





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Lati ọdọ Hudhayfah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo wa pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni o wa lọ sibi akitan ijọ kan, ti o si tọ ni iduro, ni mo ba takete si i, o wa sọ pe: «Sunmọ ibi» ni mo ba sunmọ titi mo fi duro si ibi ẹyin gigirisẹ rẹ mejeeji, nigba naa ni o ṣe aluwala ti o si fi ọwọ pa ibọsẹ alawọ rẹ mejeeji.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niHudhayfah ọmọ Al-yamān - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- n royin pe oun wa pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-, ni o wa gbero - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - lati tọ, ti o si wọ subāta ijọ kan; oun naa ni aaye ti wọn maa n da idọti ati iyẹpẹ ti wọn ba gba jade ni inu ile si, nigba naa ni o wa tọ ni iduro, èyí tí o si pọ ninu ìṣesí rẹ ni ki o tọ ni ijokoo. Ni Hudhayfah wa takete si i, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ fun un pe: Sunmọ ibi, ti Hudhayfah si sunmọ ọn titi ti o fi duro si ẹyin rẹ nibi gigisẹ rẹ mejeeji; ki o le wa gẹgẹ bii gaga fun un ki wọn ma baa ri i ni ìṣesí yẹn. Lẹyin naa ni o wa ṣe aluwala - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, nigba ti o de ibi fifọ ẹsẹ mejeeji, o fi mọ lórí pipa ibọsẹ alawọ rẹ mejeeji - awọn ni awọ fẹlẹfẹlẹ tabi nkan ti o jọ ọ ti wọn maa n bọ si ẹsẹ ti yio si bo koko ẹsẹ mejeeji - ti ko si bọ wọn silẹ.
Láti ọdọ Ibnu Abbas -kí Ọlọhun o yọnu sí awọn méjèjì- láti ọdọ Annabi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọla Rẹ o máa ba a, o s'ọpe: “Ẹ fi àwọn ìpín ogún (fara’id) fún àwọn tí ó tọ si, oun tí ó bá ṣẹkù lẹ́yìn náà, kó lọ fún ọkùnrin tí ó sunmọ́ (oku) jù lọ (ní ìbátan)".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnnabi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ o maa ba- n paṣẹ fún àwọn tí ń ṣàkóso ogún pínpín pé kí wọ́n pín (ogun ti oku fi silẹ) fún àwọn tí ó tọ si, ni ìpín ti o ṣe dede ofin (shari'a), gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́hun ṣe fẹ́. Nítorí náà, a máa fún àwọn onípin tí a ti sọ ìpín wọn di mímọ́ nínu tira Ọlọ́hun ní ipin wọn, tí awọn ìpín naa si jẹ: ìdáméjì ninu ida mẹta ogún, idankan idamẹta, idafa, ìdajì, idamẹrin, ati idamejọ ogún, ohun tí o ba wa sẹku lẹyin naa, a o fún ẹni tí ó sunmọ́ oku jù lọ ninu awọn ọkùnrin, ti wọ́n sì ń pè wọn ní Al-‘asabah (àwọn ìbátan ọkùnrin tí ń jogún ohun tí ó sẹkù lẹyin ti a pin ogun tan).
Lati ọdọ baba Abdullahi An,-Nuhman ọmọ basheer kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ má bà, O sọ pé : mọ gbọ tí òjíṣẹ Ọlọhun kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ má bà sọ pé : “Dajudaju nǹkan ẹtọ fi ojú hàn, dájúdájú nǹkan eewọ naa fi ojú hàn, o wa n bẹ láàrin àwọn méjèèjì àwọn nǹkan ti wọn ruju, ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ko si mọ wọn, ẹni tí ó bá ṣọra fun awọn iruju naa, o ti wa mímọ́ fun ẹsin rẹ ati ọmọlúwàbí rẹ, ẹni tí o ba ko sinu àwọn ìríjú naa, yoo ko sinu nǹkan eewọ, o da gẹgẹ bii adaranjẹ̀ ti n da ẹran jẹ̀ ni etí ilẹ̀ ti wọn dá ààbò bò, o sunmọ ki o da ẹran wọ inu rẹ. Ẹ tẹti ẹ gbọ, dájúdájú gbogbo ọba ni o ni ilẹ̀ ti wọn dá ààbò bò. Ẹ tẹti ẹ gbọ, ilẹ Ọlọhun ti a da ààbò bò ni àwọn nǹkan ti O ṣe ni eewọ, ẹ tẹti ẹ gbọ, dájúdájú baaṣi ẹran kan n bẹ nínú ara, ti o ba ti dáa, gbogbo ara ti dáa, ti o ba si ti bajẹ, gbogbo ara ti bajẹ, ẹ tẹti ẹ gbọ, oun naa ni ọkàn”.
