





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n rin loju ọna Makkah, ni o ba kọjá nibi oke kan ti wọn n pe e ni Jumdaan, o sọ pe: "Ẹ maa rin lọ, Jumdaan nìyí, àwọn MUFARRIDUUN ti ṣíwájú" wọn sọ pe: Awọn wo ni MUFARRIDUUN irẹ ojiṣẹ Ọlọhun? O sọ pe: Awọn ni àwọn oluranti Ọlọhun lọkunrin lọpọlọpọ ati awọn oluranti Ọlọhun lobinrin".
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé ipo awọn oluranti Ọlọhun lọpọlọpọ, pe wọn ti dá wà wọ́n si ti ṣáájú àwọn ti wọn yàtọ̀ si wọn pẹlu pe ọwọ wọn tẹ awọn ipo ti o ga julọ ninu alujanna onidẹra, o wa fi wọn we oke Jumdaan ti o da wa laarin awọn oke yókù.
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe: «Gbogbo ijọ mi ni wọn maa ṣọ kuro nibi aburu ayaafi awọn alaṣehan, ati pe dajudaju ninu aṣehan ni ki ọmọnìyàn o ṣe iṣẹ kan ni oru, lẹyin naa ki o wa ji ti Ọlọhun si ti bo aṣiri rẹ, ki o wa sọ pe: Irẹ lagbaja, mo ṣe nkan bayii bayii ni alẹ ana, ti Ọlọhun si ti bo aṣiri rẹ ni alẹ, yio waa ji lati ṣi gaga aṣiri bibo Ọlọhun kuro».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju Musulumi ẹlẹṣẹ ni o ṣeeṣe ki o ri amojukuro Ọlọhun ati aforijin Rẹ, ayaafi ẹni ti o ba n fi ẹṣẹ han ní ti ṣiṣe faari ati jijẹ aṣa, oun o lẹtọọ si amojukuro; latari pe yio da ẹṣẹ ni oru, lẹyin naa yio ji ni ẹni ti Ọlọhun ti bo aṣiri rẹ, ni yio ba sọ fun ẹlòmíràn pe oun da ẹṣẹ bayii ni ana, ti o si sun ti Oluwa rẹ ti bo o ni aṣiri, ni yio ba ji ti yoo waa tu aṣiri bibo Ọlọhun lori rẹ.
Lati ọdọ Jaabir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé: mo gbọ tí Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - sọ ni ọdun mẹta síwaju koto fi ayé silẹ báyi pé: "Ẹnikan ninu yin ko gbọ ku ayaafi ki o ni àbá daada si Ọlọhun".
Muslim gba a waAnọbi (kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) gba musulumi níyànjú lati má kùú ayaafi ki o ni àbá daada si Ọlọhun pẹlu ki o fi abala inireti sọdọ Ọlọhun leke nígbàtí nba pọka iku lọwọ n'ireti pe Ọlọhun Yóò ṣekẹ rẹ yóò ṣe amojukuro fún un; nitoripe ifoya ni nkan ti wọn beere fún ki a le ri iṣẹ se daada, ìṣesí un kii se iṣesí iṣẹ ṣiṣe, nkan ti wọn fẹ nibẹ ni ki ireti borí.
Láti ọdọ Abu Hurayrah kí Ọlọhun yọnu si: Dájúdájú arakunrin kan sọ pé: irẹ ojisẹ Ọlọhun mo ni awọn ẹni tí mo nso okun ẹbi wọn pọ ti awọn si nja kuro lọdọ mi, mo nṣe daada si wọn bẹẹ ni wọn se àìda si mi, mo nṣe suuru pẹlu wọn bẹẹ ni wọn wù iwa aimọkan pẹlu mi, Anọbi sọ pé: "tó bá ṣe pé bí o se wà lo sọ yii, bi ẹni pe ìwà wọn ti su ọ bayii, ikun lọwọ Ọlọhun konii ye konii gbo fun ọ lori wọn lópin igbati o ba ti wà bẹẹ".
