





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Abu Haazim ọmọ Diinaar: Dajudaju awọn ọkunrin kan wa ba Sahl ọmọ Sahd As-Saa’idiyy, wọn ṣe iyemeji nipa minbari latara nnkan wo ni igi rẹ ti wa, ni wọn wa bi i leere nipa ìyẹn, ni o wa sọ pe: Mo fi Ọlọhun bura, mo mọ latara nnkan ti o ti wa, dajudaju mo ri i ni ọjọ akọkọ ti wọn gbe e kalẹ, ati ọjọ akọkọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jokoo sori rẹ, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ranṣẹ si lagbaja- obinrin kan ninu awọn Ansar ti Sahl si ti dárúkọ rẹ-: “Pa ọmọ-ọdọ rẹ ti o jẹ kafinta láṣẹ ki o kan awọn igi kan fun mi ti maa maa jokoo le wọn lori ti mọ ba fẹ ba awọn eniyan sọ̀rọ̀”, ni o wa pa a láṣẹ o si ṣe e latara igi TỌRFAAHU ti o maa n wa nínú igbó, lẹyin naa o gbe e wa, ni o wa ranṣẹ si ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o wa ni ki wọn gbe wọn kalẹ sí ibì kan, lẹyin naa ni mo ri ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o kirun lori rẹ, ti o si kabara nigba ti o wa lori rẹ, lẹyin naa o rukuu ti o si wa lori rẹ, lẹyin naa o sọkalẹ ti o n fi ẹyin rìn, ni o wa forikanlẹ sibi isalẹ minbari, lẹyin naa o ṣẹri pada, nigba ti o pari o doju kọ awọn eniyan, ni o wa sọ pe: “Ẹyin ènìyàn, dajudaju mo ṣe eyi ki ẹ le tẹle mi ki ẹ si le kọ́ irun kiki mi”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAwọn ọkunrin kan wa ba ọkan ninu awọn saabe, ti wọn n bi i leere nipa minbari ti Anabi ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n lo: latara nnkan wo ni wọn ti ṣe e? Wọn ti ba ara wọn jiyan ti wọn ti ba ara wọn fa a lori ìyẹn, ni o wa sọ fun wọn pe dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ranṣẹ si arabinrin kan ninu awọn Ansar ti o ni ọmọ-ọdọ kan ti o jẹ kafinta, o wa sọ fun un pé: Pa ọmọ-ọdọ rẹ láṣẹ lati kan minbari kan fun mi ti maa maa jokoo le lori nigba ti mo ba n ba awọn eniyan sọ̀rọ̀, ni arabinrin naa ba da a lohun, o wa pa ọmọ-ọdọ rẹ láṣẹ lati ṣe minbari kan fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- latara igi ti n jẹ TỌRFAAHU, nigba ti o pari arabinrin naa ba fi ranṣẹ si Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o ba gbe e wa, ni wọn ba gbe e kalẹ si aaye rẹ ninu mọsalasi, lẹyin naa ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kirun lori rẹ ti o si kabara ti o si wa lori rẹ, lẹyin naa o rukuu ti o si wa lori rẹ, lẹyin naa o sọkalẹ ti o n rin lọ si ẹyin lai yi oju rẹ si ọgangan ẹyin, ni o wa forikanlẹ sibi isalẹ minbari, lẹyin naa o ṣẹri pada, nigba ti o pari irun o dojukọ awọn eniyan, o wa sọ pe: Ẹyin eniyan, dajudaju mo ṣe eyi ki ẹ le maa tẹle mi ki ẹ si kọ irun kiki mi.
