





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ baba Ruqọyyah Tameem ọmọ Aosi Addariyy kí Ọlọhun yọnu sí dájú dájú anọbi kí Ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ má bà sọ pé: “Ẹsin ìmọ̀ràn ni”, a sọ pé: Fún tani? O sọ pe: “Fún Ọlọhun, ati fun tira Rẹ̀, ati fun ojiṣẹ Rẹ, ati fun awọn aṣiwaju Mùsùlùmí ati apapọ wọn”.
Muslim gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹsin duro lori imọkanga ati ododo, titi ti eeyan fi maa pé e gẹ́gẹ́ bi Ọlọhun ṣe ṣe e ni dandan, ni pípé láìsí ikudiẹ-kaato nibẹ tabi irẹjẹ. Wọn wa sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Ìmọ̀ràn fun tani? O sọ pe: Akọkọ: mímọ fun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga: Pẹ̀lú mimọ iṣẹ kangá fun Un, ati ki èèyàn ma da orogun pọ̀ mọ́ Ọn, ki a si gbagbọ ninu ijẹ Oluwa Rẹ, ati ìní-ẹ̀tọ́ si ìjọsìn Rẹ, ati awọn orúkọ Rẹ ati awọn ìròyìn Rẹ, ati gbigbe ọ̀rọ̀ Rẹ tobi, ati ipepe lọ sibi ìní ìgbàgbọ́ si I. Ẹkeji: Ṣíṣe mimọ sí ọrọ rẹ òun náà ni Al-qur'aani alapọnle: pẹlu pé kí a ní adisọkan pé ọrọ ọrọ rẹ ni , àti pe oun ni igbẹyin awan tira rẹ, àti pe oun ni o se iparẹ gbgbo awan ìlànà òfin tí o tí wa síwájú re6, kí o sí máa gbé tóbi, kí o sí máa kàà bode yẹ koro ka , kí o sí máa lo èyí tí ìdájọ rẹ fojú hàn, kí o sí gbafa fún èyí tí o jọra wàn tàbí èyí tí o ru'ju nínú rẹ, kí a sí jìnà sí ituku awan tí wan tú ni itukutu, kí a sí máa ni iwoye sí awan ìkìlọ tàbí isiti rẹ, kí a sí má tán awan imọ rẹ ka , kí a sí pepe sí ará rẹ. Ìkẹta: Ìmọ̀ràn fun ojiṣẹ Rẹ tii ṣe Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-: Pẹ̀lú ki a ni adisọkan pe oun ni igbẹyin àwọn ojiṣẹ, ki a si gba a lododo nibi nǹkan ti o mu wa, ki a si tẹle àṣẹ rẹ, ki a si jinna si ohun ti o bá kọ̀. Ki a si ma jọ́sìn fun Ọlọhun àyàfi pẹ̀lú nǹkan ti o mu wa, ki a si maa gbe iwọ̀ rẹ tobi, ki a si maa pọn ọn le, ki a si maa tan ipepe rẹ ká, ki a si maa fọn ofin rẹ ka, ki a si maa tako àwọn ẹ̀sùn ti wọn ba fi kan an. Ikẹrin: Ìmọ̀ràn fun awọn aṣiwaju àwọn mùsùlùmí: Pẹ̀lú riran wọn lọ́wọ́ lórí òdodo, ki eeyan ma si du àlámọ̀rí naa mọ́ wọn lọ́wọ́, ki èèyàn si maa tẹti ki èèyàn si maa tẹle àṣẹ wọn nibi itẹle ti Ọlọhun. Ikarun-un: Ìmọ̀ràn fun awọn Mùsùlùmí: Pẹ̀lú ṣíṣe dáadáa si wọn ati pípè wọn, ati ki èèyàn má fi suta kan wọn, ati inifẹẹ oore fun wọn, ati kikun wọn lọ́wọ́ lori dáadáa ati ìpayà.