Muslim gba a waArákùnrin kan lọ fẹjọ sùn Anọbi (kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a) pe oun ni ẹbi ati ibipọ ti oun nba wọn ṣe pọ pẹlu daada bẹẹ ni awọn nba lo pẹlu àìda; oun aa máa so wọn pọ bẹẹ ni awọn nja kúrò ní ara oun, oun aa máa se daada sí wọn pẹlu rere ati ise ojúṣe bẹẹ awọn aa maa se àìda sí oun pẹlu abosi àti ìwà omugọ, òun aa máa ni suuru pẹlu wọn aa sì maa se amojukuro fun wọn, bẹẹ ni wọn a maa wu iwa aimọkan sí oun pẹlu ọrọ ẹnu ati iṣẹ ti koda, nje ki oun tún tẹsiwaju lati máa so okun ẹbi pọ pẹlu nkan ti oun sọ yii? ni Anọbi (kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) wa sọ fún un pa: ti o ba se pé bí ọrọ seri ni o sọ yi dájúdájú o ti ko iyẹpẹrẹ bá wọn, o si ti jẹ kí wọn rí ra wọn ni ẹni abuku, bi ẹni pé o nfun wọn ni eérú gbóná jẹ ni; nítorí daada rẹ tó pọ tí o nṣe fún wọn àti aburú ti wọn nṣe fun ara wọn, iranlọwọ láti ọdọ Ọlọhun wa ti yóò máa kún ọ lọwọ lórí wọn konii yẹ konii gbo pẹlu rẹ, ti yóò si máa daabo bo ọ níbi suta (aburu) wọn lópin ìgbà tí o bá wà lórí ise daada rẹ sí wọn tí awọn náà wà lórí ise àìda sí ọ.
Lati ọdọ Abu Hurayrah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a) sọ pe: "Kòsí ijọkan ti wọn yóò dide láti ibi jokolẹ kan láì dárúkọ Ọlọhun níbẹ ayaafi ki wọn didi bi àpèjúwe okunbete Kẹtẹkẹtẹ, bẹẹ ni yóò tún jẹ ìbànújẹ́ fún wọn.
Abu Daud ni o gba a waAnọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) fún wa niro pe kò ní sí awọn apapọ eniyan kan tí wọn joko sí ààyè ijoko kan ti wọn wa dìde láì dárúkọ Ọlọhun nibẹ àyàafi ki wọn dide gẹgẹ bí àwọn ti wọn ko jọ lórí òku kẹtẹkẹtẹ ni ori akitan ati aye oorùn; eleyi ri bẹ nítorípé wọn ṣe airoju kuro nibi ìrántí Ọlọhun, ijoko naa yoo jẹ ìbànújẹ́ fun wọn lọjọ igbende, yoo si jẹ abuku ati àbámọ ti yóò maa wà pẹlu wọn.
Láti ọdọ baba Musa - kí Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé: Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) sọ pe: "Àpèjúwe ẹniti nrántí Olúwa rẹ ati ẹnití kò rántí Olúwa rẹ da gege bi alààyè ati òkú ni ", gbólóhùn ti Muslim ni" Àpèjúwe ile ti wọn ti nranti Ọlọhun, ati ile ti wọn kò rántí Ọlọhun níbẹ o da gẹgẹ bí alaayè ati òkú ".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi ki ikẹ Ọlọhun ati ọlá Rẹ má bà nsalaye iyatọ to wa láàrin ẹni ti nranti Ọlọhun ti o ga jù ati ẹni tí kò rántí Rẹ, ati pé gẹgẹ bí iyatọ tó wà láàrin àlàyé ati òkú ni bi iwulo rẹ ati didara irisi rẹ, àpèjúwe ẹni ti nranti Olùwà rẹ ọ da gẹgẹ bí aláayè ti ìta rẹ gbé ẹṣọ jáde pẹlu imọlẹ iseni , ati inú rẹ pẹlu imọlẹ ìmọ, ìwúlò n'bẹ lára rẹ, àpèjúwe ẹni tí kò rántí Ọlọhun o da gẹgẹ bí òkú ti ìta rẹ ti da ṣẹlẹ ti inú rẹ sí ti bajẹ, bẹẹ ni kòsí ìwúlò kan kan lára rẹ mọn. Bẹẹ náà ni ilé wan royin rẹ pẹlu isemi (aláayè) ti awan olùgbé rẹ bá nranti Ọlọhun, ti wan ba rántí Ọlọhun a jẹ pé òkú ni ile náà kúrò níbi ìrántí Ọlọhun, ti wan ba lo aláayè ati òkú lati fí royin ile ẹni ti o gbe bẹ ni wan fi ọrọ bawo.
