





























Hadeeth Cards
Da'wa cards that highlight great meanings from the noble prophetic hadiths in a simple style and attractive display that helps the Muslim to have a deeper understanding of his religion in an easy way
All
Láti ọ̀dọ̀ Abu Bakrah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Ti Mùsùlùmí méjì ba pàdé ara wọn pẹ̀lú idà, ati ẹni ti o pa eeyan ati ẹni tí wọ́n pa, wọn jọ maa wọ iná ni”, mo wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a gbọ ti ẹni tí o pa èèyàn, ẹni tí wọ́n pa wa nkọ? O sọ pé: “Oun naa fẹ́ pa ẹni keji rẹ ni”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ti Mùsùlùmí meji ba pade ara wọn pẹ̀lú idà, ti ìkíni kejì wọn n gbero lati pa ìkejì rẹ; ẹni tí ó pa èèyàn maa wọ iná; tori pe oun ni o pa ikeji rẹ tààrà, Ọ̀rọ̀ ẹni tí wọ́n pa wa ru àwọn saabe lójú pe: Báwo ni o ṣe maa wọ ina? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé torí pé oun naa fẹ́ pa ìkejì rẹ ni, ko si si nǹkan ti o kọ̀ fun un lati ma pa a ju pe ọwọ́ ẹni tí o pa a yá ju tiẹ̀ lọ ni.
Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ pẹlu àníyàn ni, ohun ti ọmọniyan ba gba lero ni yoo maa jẹ tiẹ̀, ẹni tí hijra tiẹ̀ ba jẹ tori ti Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, hijra rẹ maa jẹ ti Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, ẹni tí hijra rẹ ba jẹ torí ayé ti o fẹ ki ọwọ rẹ o tẹ̀ tabi torí obìnrin ti o fẹ́ fẹ́, hijra rẹ maa jẹ ohun ti o ba tori rẹ ṣe hijra ni”. Ninu gbólóhùn kan ti o jẹ ti Bukhaariy: “Àwọn iṣẹ pẹ̀lú àwọn àníyàn ni, o maa jẹ ti ọmọniyan kọ̀ọ̀kan ohun ti o ba gba lero”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe gbogbo iṣẹ́ pẹlu àníyàn ni, ìdájọ́ yii kárí gbogbo iṣẹ́ bii ìjọsìn ati ibalopọ. Ẹni ti o ba gbèrò anfaani kan pẹlu iṣẹ rẹ, anfaani yẹn naa ni o maa tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́, ko si si ẹsan kankan fun un, ẹni tí ó bá wa gbèrò isunmọ Ọlọhun pẹlu iṣẹ rẹ, o maa gba ẹsan kódà ki o jẹ iṣẹ lásán bii jijẹ ati mimu. Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa fi àkàwé lélẹ̀ láti ṣàlàyé ilapa àníyàn nibi awọn iṣẹ pẹ̀lú didọgba wọn nibi àwòrán ti o hàn, o wa ṣàlàyé pe ẹni ti o ba gbèrò wíwá ìyọ́nú Ọlọhun pẹ̀lú hijra rẹ ati fifi ìlú rẹ sílẹ̀, hijra rẹ nǹkan ti o ba òfin mu ni ti a si maa tẹ́wọ́ gbà ti wọn si maa san an ni ẹsan lórí ẹ fun àníyàn òdodo rẹ, ẹni tí ó bá gbèrò anfaani ayé pẹ̀lú hijra rẹ, bii owó, tabi ipò, tabi òwò, tabi ìyàwó, anfaani yẹn ti o gbèrò naa ni o maa ri nibi hijra rẹ, ko si nii gba ẹsan.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Arákùnrin kan sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun mi, o sọ pé: “Ma ṣe maa binu”, o wa pààrà rẹ ni ọpọlọpọ ìgbà, o tun sọ pé: “Ma ṣe maa bínú”.
Bukhaariy gba a waỌ̀kan ninu awọn saabe- ki iyọnu Ọlọhun maa ba wọn- wá láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki o tọka òun si nǹkan kan tí o maa ṣe e ni anfaani, o wa pa a láṣẹ ki o ma maa bínú, itumọ ìyẹn ni pe ki o jìnnà si awọn okùnfà ti o le mu u binu, ki o si ko ara rẹ ni ìjánu ti ìbínú bá ṣẹlẹ̀, ki o ma tẹ síwájú nibi ibinu rẹ pẹlu pípa, tàbí lílù, tabi èébú, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Arákùnrin naa paara wíwá àsọtẹ́lẹ̀ naa ni ọpọlọpọ ìgbà, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko sọ fun un nibi àsọtẹ́lẹ̀ naa ju pe “ma ṣe maa binu”.
Láti ọ̀dọ̀ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Oun gbọ ti Anọbi Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ti o ba jẹ pe ẹ n gbẹkẹle Ọlọhun gẹgẹ bi o ti yẹ ki ẹ gbẹkẹle E ni, Oun iba pese fun yin gẹ́gẹ́ bí O ti pese fun awọn ẹyẹ, ti wọn maa jade ni owurọ pẹlu ebi, ti wọn si maa pada ni irọlẹ ti wọn si ti yó.”
Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a waÒjíṣẹ́ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, gba wa niyanju lati gbẹkẹle Ọlọhun lati mu anfaani wa ati lati yago fun ipalara ninu ọ̀rọ̀ aye ati ẹsin. Ko si ẹni ti o le fun èèyàn ni nǹkan tabi fi nǹkan dun èèyàn, tabi ko inira ba èèyàn tabi ṣe èèyàn ni anfaani ayafi Ọlọhun Ọ̀gá-ògo, Ki a si ṣe awọn okunfa ti o maa mu anfaani wa, ti o si maa dènà ipalara, pẹlu gbigbẹkẹle Ọlọhun ti òdodo, ti a ba ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọhun maa pese fun wa bi O ti n pese fun awọn ẹyẹ ti wọn n jade ni owurọ pẹ̀lú ebi. Lẹ́yìn naa wọn maa pada ni irọlẹ ti ikun wọn si ti kún, ati pe iṣe ti ẹyẹ yii jẹ ọkan ninu awọn ọ̀nà igbiyanju lati wa jíjẹ-mímu, laisi igbẹkẹle asán ati ìmẹ́lẹ́.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ninu nǹkan ti o gba wa lati ọdọ Olúwa rẹ tí Ó lágbára ti O gbọnngbọn, O sọ pe: “Ẹru mi da ẹṣẹ kan, o wa sọ pé: Irẹ Ọlọhun, fi orí ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun Àlekè-ọla wa sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o si mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti O si maa n fi iya ẹṣẹ jẹ eeyan, lẹyin naa o tun ṣẹri pada si idi ẹṣẹ, o wa tun sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga tun sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o si mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti O si maa n fi iya ẹṣẹ jẹ eeyan, lẹyin naa o tun ṣẹri pada si idi ẹṣẹ, o wa tun sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga tun sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o si mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti O si maa n fi iya ẹṣẹ jẹ eeyan, maa ṣe ohun ti o ba fẹ́, mo ti fi ori jin ọ”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n gba ẹgbawa láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ pe ti ẹrú ba da ẹṣẹ kan, ti o wa sọ pé: Irẹ Ọlọhun, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o wa mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti yoo waa bo o ni àṣírí, ti yoo si ṣe amojukuro fun un, tabi ki O fi ìyà jẹ ẹ lori ẹ, Mo ti fi ori jin in. Lẹ́yìn naa ni o tun tun ẹṣẹ da, o wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun wa sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o wa mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti yoo waa bo o ni àṣírí, ti yoo si ṣe amojukuro fun un, tabi ki O fi ìyà jẹ ẹ lori ẹ, Mo ti fi ori jin ẹrú Mi. Lẹ́yìn naa ni o tun tun ẹṣẹ da, o wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun wa sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o wa mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti yoo waa bo o ni àṣírí, ti yoo si ṣe amojukuro fun un, tabi ki O fi ìyà jẹ ẹ lori ẹ, Mo ti fi ori jin ẹrú Mi. Ki o maa ṣe ohun ti o ba fẹ́ lópin ìgbà ti o ba jẹ pe ti o ba ti n da ẹṣẹ naa ni yoo maa fi ẹṣẹ naa sílẹ̀, ti yoo si ká abamọ, ti yoo si pinnu pé oun ko nii pada síbẹ̀ mọ, ṣùgbọ́n ẹ̀mí rẹ maa borí rẹ, yoo tun wa da ẹṣẹ naa padà, lópin ìgbà ti o ba n ṣe báyìí, ti o n da ẹṣẹ, ti o si n ronupiwada, maa fi ori jin in; torí pé ìrònúpìwàdà maa n wó ohun ti o ba ṣáájú rẹ ni.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dájúdájú àwọn onideede maa wa lori minbari latara imọlẹ ni ọdọ Ọlọhun, ni ọwọ ọtun Ajọkẹ-aye ti O lágbára ti O gbọnngbọn, ọ̀tún si ni ọwọ Rẹ̀ méjèèjì, àwọn ti wọn n ṣe deede nibi ìdájọ́ wọn, ati lọ́dọ̀ àwọn ará ilé wọn, ati nibi ohun ti n bẹ lábẹ́ àṣẹ wọn”.