Lati ọdọ ‘Ubaadatu ọmọ As-Soomit- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: A ṣadehun fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori gbigbọ ati itẹle nigba ilekoko ati irọrun, ati nibi nnkan ti a fẹ ati nnkan ti a kọ, ati lori iwa imọtaraẹni nikan, ati pe lori pe a ko gbọdọ fa alamọri mọ awọn ti wọn ni in lọwọ, ati lori pe ki a maa sọrọ pẹlu ododo ni ayekaye ti a ba wa, a ko nii bẹru eebu buni buni kan ni oju ọna Ọlọhun.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gba adehun ati majẹmu lọwọ awọn sahaabe nibi itẹle fun awọn olori ati awọn adari nigba idẹkun ati ilekoko ati nigba ọrọ ati oṣi, boya awọn aṣẹ wọn wa latara nnkan ti ẹ̀mí fẹ tabi ti o kọ, koda ti awọn adari ba ṣe imọtaraẹni nikan pẹlu owo gbogboogbo tabi awọn ipo tabi nnkan ti o yatọ si wọn, dajudaju gbigbọ ati itẹle jẹ dandan fun wọn pẹlu daadaa, ati pe wọn ko gbọdọ jade le wọn lori nitori pe wahala ati ibajẹ ti o n bẹ nibi biba wọn ja tobi o si le koko ju ibajẹ ti o n waye pẹlu ṣíṣe abosi wọn lọ, ati pe ninu nnkan ti wọn ṣadehun rẹ fun un ni ki wọn maa sọ ododo ni ayekaye ti wọn wa ti wọn n ṣe imọkanga nibi ìyẹn fun Ọlọhun ti wọn ko si nii maa bẹru ẹni ti o ba n bu wọn.
Lati ọdọ Umu salamah iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Awọn adari kan maa jẹ, ẹ maa mọ ẹ si maa ṣe atako, ẹni ti o ba mọ, o ti bọ, ẹni ti o ba ṣe atako, o ti la, sugbọn ẹni ti o ba yọnu ti o si tẹle" wọn sọ pe: Njẹ a ko nii ba wọn ja? O sọ pe: "Rara, lópin ìgbà tí wọ́n ba ṣi n kirun".
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe awọn olori kan maa jẹ lé wa lori, a maa mọ awọn kan ninu awọn iṣẹ wọn; nitori pe wọn ba nnkan ti wọn mọ ninu Sharia mu, a si maa tako awọn kan ninu wọn; nitori wọn yapa ìyẹn, Ẹni ti o ba korira ibajẹ pẹlu ọkan rẹ, ti ko kapa lori atako; o ti bọ kuro ninu ẹṣẹ ati ṣọbẹ-selu, Ẹni ti o ba kapa lori atako pẹlu ọwọ tabi ahọn, ti o wa tako ìyẹn fun wọn o ti la kuro nibi ẹṣẹ ati kikopa nibẹ, Ṣugbọn ẹni ti o ba yọnu si iṣe wọn ti o si tẹle wọn lori rẹ, o maa parun gẹgẹ bi wọn ṣe parun. Lẹyin naa wọn bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pe: Njẹ a ko nii ba awọn adari ti wọn ṣe pe eyi ni iroyin wọn ja? O wa kọ fun wọn kuro nibẹ, o wa sọ pe: Rara, lópin ìgbà tí wọ́n ba ṣi n gbé ìrun duro láàárín yin.
Lati ọdọ Abu Musa Al-ash’ari - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Tí ẹrú Ọlọhun kan bá ṣàìsàn tabi ó rin irin-ajo, wọn yoo kọ laada silẹ fun un fún iṣẹ tí n ṣe nigba tí ó wà nílé tó sì lalaafia".
Bukhaariy gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọrọ nipa oore-ọfẹ Ọlọhun ati ikẹ Rẹ̀ lori musulumi, tí ó fi jẹ́ pé tí ó bá wà ninu àṣà musulumi pé ó máa ń ṣiṣẹ́ rere kan ní ẹni tó ní alaafia, tí kò sì rinrin ajo, musulumi naa wáá ní awawi kan latara pé ó ṣaisan, kò wá lè ṣe iṣẹ rere naa, tabi pé ó ṣairoju pẹlu irin-ajo, tabi èyíkéyìí ninu awọn awawi; dajudaju wọn maa kọ laada iṣẹ rere naa silẹ fun un ní pípé, bí ẹni pé ó ṣiṣẹ naa ni awọn asiko tó ni alaafia, tí kò sì wà ní irin-ajo.
Lati ọdọ Tamiim Ad-Daariy- ki Ọlọhun yọnu si i- pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Ẹsin ìmọ̀ràn ni”, a sọ pé: Fún tani? O sọ pe: “Fún Ọlọhun, ati fun tira Rẹ̀, ati fun ojiṣẹ Rẹ, ati fun awọn aṣiwaju Mùsùlùmí ati apapọ wọn”.