Lati ọdọ Hitton ọmọ Abdullahi Ar-Roqooshiy o sọ pe: Mo kirun kan pẹlu Abu Musa Al-Ash'ariy, nigba ti o wa lori ìjókòó, arakunrin kan ninu ijọ sọ pe: Wọn ti da irun pọ mọ ṣíṣe daadaa ati saka, o sọ pe: Nigba ti Abu Musa kirun tan ti o si salamọ, o kọ ju sẹ́yìn, ni o wa sọ pe: Ewo ninu yin lo sọ gbolohun bayii bayii? O sọ pe: Ni awọn èèyàn ba dakẹ, lẹyin naa o sọ pe: Ewo ninu yin lo sọ gbolohun bayii bayii? Ni awọn èèyàn ba dakẹ, o sọ pe: Boya iwọ Hitton lo sọ ọ? O sọ pe: Mi ko sọ ọ, mo bẹru pe ki o ma bu mi nitori rẹ, arakunrin kan ninu wa sọ pe: Emi ni mo sọ ọ, mi ko si gbero nnkan kan pẹlu rẹ afi dáadáa, ni Abu Musa wa sọ pe: Ṣe ẹ ko mọ bi ẹ ṣe ma maa sọ nibi irun yin ni? Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba wa sọ̀rọ̀ ti o si ṣàlàyé sunnah wa fun wa ti o si kọ wa ni irun wa, o wa sọ pe: "Ti ẹ ba ti fẹ kirun, ẹ gbe saafu yin dìde, lẹyin naa ki ẹnikan ninu yin ṣe imaamu fun yín, ti o ba ti kabara, ki ẹyin naa kabara, ti o ba sọ pe: (Ghayril-maghdoobi ‘alaihim wa lad-daaalleen) (Al- Fatiha: 7), ki ẹ sọ pé: Aamiin, Ọlọhun maa da yin lóhùn, ti o ba ti kabara ti o si rukuu, ki ẹyin naa kabara ki ẹ si rukuu, dajudaju imaamu maa rukuu ṣíwájú yín, yio si gbe ori dide ṣíwájú yín", ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: "Iyẹn pẹlu ìyẹn, ti o ba sọ pe: Sami'alloohu liman hamidaHu, ẹ sọ pé: Allahumo Robbanaa wa laKal hamd, Ọlọhun maa gbọ́ yín, dajudaju Ọlọhun- ibukun ni fun orúkọ Rẹ, ti ọla Rẹ ga- sọ lori ahọn Anabi Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Sami'alloohu liman hamidaHu, ti o ba ti kabara ti o forikanlẹ, ki ẹyin naa kabara ki ẹ si forikanlẹ, dájúdájú imaamu maa forikanlẹ ṣíwájú yín, o si maa gbe ori dide ṣíwájú yín", ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pe: "Iyẹn pẹlu ìyẹn, ti o ba ti wa lori ìjókòó, ki ọrọ akọkọ ẹni kọọkan ninu yin jẹ: At-tahiyyatu t-tayyibaatus-salawaatu lillah, as-salamu ‘alayka ayyuha’n-Nabiyyu wa rahmatulLaahi wa barakatuhu, as-salamu ‘alayna wa alaa ibaadil Laahis sọọlihiin, ash'hadu an laa ilaaha illal Loohu wa ash'hadu anna Muhammadan abduhuu wa rọsuuluhuu".
Muslim gba a waSaabe ti o n jẹ Abu Musa Al-Ash'ariy- ki Ọlọhun yọnu si i- kirun kan, nigba ti o wa ni ijokoo ti ataya wa nibẹ, arakunrin kan ninu awọn ti wọn kirun lẹyin rẹ sọ pe: Wọn da irun pọ mọ daadaa ati saka ninu Kuraani, nigba ti Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- kirun tan, o doju kọ awọn ero ẹyin, ni o wa bi wọn leere pé: Ewo ninu yin lo sọ gbolohun: Wọn da irun pọ mọ daadaa ati saka ninu Kuraani?! Ni awọn èèyàn ba dakẹ, ti ẹnikẹni ko sọ̀rọ̀ ninu wọn, ni o ba paara ibeere naa lẹẹkan si, nigba ti ẹnikẹni ko da a lohun, Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe: Boya iwọ Hittọọn ni o sọ ọ! Nitori ìgboyà rẹ ati asunmọ rẹ ati asopọ rẹ pẹlu rẹ, ninu nnkan ti kikẹfin rẹ ko lee ko suta ba a, ati pe ki o le ti ẹni ti o ṣe e gangan jade lati jẹwọ, ni Hittọọn wa sọ pe ko ri bẹ́ẹ̀, o wa sọ pe: Mo bẹru ki o ma bu mi ti o n lero pe emi ni mo sọ ọ; ibi yii ni arakunrin kan ti sọ ninu awọn ijọ pe: Emi ni mo sọ ọ, mi ko si gbero nnkan kan pẹlu rẹ afi dáadáa, ni Abu Musa wa sọ ni ẹni ti o n kọ ọ pé: Ṣe ẹ ko mọ bi ẹ ṣe ma maa sọ lori irun yin ni?! Eleyii jẹ àtakò lati ọdọ rẹ, lẹyin naa Abu Musa wa sọ pe dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba awọn sọ̀rọ̀ ni ọjọ kan, ti o ṣàlàyé Sharia wọn fun wọn, ti o kọ wọn ni irun wọn, ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: Ti ẹ ba fẹ kirun, ki ẹ ya gbe saafu dide ki ẹ si duro tọ́ nibẹ, lẹyin naa ki ẹnikan ninu wọn ṣe imaamu fun awọn eniyan, ti imaamu ba ti kabara wiwọ inu irun, ki ẹyin naa kabara iru rẹ, ti o ba ti ka Fatiha ti o ba wa de: ((Ghayril-maghdoobi ‘alaihim wa lad-daaalleen) (Al- Fatiha: 7)), ki ẹ sọ pe: Aamiin; ti ẹ ba ṣe bẹẹ Ọlọhun maa gba adura yin, ti o ba kabara ti o si rukuu, ki ẹyin naa kabara ki ẹ si rukuu; dajudaju imaamu maa rukuu ṣíwájú yín o si maa gbe ori dide ṣíwájú yín, nitori naa ẹ ko gbọdọ ṣíwájú rẹ; nitori pe asiko ti imaamu gba waju nibẹ lati ṣíwájú yin rukuu, ilọra yin ni rukuu lẹyin ti imaamu ti gbori kuro maa di i fun yin, iru asiko yẹn pẹlu asiko yẹn, odiwọn rukuu yin maa da gẹgẹ bii odiwọn rukuu rẹ, ti imaamu ba sọ pe: Sami'alloohu liman hamidaHu, ki ẹ sọ pé: Allahumo Robbanaa wa laKal hamdu, ti awọn ero ẹyin ba sọ ìyẹn, dajudaju Ọlọhun- mimọ ni fun Un- maa gbọ́ adura wọn ati ọrọ wọn, nitori pe Ọlọhun- ibukun ni fun orúkọ Rẹ, ti ọla Rẹ ga- sọ lori ahọn Anabi Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Samihal Loohu liman hamidaHu, lẹyin naa ti imaamu ba kabara ti o si forikanlẹ, o jẹ dandan fun awọn ero ẹyin lati kabara ki wọn si forikanlẹ, dajudaju imaamu maa forikanlẹ ṣíwájú wọn, o si maa gbe ori dide ṣíwájú wọn, iru asiko yẹn pẹlu asiko yẹn, odiwọn iforikanlẹ ero ẹyin maa da gẹgẹ bii odiwọn iforikanlẹ imaamu, ti o ba wa lori ijokoo ataya, ki akọkọ ọrọ olukirun jẹ: At-tahiyyaatu toyyibaatus solawaatu lillah" Ọla ati ṣiṣẹku ati titobi gbogbo rẹ pata jẹ ẹtọ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, gẹgẹ bẹ́ẹ̀ naa ni awọn irun maraarun-un, gbogbo rẹ pata jẹ ti Ọlọhun, "As-salaamu 'alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu, as-salaamu 'alayna wa 'alaa 'ibaadillahis soliheen", ẹ pe Ọlọhun fun lila kuro nibi gbogbo aleebu ati adinku ati ibajẹ; a maa ṣẹsa Anabi wa Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu àlàáfíà, lẹyin naa a maa tọrọ alaafia fun ara wa, lẹyin naa a maa tọrọ alaafia fun awọn ẹru Ọlọhun ti wọn jẹ ẹni rere ti wọn ṣe nnkan ti o jẹ dandan fun wọn ninu awọn iwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ati awọn iwọ awọn ẹru Rẹ, lẹyin naa, a maa jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin tọ si lododo afi Ọlọhun, a si n jẹrii pe dajudaju Muhammad ẹru Rẹ ni ati ojiṣẹ Rẹ.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: O maa n kabara nibi gbogbo irun ninu eyi ti o jẹ ọran-anyan ati eyi ti o yatọ si i, ninu Ramadan ati oṣu ti o yatọ si i, o maa n kabara nigba ti o ba dìde, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba rukuu, lẹyin naa o maa n sọ pe: Sami’alloohu liman hamidaHu, lẹyin naa o maa n sọ pe: Robbanaa wa laKal hamdu, ṣíwájú ki o to forikanlẹ, lẹyin naa o maa n sọ pe: Allahu Akbar nigba ti o ba lọ silẹ ni ẹni ti o forikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba gbe ori dide lati iforikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba forikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba gbe ori dide lati iforikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba dide lati ijokoo nibi rakah meji naa; o maa n ṣe bẹẹ nibi gbogbo rakah, titi o maa fi pari irun, lẹyin naa o maa n sọ ti o ba ti n lọ pe : Mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, dajudaju emi ni irun mi jọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ju ninu yin, eleyii si ni irun rẹ titi o fi fi aye silẹ.