





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Abu Sa‘eed Al-Khuduriy - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ọkunrin o gbọdọ maa wo ihoho ọkunrin, obinrin naa o si gbọdọ maa wo ihoho obinrin, ọkunrin o si gbọdọ maa wa ni ihoho pẹlu ọkunrin ninu asọ kan, obinrin naa o si gbọdọ maa wa ni ihoho pẹlu obinrin ninu asọ kan».
Muslim gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ ki ọkunrin o maa wo ihoho ọkunrin, tabi ki obinrin o maa wo ihoho obinrin. Ati pe nkan ti n jẹ ‘Aorah ni: Gbogbo nkan ti wọn maa n tiju latara rẹ ti o ba hàn (nkan ti wọn o ki n fẹ ki o han), ati pe ihoho ọkunrin ni nkan ti o wa laarin idodo rẹ ati orunkun rẹ, Ati pe gbogbo ara obinrin pata ni ihoho fun awọn ọkunrin ajoji, ṣugbọn fun awọn obinrin ati awọn eleewọ rẹ, o le fi han nkan ti o saaba maa n han nigba ti o ba n ṣiṣẹ ni inu ile. Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tun kọ kuro nibi ki ọkùnrin ati ọkùnrin o wa ni ihoho ninu asọ kan tabi lábẹ́ aṣọ ibora kan, ati nibi ki obinrin ati obinrin o wa ni ihoho ninu aṣọ kan tabi lábẹ́ aṣọ ibora kan; nítorí pé ìyẹn le maa fa ki ọkọọkan ninu wọn o maa fi ọwọ pa ihoho ẹnìkejì rẹ, ati pe fifi ọwọ kan an (ihoho) nkan ti wọn kọ ni gẹgẹ bii wiwo o naa ni, koda kikọ rẹ (fifi ọwọ pa ihoho) tun le jù; latari pe ìyẹn le tini lọ sibi awọn ibajẹ ti o tobi.
Lati ọdọ Anas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Arakunrin kan wa sọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, mi ko fi ẹṣẹ kankan sílẹ̀ láì dá, o sọ pe: “Njẹ ṣe ko ki n ṣe pe o n jẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn tọ si òdodo afi Allahu ni, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni? Ni ẹẹmẹta. O sọ pe: bẹẹni, Anabi sọ pe Dajudaju ìyẹn maa pa àwọn ẹṣẹ yẹn rẹ.
Abu Yahlaa ati Tọbarọọniy ati Ad-Diyaau Al-Makdisiy ni wọn gba a waArakunrin kan wa sọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, dajudaju mo ti da gbogbo ẹṣẹ, ti mi ko fi ẹṣẹ kekere tabi ńlá kalẹ afi ki n ti ṣe e, njẹ wọn maa forí jin mi? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pé: Njẹ ṣe ko ki n ṣe pe o n jẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn tọ si ni ododo afi Allahu ni, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni? O paara rẹ ni ẹẹmẹta, O da a lohun pe: Bẹẹni mo n jẹrii, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ ọla ti o n bẹ fun ijẹrii mejeeji fun un ati pipa awọn aburu rẹ̀ rẹ́, ati pe ironupiwada maa n pa nnkan ti o ṣíwájú rẹ rẹ.
Láti ọ̀dọ̀ Jaabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹ ma kọ́ imọ lati le maa fi ba àwọn onimimọ ṣe iyanran, tabi lati le baa maa fi ja àwọn omugọ níyàn, ẹ si ma ṣẹsa lati wa ni iwájú ni àwọn àpéjọ pẹ̀lú ẹ, ẹni tí ó bá ṣe iyẹn, iná ni, iná ni”.
Ibnu Maajah ni o gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kilọ kúrò nibi wiwa imọ lati maa fi ba àwọn onimimọ ṣe iyanran, ati lati le fi hàn pé onimimọ bii tiyín ni èmi náà, tabi lati fi ba àwọn omugọ ati awọn ti làákàyè wọn lẹ sọ̀rọ̀ lati ba wọn jiyàn, tabi ki o kọ imọ lati wa ni iwájú ni àpéjọ, ti wọn si maa ti i saaju ẹlòmíràn nibẹ. Ẹni tí ó bá ṣe iyẹn; o ni ẹtọ si iná pẹlu ṣekarimi rẹ ati àìní imọkanga nibi wiwa imọ naa nítorí Ọlọhun.