Muslim gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹsin duro lori imọkanga ati ododo, titi ti eeyan fi maa pé e gẹ́gẹ́ bi Ọlọhun ṣe ṣe e ni dandan, ni pípé láìsí ikudiẹ-kaato nibẹ tabi irẹjẹ. Wọn wa sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Ìmọ̀ràn fun tani? O sọ pe: Akọkọ: Ìmọ̀ràn fun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga: Pẹ̀lú mimọ iṣẹ kangá fun Un, ati ki èèyàn ma da orogun pọ̀ mọ́ Ọn, ki a si gbagbọ ninu ijẹ Oluwa Rẹ, ati ìní-ẹ̀tọ́ si ìjọsìn Rẹ, ati awọn orúkọ Rẹ ati awọn ìròyìn Rẹ, ati gbigbe ọ̀rọ̀ Rẹ tobi, ati ipepe lọ sibi ìní ìgbàgbọ́ si I. Ìkejì: Ìmọ̀ràn fun tira Rẹ tii ṣe Kuraani Alapọn-ọnle: Pẹlu pe ki a ni adisọkan pe ọrọ Rẹ ni, oun si ni tira Rẹ ti o kẹyin, o si ti pa gbogbo àwọn ofin ti o ṣíwájú rẹ̀ rẹ́, a maa gbe e tobi, a si maa ka a bi o ṣe tọ́. A maa lo eyi ti ko ba rújú nínú ẹ, a si maa yọnu si èyí ti o ba rújú ninu ẹ, a si maa le àwọn èèyàn kuro nibi itukutuu àwọn ti n yi itumọ rẹ padà, a si maa woye si awọn wàásù rẹ, a si maa tan imọ rẹ ka, a si maa pepe si i. Ìkẹta: Ìmọ̀ràn fun ojiṣẹ Rẹ tii ṣe Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-: Pẹ̀lú ki a ni adisọkan pe oun ni igbẹyin àwọn ojiṣẹ, ki a si gba a lododo nibi nǹkan ti o mu wa, ki a si tẹle àṣẹ rẹ, ki a si jinna si ohun ti o bá kọ̀. Ki a si ma jọ́sìn fun Ọlọhun àyàfi pẹ̀lú nǹkan ti o mu wa, ki a si maa gbe iwọ̀ rẹ tobi, ki a si maa pọn ọn le, ki a si maa tan ipepe rẹ ká, ki a si maa fọn ofin rẹ ka, ki a si maa tako àwọn ẹ̀sùn ti wọn ba fi kan an. Ikẹrin: Ìmọ̀ràn fun awọn aṣiwaju àwọn mùsùlùmí: Pẹ̀lú riran wọn lọ́wọ́ lórí òdodo, ki eeyan ma si du àlámọ̀rí naa mọ́ wọn lọ́wọ́, ki èèyàn si maa tẹti ki èèyàn si maa tẹle àṣẹ wọn nibi itẹle ti Ọlọhun. Ikarun-un: Ìmọ̀ràn fun awọn Mùsùlùmí: Pẹ̀lú ṣíṣe dáadáa si wọn ati pípè wọn, ati ki èèyàn má fi suta kan wọn, ati inifẹẹ oore fun wọn, ati kikun wọn lọ́wọ́ lori dáadáa ati ìpayà.
Lati ọdọ Aisha- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ lẹ́nu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ ninu ilé mi yii pe: “Ìwọ Ọlọhun, ẹnikẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ijọ mi, ti o wa fi ara ni wọn, ki O fi ara ni in, ẹnikẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ijọ mi, ti o wa ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú wọn, ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú oun naa”.
Muslim gba a waÒjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣẹ èpè lé gbogbo ẹni tí ó bá jẹ alaṣẹ lori àlámọ̀rí kan fun awọn Mùsùlùmí, bóyá o kéré ni tabi o tóbi, bóyá ti gbogbogboo ni tabi fun apá ibikan sọ́, tí o wa fi ara ni wọn ti ko ṣàánú wọn, pe Ọlọhun ti ọla Rẹ ga maa san an lẹsan latara irú iṣẹ rẹ pẹlu pe ki o fi ara ni oun náà. Ẹni tí ó bá wa ṣàánú wọn ti o si ṣe àlámọ̀rí wọn ni irọrun, pe ki Ọlọhun ṣàánú tiẹ̀ naa ki O si ṣe àlámọ̀rí rẹ ni irọrun.