رواه البخاري ومسلمAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé òfin kan ti o kárí nibi awọn nǹkan, o si pin si mẹta ninu ṣẹria: Ẹ̀tọ́ ti o fi ojú hàn, ati eewọ ti o fi ojú hàn, ati awọn alamọri kan ti wọn ruju ti idajọ wọn kò hàn nipa pe ṣe ẹtọ ni abi eewọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ninu awọn èèyàn ko mọ idajọ wọn. Ẹni ti o ba gbe àwọn nǹkan iruju yẹn jù silẹ, ẹsin rẹ maa ni àlàáfíà pẹ̀lú jíjìnnà sí kiko sinu nǹkan eewọ, ọmọlúwàbí rẹ naa si maa ni àlàáfíà kuro nibi ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn pẹ̀lú nǹkan ti wọn yoo fi maa bu u ti o ba ṣe nǹkan ìríjú yii. Ẹni ti ko ba jìnnà si awọn nǹkan ìríjú, ninu ki o ko sinu nǹkan eewọ, tabi ki àwọn èèyàn bu ẹnu àtẹ́ lu ọmọlúwàbí rẹ. Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi àkàwé kan lélẹ̀ lati ṣàlàyé iṣesi ẹni tí o ba n ṣe àwọn nǹkan iruju pe o da gẹgẹ bii adaranjẹ ti n da ẹran rẹ jẹ ni tòsí ilẹ̀ kan ti ẹni tí ó ni i ti da aabo bo o, o sunmọ ki awọn ẹran rẹ jẹ ninu ilẹ̀ ti a da aabo bo yii torí wiwa wọn ni tòsí ibẹ, bẹ́ẹ̀ naa ni ẹni ti n ṣe nnkan ti ìríjú wa ninu ẹ, pẹ̀lú ìyẹn o ti n sunmọ nǹkan eewọ, o si sunmọ ki o ko sinu rẹ. Lẹyin rẹ ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé baaṣi ẹran kan n bẹ ninu ara (oun naa ni ọkàn), ara yoo maa dáa pẹ̀lú dídára rẹ, o si maa bajẹ pẹ̀lú bibajẹ rẹ.
Lati ọdọ Abu Bakra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: “Njẹ emi ko wa ni fun yin ni iro nipa awọn ti o tobi ju ninu awọn ẹṣẹ ńlá bi?” O sọ bẹẹ ni igba mẹ́ta, wọn sọ pe: A fẹ bẹẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: “Mimu orogun pẹ̀lú Ọlọhun ati yiyapa aṣẹ awọn obi mejeeji”, o wa jokoo, o si jẹ ẹni ti o rọgbọku tẹlẹ, ni o wa sọ pe: “Ẹ gbọ o, ati ọrọ eke”, o sọ pe: Ko wa yẹ ni ẹni ti n wi i ni awitunwi titi ti a fi sọ pe: Iba tiẹ si dakẹ.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba - n sọ fun awọn saabe rẹ nipa awọn ti o tobi ju ninu awọn ẹṣẹ nla, nitori naa o darukọ àwọn mẹta yii: 1. Imu orogun pọ mọ Ọlọhun: Oun naa ni fifi iran kan ninu awọn iran ijọsin fun ẹlòmíràn yatọ si Ọlọhun, ati fifi ẹni ti o yatọ si Ọlọhun dọgba pẹlu Ọlọhun nibi ìní-ẹ̀tọ́ si ijọsin Rẹ, ati ijẹ Oluwa Rẹ, ati awọn orukọ ati awọn iroyin Rẹ. 2. Yiyapa aṣẹ awọn obi mejeeji: Oun naa ni gbogbo ipalara ṣiṣe si obi mejeeji, yala ninu ọrọ tabi iṣe, ati gbigbe ṣiṣe daadaa si wọn jù silẹ. 3. Ọrọ eke, ninu rẹ naa ni ẹri eke: Oun naa ni gbogbo ọrọ irọ ti wọn n fẹ lati fi tabuku ẹni ti o ba ṣẹlẹ si i, pẹlu gbígba dúkìá rẹ, tabi titayọ aala lori ọmọluabi rẹ tabi nkan ti o jọ bẹẹ. Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti paara ikilọ kuro nibi ọrọ eke, lati ṣe itaniji lori ibajẹ rẹ (aidara rẹ) ati oripa aburu rẹ lori awujọ, titi ti awọn saabe fi sọ pe: Ko ba tiẹ si dakẹ; ni ti ìkáàánú rẹ, ati ikorira ohun ti o n yọ ọ lẹnu.