Lati ọdọ An-Nawwaas ọmọ Sam’haan Al-Ansaariy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé: “Ọlọhun fi àkàwé kan lélẹ̀ nipa ojú ọ̀nà tààrà kan, ti ògiri méjì wa ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ojú ọ̀nà naa, ti àwọn ẹnu ọ̀nà ti wọn ṣí silẹ wa nibẹ, ti àwọn aṣọ ẹnu ọ̀nà ti wọn dà wálẹ̀ si n bẹ ni àwọn ẹnu ọ̀nà naa, olupepe kan n bẹ ni ẹnu ọ̀nà ojú ọ̀nà naa ti n sọ pé: Ẹ̀yin èèyàn, gbogbo yin ẹ ko sínú ọ̀nà naa, ẹ má ṣe wọ́, ati olupepe kan ti n pepe lati òkè ọ̀nà naa, ti o ba ti wa fẹ ṣí nǹkan kan ninu awọn ojú ọ̀nà yẹn, o maa sọ pé: Káì, ma ṣi i, ti o ba fi le ṣi i wàá wọ̀ ọ́, ojú ọ̀nà naa ni Isilaamu, àwọn ògiri méjèèjì naa ni: Awọn ààlà Ọlọhun, àwọn ẹnu ọ̀nà ti wọn ṣi silẹ ni: Awọn nǹkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ, ẹni tí n pepe ni orí ojú ọ̀nà naa ni: Tira Ọlọhun, ẹni tí n pepe ni òkè ojú ọ̀nà naa ni: Oníwàásù Ọlọhun ninu ọkàn gbogbo Musulumi”.
Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe: Ọlọhun fi àkàwé lélẹ̀ fun Isilaamu pẹlu ojú ọ̀nà tààrà ti o tẹ́ ti kò wọ́, tí ògiri méjì n bẹ ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ojú ọ̀nà naa ti wọn rọkirika rẹ, àwọn méjèèjì náà ni àwọn ààlà Ọlọhun, àwọn ẹnu ọ̀nà ti wọn ṣi silẹ n bẹ láàrin ògiri méjì yii, àwọn naa ni àwọn nǹkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ, àwọn aṣọ ẹnu ọ̀nà n bẹ ni àwọn ẹnu ọ̀nà naa ti ko nii jẹ ki ẹni tí n kọjá ri ẹni tí ó wà ninu rẹ, olupepe kan si n bẹ ni ìbẹ̀rẹ̀ ojú ọ̀nà naa ti n dari àwọn èèyàn ti o si n sọ fún wọn pé: Ẹ maa rìn lọ lori ẹ láì fi si etí ati ẹ̀gbẹ́, olupepe yii ni tira Ọlọhun, olupepe mìíràn tun wa ni òkè ọ̀nà naa; olupepe yii, gbogbo igba ti ẹni tí n rìn ni oju ọna naa ba ti fẹ ṣi aṣọ ẹnu ọ̀nà yẹn díẹ̀, o maa jagbe mọ́ ọn, o maa wa sọ fún un pé: Ó ṣe fún ẹ, o ò gbọdọ ṣí i! Ti o ba ṣi i, waa wọ inú ẹ, o ò si nii ni ikapa lati kọ̀ fun ara rẹ lati má wọlé, olupepe yii ni oníwàásù Ọlọhun ninu ọkan gbogbo Musulumi.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni nínú yín yóò fẹ́, nígbà tí ó bá padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, láti rí ràkúnmí aboyún mẹ́ta ti wọn tobi ti wọn sanra ni ọdọ wọn?” A sọ pé: Bẹ́ẹ̀ ni. Ó sọ pé: “Àwọn aaya mẹ́ta tí ọ̀kan nínú yín máa ń ka lori irun rẹ ni oore fun un ju ràkúnmí aboyún mẹ́ta ti wọn tobi ti wọn sanra lọ”.
Muslim gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ẹ̀san kika aaya mẹ́ta lori irun; o ni oore ju ki èèyàn o ri ràkúnmí aboyún mẹ́ta ti wọn tobi ti wọn sanra ni ilé rẹ lọ.
Láti ọ̀dọ̀ Uqbah ọmọ Aamir Al-Juhaniy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ba n ka Kuraani sókè da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe sàárà gbanngba, ẹni tí n ka Kuraani jẹ́ẹ́jẹ́ da gẹgẹ bii ẹni ti n ṣe saara kọ̀kọ̀”.
Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe ẹni ti ba n ka Kuraani sókè da gẹgẹ bii ẹni tí n kéde sàárà ṣíṣe, ẹni tí n ka Kuraani jẹ́ẹ́jẹ́ da gẹgẹ bii ẹni tí n fi sàárà pamọ.
Lati ọdọ ‘Aliyy o sọ pe: Dajudaju mo jẹ ọkunrin kan ti o ṣe pe ti mo ba ti gbọ ọrọ kan lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - Ọlọhun maa n fi nkan ti O ba fẹ ṣe mi ni anfaani pẹlu rẹ, ti ẹnikẹni ba wa sọrọ fun mi ninu awọn saabe rẹ (Anabi) maa ni ki o bura, ti o ba ti wa bura fun mi maa gba a gbọ, Abubakar wa sọrọ fun mi, ododo si ni Abubakar sọ, o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe: «Ko si ẹnìkankan ti yio da ẹṣẹ kan, lẹyin naa ni o wa dide ti o si ṣe imọra, lẹyin naa ni o wa kirun, lẹyin naa o wa aforijin Ọlọhun, ayaafi ki Ọlọhun ṣe aforijin fun un», lẹyin naa ni o wa ka aaya yii: {Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe ìbàjẹ́ kan tàbí tí wọ́n bá ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n á rántí Allāhu, wọ́n á sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn} [Āl ‘Imraan: 135].
Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú al-Kubrọ, ati Ibnu Maajah ati AhmadAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju ko si ẹru kan ti yio da ẹṣẹ kan, ti yio wa se aluwala daadaa, lẹyin naa ti yio ki irun rakaah meji pẹlu aniyan ituuba kuro nibi ẹṣẹ rẹ yii, lẹyin naa ti o wa aforijin Ọlọhun, ayaafi ki Ọlọhun fi ori jin in. Lẹyin naa ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ka ọrọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti o sọ pe: ﴾Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe ìbàjẹ́ kan tàbí tí wọ́n bá ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n á rántí Allāhu, wọ́n á sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn, - Ta sì ni Ó ń forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jin (ẹ̀dá) bí kò ṣe Allāhu. Wọn kò sì takú sórí ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n mọ̀ (pé ẹ̀ṣẹ̀ ni).﴿ [Āl ‘Imraan: 135].
Láti ọdọ bàbá Saheed Al - Khudiryy kí Ọlọhun yọnu sí o sọ pé: Òjíṣẹ Ọlọhun kí ikẹ àti ọlá Rẹ má bà s'ọpe : « Sokoto tàbí aṣọ iwọ sisalẹ Muslim ni láti gun dé ìdajì ojúgun, kò sí àìdá - tàbí kòsí ẹsẹ ni bí - kí o obgun dé láàrin ojúgun àti kókósẹ méjèjì , èyí ti o ba tí kọ já kókó ẹsẹ méjèjì òun ni o tí wa nínú inaa, ẹni k'ẹni tí o ba wọ asọ rẹ tàbí Sokoto rẹ nilẹ ni tí ayọ pọra , Ọlọhun kòní siju wó»
Abu Daud ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a waAnọbi kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ má bà tí se alaye pé dajudaju sokoto muslim l'ọkunrin ni awan ìsesí mẹta , sokoto ni òun tí yóò bọ ìdajì isalẹ ará ọkunrin: Alakọkọ ni : Èyí tí wan fẹ ni kí o gùn fẹ ìdajì ojúgun rẹ. Ẹlẹẹkeji ni : Èyí tí o lẹtọ lai sí kikorira níbẹ ni pé kí o kọja ìdajì ojúgun titi de kókósẹ méjèjì ' òun náà ni egún gùn méjì Ẹlẹkẹta : èyí tí o jẹ èèwọ pẹlu pé kí o gùn kọja kókósẹ méjèjì, ipaya sí wa lórí rẹ pé kí inan má lọ ṣẹlẹ sí , tí o ba se pé o se bẹ ni tí moto moto àti ìyá yọ pọra àti ikọja aala Ọlọhun kòní siju aanu wó .
Láti ọdọ Ubayy ọmọ Kahab ki Ọlọhun yọnu sí o sọ pé : òjíṣẹ Ọlọhun ki ikẹ Ọlọhun ati ọlá Rẹ máa bá sọ pé : b " ẹ má ṣe bú atẹgun , yi e bá rí nkankan ti ko wù yín e sọ bayi pe: " irẹ Ọlọhun àwa n'bere òòrè ti wà lára atẹgun yí lọdọ rẹ àti oore tó wà nínú rẹ àti oore nkan ti wan pàá lasẹ, anwa idaabobo lọdọ rẹ níbi aburú afẹfẹ yí ati aburú nkan ti wa nínú rẹ ati aburú nkan ti wan pàá lasẹ,
Tirmiziy ni o gba a waanọbi kí ikẹ Ọlọhun ati ọlá Rẹ má bà kọ fún wa láti má má bú tabi ṣepe lẹ afẹfẹ, nítorípé àṣẹda rẹ lo pá lasẹ , a má nu ikẹ wà beesini a má mú iya wà , bibu afẹfẹ tumọ sí bubu àṣẹda rẹ àti ìbínú sí idajọ rẹ, leyin náà ni anọbi kí ikẹ Ọlọhun ati ọlá Rẹ má bà tọ wá sọ nán pé kí a Seri pàdà sí ọdọ aṣẹ̀dá rẹ ti ṣe Ọlọhun láti bèrè òòrè rẹ ati òòrè ti wan ran lọdọ rẹ , gege bí mímú ọjọ wà , ati gbígbé gígùn takọ tabo awan irúgbìn ati bẹẹ lọ , ati lati wà isora ati ààbò níbí àbúru rẹ ati àbúru ti wan firan gẹgẹ bí