Láti ọ̀dọ̀ Mah’qil ọmọ Yasaar Al-Muzaniy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Ko si ẹrú kan ti Ọlọhun fi ṣe alaṣẹ lori awọn kan, ki o wa kú ni ọjọ́ ti o maa kú ti o si n tan àwọn ti wọn wa ni abẹ rẹ jẹ, àfi ki Ọlọhun ṣe alujanna ni eewọ fun un”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹni kọọkan ti Ọlọhun ba fi ṣe olori fun awọn èèyàn, boya o jẹ àṣẹ ti gbogbogboo ni gẹgẹ bii alaṣẹ ìlú, tàbí àṣẹ ti kii ṣe ti gbogbogboo, gẹgẹ bii ọkùnrin ninu ile rẹ, ati obinrin ninu ile rẹ, ti o wa ṣe ohun ti o kù díẹ̀ káàtó nibi ẹ̀tọ́ àwọn ti n bẹ ni abẹ rẹ, o tun rẹ́ wọn jẹ, ko si gba wọn ni imọran, o wa fi iwọ̀ wọn ti ẹsin ati ayé ráre, o ti ni ẹ̀tọ́ si ìjìyà ti o le koko yìí.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹni ti o ba jade kuro ninu itẹle, ti o wa fi janmọọn sílẹ̀, ti o wa ku, o ku ni iku ti asiko aimọkan, ẹni ti o ba ja ni abẹ àsìá kan ti o fọ́jú, ti o n binu nitori ẹlẹyamẹya, tabi o n pepe lọ sibi ẹlẹyamẹya, tabi o n ran ẹlẹyamẹya ṣe, wọn wa pa a, o jẹ pipa kan ti o jẹ ti asiko aimọkan, ẹni ti o ba jade si ijọ mi, ti o n pa ẹni rere rẹ ati ẹni buburu rẹ, ti ko bikita pipa olugbagbọ rẹ, ti ko pe adehun rẹ fun aladehun, ko si ninu ijọ mi, emi naa ko si ninu ijọ rẹ”.
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba jade kuro ninu itẹle awọn adari, ti o tu ijọ Isilaamu ti o fẹnu ko lori ṣiṣe adehun fun olori, o wa ku lori isẹsi yẹn ninu ituka ati aitẹle, o maa ku ni iku awọn asiko aimọkan, awọn ti wọn ko ki n tẹle adari ti wọn ko ki n darapọ mọ ijọ kan, bi ko ṣe pe awọn ijọ ni wọn ati awọn ẹlẹyamẹya ti awọn kan maa n ba awọn kan ja ninu wọn. Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe ẹni ti o ba ja lábẹ́ àsìá kan ti oju ododo ko han yatọ si ibajẹ nibẹ, ti o n binu nitori ẹlẹyamẹya lasan fun ìjọ rẹ tabi idile rẹ, ti ko ki n ṣe tori riran ẹsin ati ododo ṣe, ti o wa n ja ni ti ẹlẹyamẹya laini amọdaju ati imọ, ti wọn ba pa a lori isẹsi yẹn, o da gẹgẹ bii pipa ti asiko aimọkan ni. Ati pe dajudaju ẹni ti o ba jade si ijọ rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o pa ẹni rere rẹ ati ẹni buburu rẹ, ti ko bikita pẹlu nnkan ti o n ṣe ti ko si bẹru ijiya rẹ ninu pipa olugbagbọ rẹ, ti ko si pe adehun wọn fun awọn aladehun ninu awọn alaigbagbọ tabi awọn adari bi ko ṣe pe o n tu u ni, eleyii wa ninu ẹṣẹ ńláńlá, ati pe ẹni ti o ba ṣe e dajudaju o ti lẹtọọ si adehun iya ti o le koko yìí.
Lati ọdọ ‘Arfaja – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe: «Ẹni ti o ba wa ba yin nigba ti ọrọ yin papọ lori arakunrin kan, ti o wa n gbero láti ya yin, tabi lati pin akojọpọ yin, ki ẹ yaa pa a».
Muslim gba a waAnabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n ṣe alaye wipe dajudaju ti awọn Musulumi ba kojọ lori olori kan, ati akojọpọ kan, lẹyin naa ni ẹni ti o fẹ ba a du ipo aṣẹ wa de, tabi ti o gbero lati pin awọn Musulumi si ijọ ti o pọ ju ẹyọkan lọ, o jẹ dandan fun wọn lati kọ fun un ati lati ba a ja; lati fi ti aburu rẹ danu ati lati fi da aabo bo ẹjẹ awọn Musulumi.