Lati ọdọ Al-Miqdam ọmọ Maadi Karib, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe: “Bí ọkùnrin kan bá nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, kí ó sọ fún un pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀”.
Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú al-Kubrọ, ati AhmadAnabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n ṣe alaye ọkan lara awọn okunfa ti o lè fun ajọṣepọ ati ifẹ lagbara laarin awọn onigbagbọ ododo, òun naa ni pe ti ẹnikẹni ba nífẹ̀ẹ́ arakunrin rẹ̀, ki o sọ fun un pe oun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Awọn ẹṣẹ nlanla ni: Mimu orogun pẹlu Ọlọhun, ṣiṣẹ baba ati ìyá, pipa ẹmi, ati bibura lori irọ”.
Bukhaariy gba a waAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe awọn nlanla ninu awọn ẹṣẹ, àwọn ni eyi ti wọn ṣe adehun iya fun ẹni ti o ba ṣe e pẹlu adehun iya ti o le koko ni aye tabi ni ọrun. Akọkọ ninu ẹ ni “Mimu orogun pọ mọ Ọlọhun”: Oun ni yiyi eyikeyii iran ninu awọn iran ijọsin fun ẹni ti o yatọ si Ọlọhun, ati gbigbe ẹni ti o yatọ si Ọlọhun si ipo Ọlọhun nibi nnkan ti o jẹ awọn ẹsa Ọlọhun nibi ìní-ẹ̀tọ́ si ijọsin Rẹ, ati nibi jijẹ Oluwa Rẹ ati nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ. Ikeji nibẹ ni “Ṣiṣẹ baba ati iya”: Oun ni gbogbo nnkan ti o le sọ fifi suta kan baba ati iya di dandan ni ti ọrọ ni tabi iṣe, ati gbigbe ṣiṣe daadaa si wọn ju silẹ. Ikẹta nibẹ ni “pipa ẹmi”: Laini ẹtọ, gẹgẹ bii pipa ẹmi ni ti abosi ati ni ti itayọ ẹnu-àlà. Ikẹrin nibẹ ni “Bibura lori irọ”: Oun ni bibura ni ẹni tí n pa irọ ti o si mọ̀ pé irọ́ ni oun n pa, wọn sọ ọ ni orúkọ yẹn; nitori pe o maa n tẹ ẹni ti o n pa a ri sinu ẹṣẹ tabi inu ina.
Lati ọdọ Abu Huraira, o sọ pe: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Oluran awọn opo ati alaini lọwọ, da gẹgẹ bii olugbinyanju soju ọna Ọlọhun, tabi ẹni ti o n fi oru rẹ dide ti o si n fi ọsan rẹ gba awẹ".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba n ṣe anfaani fun obinrin ti ọkọ rẹ ku, ti ko ni ẹni kankan ti o maa moju to awọn alamọri rẹ, ati alaini ti o ni bukaata, ti o si n na owo fun wọn ni ẹni ti o n wa ẹsan lọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nibi ẹsan, o da gẹgẹ bii olujagun loju ọna Ọlọhun, tabi ẹni ti o n ki irun ni oru ti ko ki n rẹ ẹ, ati alaawẹ ti ko ki n túnu.
