẹẹmeji ṣíwájú ki o to salamọ. Ti o ba ṣe pe nnkan ti o ki jẹ mẹrin ni òtítọ́; o maa di marun-un pẹlu alekun rakah kan, ti iforikanlẹ mejeeji ti igbagbe maa jẹ ijirọ fun rakah kan, onka naa maa jẹ nǹkan ti eéjì le pin ko nii jẹ nǹkan tí eeji ko le pin: Ti o ba wa ki mẹrin pẹlu rakah ti o lekun; o maa jẹ pe o ti ṣe nnkan ti o jẹ dandan fun un laisi alekun tabi adinku. Iforikanlẹ igbagbe mejeeji jẹ iyẹpẹrẹ fún shaytaan ati ile e jina, ati lile e jina si erongba rẹ; torí pé o ti da irun rẹ ru mọ ọn l'oju, ti o si tun fẹ ba a jẹ, ati pe irun ọmọ Anabi Ādam pe nígbà tí o ba ti tẹle aṣẹ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pẹlu iforikanlẹ eleyii ti èṣù yapa nitori rẹ, nígbà tí o kọ lati tẹle àṣẹ Ọlọhun pẹlu fifi orikanlẹ fun Ādam.
Lati ọdọ ọmọ Umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira ọti ni, ati pe gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira eewọ ni, ati pe ẹni ti o ba mu ọti ni aye ti o wa ku ni ẹni ti o kúndùn rẹ ti ko tuuba, ko nii mu un ni ọjọ ikẹyin».
رواه مسلم وأخرج البخاري الجملة الأخيرة منهAnabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ṣe alaye pe dajudaju gbogbo nkan ti o ba ti le mu laakaye lọ ni ọti ti n pa eeyan, yala o jẹ mímu tabi jijẹ tabi fifin simu tabi eyi ti o yato si i, ati pe dajudaju gbogbo nkan ti o le muni maa hunrira ti O si maa pa laakaye ni Ọlọhun Ọba ti O biyi ti O gbọnngbọn ti ṣe e ni eewọ ti O si tun kọ kuro nibẹ, kekere rẹ ni ati pipọ rẹ, Ati pe gbogbo ẹni ti o ba mu èyíkéyìí ninu awọn iran nkan ti o máa ń muni hunrira, ti o tun wa dunni mọ mimu un ti ko si tun tuuba ninu rẹ ti o fi ku; onítọ̀hún ti lẹtọọ si Iya Ọlọhun pẹlu ṣiṣe mimu un ni eewọ fun un ninu al-jannah.
Láti ọdọ Anas - ki Ọlọhun yọnu si i - dájúdájú Anọbi (kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) sọ pé: "E ṣe ìgbìyànjú igbogunti awon olusẹbọ pẹlu Ọlọhun pẹlu owo yin ati èmi yín àti ahán yin".
رواه أبو داود والنسائي وأحمدAnọbi (kí ikẹ Ọlọhun ati ọlá Rẹ máa bà) pa wà lasẹ lati gbógun ti alaigbagbọ, ki a sì ná ìgbìyànjú láti dájú kọ won pẹlu gbogbo ọnà tí a ni ìkápá le lórí nítorí kì gbólóhùn ati ọrọ Ọlọhun le wa loke, nínú ìgbìyànjú náà ni: Alakọkọ: nina owó àti dukia lati fi gbógun ti won, bí rírà nkan ijagun, ati ìnáwó lórí awon jagunjagun ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ẹlẹkeji: ki a jàdé pẹlu emi ati ará lati lọ pàdé won ati lati da won pàdà. Ẹlèkẹta: pẹlu pípé won síbi ẹṣin Islam yi pẹlú ahán, ati ifi idi ọrọ ati ẹri rinlẹ fún won ati ijagbe mọ won ati ìfun won lèsi.