Muslim gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe àwọn ti wọn n dajọ pẹ̀lú deede ati òdodo láàrin àwọn èèyàn ti wọn n bẹ lábẹ́ àṣẹ wọn ati idajọ wọn, ati ara ile wọn, wọ́n maa jókòó lori aga ti o ga ti wọn da latara imọlẹ, láti ṣe apọnle wọn ni ọjọ́ igbende. Ọwọ́ ọ̀tún Ọlọhun ni àwọn minbari yii maa wà, ọ̀tún si ni ọwọ Rẹ méjèèjì.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Njẹ ẹ mọ ohun ti n jẹ ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn?”, wọn sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ ju, o sọ pé: “Oun naa ni ki o maa sọ nipa ọmọ-ìyá rẹ ohun ti o korira”, wọn sọ pé: Ti ohun ti mo n sọ ba n bẹ lara ọmọ-ìyá mi ńkọ́? O sọ pe: “Ti ohun ti o n sọ ba n bẹ lara ọmọ-iya rẹ, o ti sọ ọrọ rẹ lẹ́yìn nìyẹn, ṣùgbọ́n ti ko ba si lara rẹ, o ti dá àdápa irọ́ mọ ọn nìyẹn”.
Muslim gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pàápàá ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn ti o jẹ eewọ, oun naa ni: Sísọ nipa Mùsùlùmí ti ko si ni tòsí ohun ti o maa korira, bóyá o jẹ nibi awọn ìròyìn rẹ ti wọn dá mọ ọn tabi ti ìwà, gẹgẹ bii: Olojukan ẹlẹtan òpùrọ́, ati awọn nǹkan ti o jọ ọ ninu awọn ìròyìn ẹ̀gàn, kódà ki ìròyìn náà o wa lára rẹ. Ṣùgbọ́n ti iroyin naa ko ba si lara rẹ, eyi tun buru ju ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn lọ, oun ni BUHTAAN, itumọ rẹ ni: Adapa irọ mọ ọmọniyan pẹ̀lú nǹkan ti ko si lára rẹ.
Lati ọdọ Khaolah Al-Ansaariyyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Dájúdájú àwọn èèyàn kan n wọ inu dúkìá Ọlọhun ni ọ̀nà tí kò tọ́, wọn maa wọ iná ni Ọjọ́ Àjíǹde”.
Bukhaariy gba a waAnọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nipa awọn eeyan kan ti wọn n ṣe ibajẹ ninu dúkìá àwọn Musulumi, ti wọn si n mu u ni ọ̀nà ti kò tọ́, eyi ni itumọ kan ti o kari nibi dukia, nibi kiko o jọ lati ibi ti ko ti ni ẹtọ, ati nina an sibi ti kii ṣe aaye rẹ ti o tọ, jíjẹ dúkìá àwọn ọmọ orukan maa wọ inú ẹ, àti awọn dúkìá ti a fi sọri awọn kan, ati titako agbafipamọ, ati mimu ninu dúkìá gbogbogboo ni ọ̀nà tí kò tọ́. Lẹ́yìn náà ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé ẹsan wọn ni iná ni Ọjọ́ Àjíǹde.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Ẹ sọra fun aba dida; nitori pe aba dida jẹ eyi ti o jẹ irọ julọ ninu ọrọ, ẹ ma ṣe maa ọ̀nà láti tu ihoho ara yin sita, ki ẹ si ma maa tọpinpin ara yin, ki ẹ si ma maa ṣe keeta ara yín, ki ẹ si ma maa kọ ẹyin si ara yin, ki ẹ si ma maa korira ara yín, ki ẹ jẹ ẹru Ọlọhun ni ti ọmọ iya".
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí niAnabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n kọ o si n kilọ kuro nibi awọn kan ninu nnkan ti o le bi opinya ati ọta laaarin awọn Musulumi, Ninu ìyẹn ni: (Az zonnu) oun ni ikẹfin ti o maa n ṣẹlẹ̀ ninu ọkan laini ẹri; o si ṣàlàyé pe o wa ninu eyi ti o jẹ irọ julọ ninu ọrọ. Ati kuro nibi (At tahassus): Oun ni wiwadii nipa awọn ihoho awọn eniyan pẹlu oju tabi etí. Ati (At-tajassus): Oun ni wiwadii nipa nnkan ti o pamọ ninu awọn alamọri, ibi tí wọ́n ti maa n sọ ìyẹn ju ni nibi aburú. Ati kuro nibi: (Al hasad) oun ni ikorira ṣiṣẹlẹ idẹra fun awọn ẹlomiran. Ati kuro nibi (At tadaabur) ki awọn kan ninu wọn maa gbúnrí kúrò lọ́dọ̀ awọn kan, ko nii salamọ, ko si nii ṣe abẹwo ọmọ-iya rẹ ti o jẹ Mùsùlùmí, Ati kuro nibi: (At tabaagud) ati ikorira ati jíjìnnà-sini, gẹgẹ bii fifi suta kan awọn ẹlomiran, ati lile oju ati aima pade ara ẹni dáadáa. Lẹyin naa, o sọ gbolohun ṣókí kan ti o ko nǹkan ti o pọ sínú ti o maa tun awọn isẹsi awọn Musulumi ṣe pẹlu ara wọn: (ki ẹ jẹ ẹru Ọlọhun ni ti ọmọ iya) Ati pe ìjẹ́ ọmọ iya jẹ asopọ kan ti awọn ajọṣepọ laaarin awọn eniyan fi maa n lẹ̀ pọ̀, ti o maa n lekun ifẹ ati irẹpọ láàárín wọn.