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe: “Ẹ yẹra fún awọn nkan meje tí n pani run” Wọ́n sọ pé: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, kí ni awọn nkan naa? Ó ní: “Ṣíṣe ẹbọ pẹ̀lú Ọlọhun, pípidán, pípa eniyan tí Ọlọhun ṣe ní eewọ, àyàfi pẹlu ẹ̀tọ́, jíjẹ owó èlé, jíjẹ owó ọmọ òrukàn, sísálọ ní ọjọ́ ogun ẹsin, ati jíju òkò ṣina mọ́ awọn obinrin abilékọ, onígbàgbọ́ ododo, àwọn tí sìná kò sí lórí ọkàn wọn”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niOjiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n paṣẹ fún àwọn ijọ rẹ̀ pé kí wọ́n jinna sí awọn iwa ọdaran ati ẹṣẹ meje ti n pani run, nigba ti wọ́n wá bi i leere pé kí ni wọ́n? O ṣalaye pé àwọn ni: Ikinni: Ṣíṣe ẹbọ pẹlu Ọlọhun, nipasẹ wíwá alafiwe ati alafijọ fun Un, èyí ó wù ki o jẹ, mimọ ni fún Ọlọhun, ati ṣiṣe eyikeyii ninu awọn ijọsin fún ẹlomiran tó yatọ si Ọlọhun Allah, Ọba Aleke ọla. Àti pé Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – bẹrẹ pẹlu ẹbọ; nitori pe oun ló tobi julọ ninu awọn ẹṣẹ. Ikeji: Idán ṣíṣe – oun naa ni títa kókó àwọn nkankan, ati pípọfọ̀, ati awọn oogùn, ati awọn èéfín ti n rú jáde – yoo lapa lára ẹni tí wọ́n bá ṣe idan sí, bii kí o pa ẹni naa, tabi kí ó kó àisàn ba a, tabi kí ó fa ipinya laarin ọkọ ati aya. Iṣẹ ẹ̀ṣù ni, ati pé wọn ò lè rí ọpọlọpọ ninu awọn idan yi ṣe ayafi nipasẹ ẹbọ ati ìpèsè nkan ti awọn ẹ̀mí eṣu buruku nífẹ̀ẹ́ si fun wọn. Ẹkẹta: Pípa ẹmi ti Ọlọhun ṣe ni eewọ lati pa a ayafi pẹ̀lú nǹkan ti o maa sọ ọ́ di ẹ̀tọ́ ti o ba ṣẹria mu ti oludajọ ṣẹria sì maa mu u ṣẹ. Ẹkẹrin: Gbígba owo èlé lati lè jẹ́ ẹ tabi lilo o ní ọna miiran ninu awọn ọna anfaani. Ìkarùn-ún: Ìtayọ àlà sí owó ọmọ kékeré tí bàbá rẹ̀ kú nígbà tí kò ì tíì bàlágà. Ẹkẹfa: Sísá kúrò loju ogun ẹsin pẹ̀lú awọn keferi. Ìkeje: Fífi ẹ̀sùn àgbèrè kan àwọn obìnrin olómìnira, oluṣọra nibi ìranù, àti fífi ẹ̀sùn kan àwọn ọkùnrin bakan naa.
Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ṣo pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: “Ẹ má ṣe sọ ilé yín di saare, ẹ sì má sọ saare mi di àáye àjọ̀dún, ẹ maa ṣe asalatu fún mi; dajudaju asalatu yín ó kàn mi lara lati ibikibi ti ẹ ba wa.
Abu Daud ni o gba a waAnabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n kọ̀ fún wa níbi kí a má maa ki ìrun ninu awọn ile wa, tí awọn ile naa yio waa da gẹgẹ bii itẹ́ awọn òkú, tí ẹnikẹni kò gbọdọ̀ kirun nibẹ. O sì kọ̀ fun wa lati maa ṣe àbẹ̀wò saare rẹ̀ léraléra ati imaa kójọ sibẹ ni igba gbogbo; nitori pe iyẹn jẹ́ ọna kan tí ó lè mu wa wọ inu ẹbọ. Ó paṣẹ pe ki a maa tọrọ ìkẹ́ ati ìgẹ̀ fun oun ni ibikibi lori ilẹ aye; nitori pe iyẹn yoo kàn án lara lati ọdọ ẹniti ó sunmọ ati ẹniti ó jinna bakan naa, nitori naa a o ni bukata si ki a maa paara ibi saare rẹ̀.