Lati ọdọ Khuraim ọmọ Faatik- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Mẹ́fà ni àwọn iṣẹ́, mẹrin si ni àwọn èèyàn, méjì maa n sọ nǹkan di dandan, ati èyí ti o ṣe pe déédéé iṣẹ ti eeyan ba ṣe naa ni ẹsan rẹ, ati eyi ti o ṣe pe iṣẹ rere kan pẹlu ẹsan mẹ́wàá ni, ati eyi ti o ṣe pe iṣẹ rere kan pẹlu ẹẹdẹgbẹrin ẹsan ni, ṣe ẹ wa ri méjì tii sọ nǹkan di dandan: Ẹni tí ó bá kú, ti ko si da nnkan kan pọ mọ Ọlọhun, yoo wọ alujanna, ẹni tí ó bá kú ti o si da nnkan pọ mọ Ọlọhun, yoo wọ ina, ṣe ẹ wa ri èyí ti o ṣe pe déédéé iṣẹ ti eeyan ba ṣe naa ni ẹsan rẹ: Ẹni ti o ba gbèrò dáadáa títí ti ọkàn rẹ fi mọ ọn lára, ti Ọlọhun si mọ ọn lati ọdọ rẹ, wọn maa kọ ọ silẹ fun un ni ẹsan kan, ẹni tí ó bá ṣe aburu kan, wọn maa kọ ọ silẹ fun un ni aburu kan, ẹni tí o ba ṣe dáadáa kan, o maa gba ẹsan mẹ́wàá irú rẹ, ẹni tí ó bá na owó si oju-ọna Ọlọhun, dáadáa kan maa wa pẹlu ẹsan ẹẹdẹgbẹrin, ṣùgbọ́n àwọn èèyàn, o n bẹ ninu wọn ẹni ti Ọlọhun maa gbòòrò arisiki rẹ ni ayé ṣùgbọ́n ti o maa ri ifunpinpin ni alukiyaamọ, o si n bẹ ninu wọn ẹni ti Ọlọhun ko nii gbòòrò arisiki fun ni ayé, ṣùgbọ́n o maa ri igbalaaye ni alukiyaamọ, o tun bẹ ninu wọn ẹni ti Ọlọhun ko nii gbòòrò arisiki fun ni ayé ati alukiyaamọ, o si n bẹ ninu wọn ẹni ti Ọlọhun maa gbòòrò arisiki rẹ ni ayé ati alukiyaamọ”.
Ahmad ni o gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe iran mẹfa ni àwọn iṣẹ, iran mẹ́rin si ni àwọn èèyàn. Àwọn iṣẹ́ mẹfẹẹfa naa ni: Akọkọ: Ẹni tí ó bá ku ti ko da nnkan kan pọ mọ Ọlọhun, alujanna di dandan fun un. Ẹlẹẹkeji: Ẹni tí ó bá kú ti o si da nǹkan pọ mọ Ọlọhun, ina di dandan fún un, yoo si ṣe gbere ninu ẹ. Àwọn mejeeji ni nnkan meji ti wọn maa n sọ nǹkan di dandan. Ẹlẹẹkẹta: Daadaa ti a gbero, ẹni tí ó bá gbero lati ṣe dáadáa pẹ̀lú aniyan òdodo titi ti ọkan rẹ fi maa mọ ọn lara ti Ọlọhun naa si mọ àníyàn yii lati ọdọ rẹ, ki àlámọ̀rí kan waa sẹlẹ si i lẹ́yìn naa, ti ko waa ni ikapa lati ṣe daadaa yii, wọn maa kọ ẹsan ti o pe fun un. Ikẹrin: Aburu ti a ṣe, ẹni ti o ba ṣe aburu kan wọn maa kọ aburu kan fun un. Àwọn mejeeji ni: Iru kan pẹlu iru kan laini adipele. Ikarun-un: Daadaa ti o maa jẹ pẹlu daadaa mẹwaa iru rẹ, oun ni ẹni ti o gbero daadaa ti o si ṣe é; wọn maa kọ daadaa mẹwaa fun un. Ikẹfa: Daadaa ti o maa jẹ pẹlu ẹẹdẹgbẹrin ẹsan, oun ni ẹni ti o ba na owó kan si oju ọna Ọlọhun, wọn maa kọ daadaa yii fun un pẹlu ẹẹdẹgbẹrin