Láti ọdọ bàbá Sa'eed Al-Khudriy ki Ọlọhun yọnu si: Dájúdájú Anọbi (kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) o joko ni ọjọ kan lórí minbari ti awa si joko ní ẹgbẹ rẹ, ló bá sọ pé: "dájúdájú ninu nkan ti emi nbẹru fún nípa yin ti mo bá lọ tán ni yodoyindin aye àti ọsọ rẹ ti wọn yóò si fún yín" ni arákùnrin kan bá sọ pé: mope irẹ Ojisẹ Ọlọhun: ṣe oore le tun mu aburú wa ni? Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) bá dakẹ kò sọrọ, ni wọn bá sọ fún arákùnrin náà pé: kí ló ṣe ọ? o nba Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) sọrọ kò si bá ọ sọrọ? la bá ri pé Qur'an nsọkalẹ fún Anọbi lọwọ ni? ó sọ pé: ni o ba nnu oogun kúrò ní ara rẹ, ni o ba sọ pé: "nibo ni onibeerè náà wà? "bi ẹni pé o yin-in, lo bá wa sọ fun pe: "kii ṣe pé oore a máa mú aburú wa, dájúdájú irúgbìn iṣẹ palẹ ojo o le pa ẹranko tí ó jẹ tàbí kó fẹẹ pa á ayaafí tí eranko náà bá jẹ nibẹ, ti o si ri pé inú ti kun kẹkẹ ti o fi ewéko náà silẹ o lọ yeerun osi náà tọtọ, o tọ o yagbẹ o tun fi ẹnu jẹ koríko lọ, dájúdájú owo tabi dukia yi ni ewéko tútù to dùn, mandala eyi ti yóò mọ bẹ pẹlu musulumi nínú èyí tí o ná fún alaini ọmọ orukan àti onírin àjò - tabi gẹgẹ bí Anọbi ṣe sọ - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - eni tó bá gba dukia náà láì ṣe ọna ẹtọ o da bí ẹni tí njẹ un ti ko yo ni, yóò sì jẹ ibalẹjọ fun ni ọjọ igbende.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi - kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - joko lẹ ori minbari ni ọjọ kan ti mbá awọn ọmọ lẹyìn rẹ sọrọ, o si ṣọ pe: dájúdájú eyí ti o pọ ti mo nbẹru tí mo sì npáya fún nípa yin lẹyin mi ni ohun tí wọn yóò ṣi silẹ fún yin nínú àwọn ìbùkún ilẹ ati aye ati ọsọ rẹ àti ẹwà rẹ ati awọn orisirisi igbadun ati aṣọ ati awọn irúgbìn àti awọn nkan míran ti awọn eniyan ma fi nse iyanran àti akọ to un ti pé isẹku rẹ kéré. Ni arákùnrin kan bá sọ pé: ọsọ aye idẹra lo jẹ láti ọdọ Ọlọhun, se idẹra yi yoo tun pada di iya ati ìbáwí ni bi?! ni awọn eniyan ba bu onibeere naa nigbati wọn ri pe Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Re máa ba a) dakẹ ti kò sọrọ, wọn ro pé oti mu Anọbi binu ni. O padà wá hàn pé dájúdájú Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ngba waayi kuraani lọ wọ (Kuraani nsọ kalẹ fun) o wa bẹrẹ síní nu oogun ojú rẹ kúrò, o wa sọ pé: onibeere náà dà? O sọ pé: emi ni. Anọbi dupẹ fún Ọlọhun o si fi iyin fun, leyin náà ni o sọ pé: oore gangan koni mu nkan wa ju oore lọ, ṣugbọn nkan yindin won yi kii se oore pọnbele nítorí awọn wahala ati ifiga gbága lórí rẹ ati igbaju mọ ti kii jẹ ki a le gbaju mọ ọrun ni pípé, lẹyin naa ni o wa se àpèjúwe rẹ, o sọ pé: dájúdájú irúgbìn iṣẹ palẹ ojo ati