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAbu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- gba apakan wa ninu bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe maa n kirun, o wa sọ pe ti o ba fẹ kirun, o maa n kabara nigba ti o ba dide fun kabara wiwọ irun, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba n lọ si rukuu, ati nigba ti o ba fẹ forikanlẹ, ati nigba ti o ba gbe ori dide lati iforikanlẹ, ati nigba ti o ba forikanlẹ ni iforikanlẹ ẹlẹẹkeji, ati nigba ti o ba gbe ori rẹ dide kuro nibẹ, ati nigba ti o ba dide lati rakah meji akọkọ lẹyin ti o ba jokoo fun ataya akọkọ nibi irun oni rakah mẹta tabi oni rakah mẹrin, lẹyin naa o maa n ṣe bẹẹ nibi gbogbo irun pata titi o maa fi pari rẹ, o maa n sọ ti o ba ti gbe ẹyin rẹ dide lati rukuu pe: Sami’alloohu liman hamidaHu, lẹyin naa o maa n sọ ti o ba wa ni iduro pe: Robbanaa wa laKal hamdu. Lẹyin naa Abu Huraira maa n sọ ti o ba ti pari irun pé: Mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, dajudaju ẹmi ni ìrun mi jọ irun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jù, bi o ṣe maa n kirun nìyí titi o fi fi aye silẹ.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni ti o buru julọ ninu awọn eniyan ni ti ole jija, ni ẹni ti o n ja irun rẹ lole” o sọ pe: Bawo ni o ṣe maa ja irun rẹ lole? O sọ pe: “ Ko nii rukuu dáadáa, ko si nii ṣe iforikanlẹ rẹ laṣẹpe”.
Ibnu Hibbaan ni o gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o buru julọ ninu awọn eniyan ni ti iwa buruku nibi ole jija ni ẹni ti o maa n jale nibi irun rẹ; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nitori pe ẹni ti o ba mu owo ẹlomiran, o ṣeeṣe ki o ṣe anfaani pẹlu rẹ ni aye, yatọ si ole yii, dajudaju oun ja ẹtọ ara rẹ lole ninu ẹsan ati laada, wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, bawo ni o maa ṣe jale ninu irun rẹ? O sọ pe: Ko nii ṣe rukuu rẹ laṣepe, ko si nii ṣe iforikanlẹ rẹ laṣepe; ìyẹn maa rí bẹ́ẹ̀ pẹlu pe ki o maa kanju nibi rukuu ati iforikanlẹ, ti ko nii mu mejeeji wa ni ona ti o pe.
Lati ọdọ ọmọ Abu Aofaa- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba gbe ẹyin rẹ dide lati rukuu, o maa sọ pé: “Sami’alloohu liman hamidaHu, Allahumo Robbanaa wa laKal hamdu, milhas samoowaati wa milhal ardi wa milha maa shi-ita min shaihin bahdu”.
Muslim gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti gbe ẹyin rẹ dide lati rukuu ninu irun, o maa n sọ pe: “Sami’alloohu liman hamidaHu”, o n túmọ̀ si: Dajudaju ẹni ti o ba dupẹ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa da a lohun, yio si gba ọpẹ rẹ ati ẹyin rẹ, yio si san lẹsan, lẹyin naa, o maa dupẹ fun Ọlọhun pẹlu sisọ pe: “Allahumo Robbanaa wa laKal hamdu, milhas samoowaati wa milhal ardi wa milha maa shi-ita min shaihin bahdu”, ni ọpẹ kan ti o maa kun awọn sanmọ ati awọn ilẹ ati nnkan ti o n bẹ laaarin mejeeji, ti o si n kun nnkan ti Ọlọhun ba fẹ ninu nnkan kan.