daadaa, eleyii wa ninu ọlá Rẹ- ìbùkún ni fun Un ti ọla Rẹ ga- ati ọrẹ Rẹ lori awọn ẹru Rẹ. Ṣugbọn àwọn iran awọn eniyan mẹrẹẹrin ni: Akọkọ: Ẹni ti wọn maa gba laaye ni aye ninu arisiki, wọn maa dẹ ẹ lara nibẹ pẹlu nnkan ti o ba fẹ, sugbọn wọn maa fun pinpin mọ ọn ni ọrun ti ìkángun rẹ si maa jẹ ina, oun ni alaigbagbọ ọlọrọ. Ikeji: Ẹni ti wọn maa fun pinpin mọ ọn ni aye ninu arisiki, sugbọn wọn maa gba a laaye ni ọrun, ti ìkángun rẹ si maa jẹ alujanna, oun ni olugbagbọ alaini. Ikẹta: Ẹni ti wọn maa fun pinpin mọ ọn ni aye ati ọrun, oun ni alaigbagbọ alaini. Ikẹrin: Ẹni ti wọn maa gba a laaye ni aye ati ọrun, oun ni olugbagbọ ọlọrọ.
Lati ọdọ Ibnu Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojisẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dajudaju Ọlọhun maa n fẹ́ lati mu awọn ofin idẹkun Rẹ wa, gẹgẹ bi O ṣe nífẹ̀ẹ́ lati mu awọn eyi ti o jẹ dandan wa”.
Ibnu Hibbaan ni o gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: Dajudaju Ọlọhun maa n nífẹ̀ẹ́ sí mímú awọn ofin idẹkun Rẹ ti O ṣe wọn lofin wa, ninu awọn nnkan ti O ṣe wọn ni fifuyẹ nibi awọn idajọ ati ijọsin, ati ṣíṣe irọrun nibẹ fun awọn ẹni ti a la iwọ Ọlọhun bọ lọrun fun idi kan- gẹgẹ bii dindin irun ku ati dida a pọ ni ori irin ajo-, Gẹgẹ bi O ṣe nífẹ̀ẹ́ si mimu awọn ofin ti wọn jẹ dandan wa, ninu awọn alamọri ti wọn jẹ dandan; nitori pe aṣẹ Ọlọhun nibi awọn ìdẹkùn ati awọn nnkan ti wọn jẹ dandan jẹ ọ̀kan.
Lati ọdọ ‘Amru ọmọ ‘Aamir lati ọdọ Anas ọmọ Mālik o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun, mo wa sọ pe: Bawo ni ẹyin ṣe maa n ṣe? O sọ pe: Aluwala ẹyọkan maa n to fun ẹnikẹni ninu wa lopin igba ti ko ba ti dá ẹgbin.
Bukhaariy gba a waAnabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun ọranyan koda ki aluwala rẹ o ma bajẹ; iyẹn ni lati fi gba ẹsan ati ọla. O si tun lẹtọọ ki o ki ju irun ọranyan ẹyọkan lọ pẹlu aluwala ẹyọkan lopin igba ti o ba ṣi ni aluwala.
Lati ọdọ ọmọ Abbās – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji – o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe aluwala ni ẹyọkọọkan.
Bukhaariy gba a waAnabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti o ṣe pe ni awọn igba miran ti o ba ṣe aluwala yio fọ oríkèé kọọkan ninu awọn oríkèé ara rẹ ni ẹẹkan, ti yio fọ oju – ninu rẹ ni yiyọ ẹnu ati fifin imu -, ati ọwọ mejeeji ati ẹsẹ mejeeji ni ẹẹkan, ati pe eleyii ni odiwọn ti o jẹ dandan.