titutu rẹ; òhun ni iru irúgbìn kan ti aa ma wu ewurẹ tabi àgùntàn lati jẹ ẹ, ti o bá jẹ pẹlu parahan ati wọbia yóò pa tabi ko fẹ pa a, ayaafi ẹran ti o jẹ ewé tutu yi ti ẹgbẹ kan inu rẹ bá ti kun yóò fi yoku silẹ, leyin náà yóò kọjú sí òòrùn lati sinmi, yóò jagbẹ yóò tó bẹẹ ni yóò gbé awon eyi to kù ni enu rẹ mi, lẹyìn naa yóò tún padà sí bẹ lati jẹ. dájúdájú dukiya yi bi ewéko to tutù daada ni ti o si dùn, ọpọ rẹ le pani tabi ki o fẹẹ pani; ayaafi ti o ba jẹ diẹ ti o ni bukaata si ti yóò sì tó ní ọna ẹtọ, irú bẹ ko nii mu ìnira lọwọ, idẹra musulumi ohun ni ẹnití o bá aláìní ati ọmọ orukan ati onírinàjò ninu rẹ, ẹnití o bá gbà pẹlu ẹtọ rẹ wọn yóò fi ibukún si fun, ẹni tí o bá gba a láì ṣe pẹlu ẹtọ rẹ àpèjúwe rẹ o dà gẹgẹ bi ẹnití njẹ un tiko yó, yóò padà jẹ ibalẹjo fún un ni ọjọ igbende.
Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ṣo pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹni ti o n gun nkan ni o maa salamọ si ẹni ti o n rin, ẹni ti o n rin ni o máa salamọ si ẹni ti o jokoo, awọn ti onka wọn kere ni wọ́n maa salamọ si awọn ti onka wọn pọ». Ati pe ninu Al-bukhari: «Ọmọde maa salamọ si agbalagba, ẹni ti o n rekọja maa salamọ si ẹni ti o jokoo, awọn ti wọn kere maa salamọ si awọn ti wọn pọ».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe itọsọna lọ sibi ẹkọ sisalamọ laarin awọn eeyan "As salaamu alaykum wa rahmotuLloohi wabarakātuHu". Ọmọde o wa salamọ si agbalagba, ẹni ti o n gun nkan o si salamọ si ẹni ti o n rin, ẹni ti o n rin o salamọ si ẹni ti o jokoo, awọn ti onka wọn kere o salamọ si awọn ti onka wọn pọ.
Lati ọdọ An-nawwaas ọmọ Sim'aan al-ansaariy - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé: Mo beere lọwọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) nípa iṣẹ daada ati iwa ẹṣẹ, lo bá sọ pé: "daada ni iwa daada, ẹṣẹ ni nkan ti nlọ ti mbọ ninu igbaaya rẹ, ti kò sì wù ọ ki awọn eniyan mọn ".
Muslim gba a waWọ́n bi Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) nípa iṣẹ daada ati iwa ẹṣẹ, ni o ba daun pe: Èyí tó tóbi jù nínú iṣẹ daada ni iwa rere pẹlu Ọlọhun láti ara ìbẹrù Rẹ, ati pẹlu awọn ẹda pẹlu imaa gbé àìda mọra, ìbínú niwọnba, itujuka, ọrọ ti o da lẹnu, ida ẹbi pọ, itẹle aṣẹ Ọlọhun, iṣe pẹlẹ, iṣe daada, ibani lo lọna to da, àti ibarinpọ tó da. Ṣugbọn ẹṣẹ oun ni nkan ti nlọ ti mbọ ninu ìgbààyà nínú àwọn iruju ati seyi sòún ọkàn láì sí isipaya igbaaya fún un, ti iyemeji nipa rẹ ati ìbẹrù nípa pe se ẹsẹ ni tabi kii se ẹsẹ ti kosi fẹ lati se afihan pe aida ni si awọn ojulowo ati awọn ti wọn pe leniyan, nitoripe adamọ ni pé ẹmi fẹ lati jẹ ki awọn ènìyàn rí daada rẹ, ti kò bá fé kí awọn eniyan ri awọn apákan iṣẹ rẹ, a jasipe iṣẹ naa kosi oore níbẹ.