Lati ọdọ Warrood olukọwe Al-Mugiiroh ọmọ Shu’bah, o sọ pe: Al-Mugiiroh ọmọ Shu’bah pe àpèkọ fun mi ninu iwe kan si Mu’aawiyah pe: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ lẹyin gbogbo irun ọran-anyan pe: “Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu, laHul mulku wa laHul hamdu, waHuha ‘ala qulli shai’in Qodeer, Allahumo laa maania limaa ‘atoita, wa laa mu’tiya limaa mana’ta, wa laa yanfa’u dhal jaddi minKal jaddu”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ lẹyin gbogbo irun ọran-anyan pe: “Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu, laHul mulku wa laHul hamdu, waHuha ‘ala qulli shai’in Qodeer, Allahumo laa maania limaa ‘ah'toita, wa laa mu’tiya limaa mana’ta, wa laa yanfa’u dhal jaddi minKal jaddu”. O n túmọ̀ si pe: Mo n fi rinlẹ mo si n gba gbolohun imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo “Laa ilaaha illallohu” wọlé, ati pe ijọsin ododo mo n fi i rinlẹ fun Ọlọhun, mo si n kọ ọ fun ẹni ti o yatọ si i, ati pe ko si ẹni ti a le maa jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Allahu, mo si n fi ọla gangan ti o pe rinlẹ fun Ọlọhun, ati gbogbo ọpẹ awọn ara inu sanmọ ati ilẹ jẹ ẹtọ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nigba ti O ṣe pe Onikapa ni lori gbogbo nnkan, ati pe nnkan ti Ọlọhun ba kadara rẹ ninu fifun ati kikọ, ko si oludapada kankan fun un, lọdọ Rẹ, ọrọ ko lee ṣe ọlọrọ ni anfaani, bi ko ṣe pe iṣẹ rere ni yoo ṣe e ni anfaani.
Lati ọdọ Huzeifah- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ laaarin iforikanlẹ mejeeji pé: Robbi igfir liy, Robbi igfir liy”.
Abu Daud ati Nasaa'iy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ nibi ijokoo laaarin iforikanlẹ mejeeji pé: Robbi igfir liy, Robbi igfir liy, o si maa n paara rẹ. Ìtumọ̀ Robbi igfir liy ni pé: Ki ẹru wa lati ọdọ Oluwa rẹ lati pa awọn ẹṣẹ rẹ rẹ ki O si bo awọn aleebu rẹ.
Lati ọdọ ọmọ Abbās - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ fun arabinrin kan ninu awọn Ansaar, Ibnu Abbās darukọ rẹ, mo wa gbagbe orukọ rẹ, o sọ fun un pe: «Kini o kọ fun ọ lati ṣe hajj pẹlu wa?» O sọ pe: A ko ni ju rakunmi meji lọ (ti a fi maa n fun oko wa lomi) ti ọkọ rẹ ati ọmọ rẹ si ṣe irinajo hajj lori ẹyọkan, o si fi ẹyọkan silẹ fun wa lati maa lo o lati fi maa pọn omi, o sọ pe: «Ti Ramadan ba ti de ki o yaa ṣe umurah; tori pe dajudaju umurah inu rẹ ṣe deedee hajj».
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niNígbà tí Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣẹri lati hajj idagbere, o sọ fún arabinrin kan ninu Ansaar ti ko ṣe hajj pe: Kini nkan ti o kọ fun ọ lati ṣe hajj pẹlu wa? O wa mu awijare wa pe awọn ni rakunmi meji, ti ọkọ oun ati ọmọ òun si ṣe hajj lori ọkan ninu mejeeji, ti o si fi ẹyọkan silẹ lati lẹ maa fi i pọn omi lati inu kanga. Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa fun un ni iro pe dajudaju ṣiṣe umurah ninu oṣu ramadan ẹsan rẹ ṣe deedee ẹsan hajj.
Lati ọdọ Āisha iya àwọn mumini - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a n ri pe jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ni iṣẹ ti o lọla julọ, ṣe aa nii jagun ni? O sọ pe: «Rara, ṣugbọn jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ti o lọla julọ ni: hajj ti o mọ kanga (ti o jẹ atẹwọgba)».
Bukhaariy gba a waAwọn saabe - ki Ọlọhun yọnu si wọn - maa n ri ijagun si oju-ọna Ọlọhun ati biba awọn ọta ja ni iṣẹ ti o fi n lọla julọ, Ni Āisha - ki Ọlọhun yọnu si i - wa bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe ṣe awọn naa o nii jagun ni? Ni o wa juwe wọn - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lọ sí ibi jihad ti o lọla julọ fun wọn, oun naa ni hajj atẹwọgba (ti o mọ kanga) eleyii ti o ṣe deedee tira Ọlọhun ati sunnah Anabi, ti o si tun la kuro nibi ẹṣẹ ati ṣekarimi.